ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w08 4/1 ojú ìwé 30
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀ Ọ́n?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀ Ọ́n?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jésù Lọ sí Sínágọ́gù Tó Wà ní Násárẹ́tì
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Bíbélì Di Odindi Ìwé Ó Kúrò Ní Àkájọ Ìwé, Ó Di Ìwé Alábala
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ninu Sinagọgu Ilu Ibilẹ Jesu
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Lílajú Sí Ìhìnrere
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
w08 4/1 ojú ìwé 30

Ǹjẹ́ O Mọ̀ Ọ́n?

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ ni Jésù ń la ojú afọ́jú kan?

Nínú Máàkù 8:22-26, a kà nípa bí Jésù ṣe la ojú afọ́jú kan ní Bẹtisáídà. Ìtàn yẹn fi yé wa pé Jésù kọ́kọ́ tutọ́ sí ojú ọkùnrin náà kó tó wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó ríran. Ohun tọ́kùnrin yẹn sọ fi hàn pé ohun tó ṣẹlẹ̀ kò tètè yé e, torí ó sọ pé: “Mo rí àwọn ènìyàn, nítorí mo ṣàkíyèsí àwọn ohun tí ó jọ igi, ṣùgbọ́n wọ́n ń rìn káàkiri.” Lẹ́yìn ìyẹn ni Jésù tún fọwọ́ kan ojú ọkùnrin náà. Bíbélì sọ ohun tó wá ṣẹlẹ̀ pé: “Ọkùnrin náà sì ríran kedere, a sì mú un padà bọ̀ sípò, ó sì ń rí ohun gbogbo ní ketekete.” Ó dájú pé díẹ̀díẹ̀ ni Jésù la ojú ọkùnrin náà. Ṣùgbọ́n kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé, a lè ṣàlàyé ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ojú tó ti fọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún—tàbí ká tiẹ̀ sọ pé tí kò ríran rí—tó wá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ríran fún ìgbà àkọ́kọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ àrà mérìíyìírí. Bí àpẹẹrẹ, wọn máa ń fi àwọn ẹṣin kan wa kùsà nígbà kan. Inú òkùnkùn tí wọ́n máa ń wà nínú kòtò yẹn ti mọ́ wọn lára débi pé tí wọ́n bá jáde síta gbangba, ó máa ń tó odindi ọjọ́ kan kí ojú wọn tó lè ríran dáadáa. Àgàgà bí ẹṣin yẹn ó bá tiẹ̀ wá ríran dáadáa tẹ́lẹ̀, o máa ju ọjọ́ kan lọ kó tó lè ríran kedere. Lóde òní, àwọn dókítà tó ń ṣiṣẹ́ abẹ ti tún ojú àwọn kan tí ò ríràn dáadáa tẹ́lẹ̀ ṣe tí wọ́n sì ti ń fi ojú ọ̀hún ríran. Àmọ́ ṣá, ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé ọpọlọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kì í kọ́kọ́ lè gbé gbogbo ohun tójú wọn ń rí ní báyìí tójú wọn ti wá ń ríran kedere. Oríṣiríṣi àwọ̀ àti gbogbo ohun tí wọ́n ń rí báyìí máa ń kọ wọ́n lóminú débi pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tó wọ́pọ̀ táwọn èèyàn ń rí tó sì ń yé wọn ló ṣàjèjì sáwọn. Ó máa ń ṣe díẹ̀ kí ọpọlọ wọn tó lè gbé gbogbo ohun tí wọ́n ń rí.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí àánú ọ̀gbẹ́ni yẹn ṣe ṣe Jésù tó ló jẹ́ kó la ojú ẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Lákòótán, pé “ọkùnrin náà sì ríran kedere,” fi hàn pé ó lóye gbogbo ohun tó rí dáádáá.

Kí ló mú kí àkájọ ìwé ṣòroó kà lásìkò tí Jésù wà láyé?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé abala àkájọ ìwé máa ń gùn tó ìwé àjákọ, síbẹ̀ àwọn abala kan wà tí kì í gùn tó o, bákan náà sì lọ̀rọ̀ rí ní ti fífẹ̀ àkájọ ìwé. Wọ́n á wá lẹ abala bíi mélòó kan pọ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ tàbí kí wọ́n fi fọ́nrán òwú ọ̀gbọ̀ so ó pọ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́. Nígbà míì sì rèé, àwọn abala náà á máa gùn ju ìwé àjákọ lọ. Àpapọ̀ abala tí wọ́n fi ṣe ìwé Aísáyà tó wà lára Àkájọ Òkun Òkú tó wà lọ́wọ́ báyìí jẹ́ mẹ́tàdínlógún, ó sì fi díẹ̀ fẹ̀ ju ìwé àjákọ méjì lọ. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí àkájọ ìwé tá à ń sọ yìí ṣe gùn tó náà ni àkájọ Aísáyà tí Jésù lò ní sínágọ́gù nílùú Násárétì ṣe gùn tó.—Lúùkù 4:16, 17.

Lórí kókó yìí, Alan Millard sọ nínú ìwé kan tó pè ní Discoveries From the Time of Jesus, pé: “Ṣe ni òǹkàwé máa ń fi ọwọ́ òsì tú àkájọ ìwé náà lábala-lábala, bó bá sì ti kà á tán, á bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọwọ́ ọ̀tún ká a padà. Kí Jésù tó lè rí Aísáyà orí kọkànlélọ́gọ́ta tó kà nínú sínágọ́gù, àfàìmọ̀ ni kì í ṣe pé gbogbo àkájọ ìwé náà ló tú tán, tàbí kó tiẹ̀ ti ká a lákàátúnká.”

Lákòókò tá à ń sọ yìí, ìwé Aísáyà inú Bíbélì ò rí bó ṣe rí lónìí yìí, torí kò ní orí, kò sì ní ẹsẹ. Nígbà tí wọ́n fi àkájọ ìwé Aísáyà lé Jésù lọ́wọ́ ní sínágọ́gù ti Násárétì, ó ní láti kọ́kọ́ wá apá ibi tó fẹ́ kà, ìyẹn ibi tá a wá mọ̀ sí Aísáyà 61:1, 2 nínú Bíbélì tá à ń lò lónìí. Lọ́gán ni Jésù “rí ibi” tó fẹ́ kà náà, ìyẹn sì jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù mọ tinú tẹ̀yìn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́