Lílajú Sí Ìhìnrere
ÒWE Danish kan sọ pé, “àwọsánmà kò ṣaláì dúdú bí aró nítorí pé afọ́jú kò rí i.” Ṣùgbọ́n nínú ìgbòkègbodò ìgbésí-ayé wa ojoojúmọ́ tí ó há gádígádí, a ha rí i pé àwọsánmà dúdú bí aró, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe yẹ kí ó rí bí? A ha ń wo ọjọ́-ọ̀la pẹ̀lú ìgbọ́kànlé bí? A ha gba ìhìnrere tí Bibeli, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, gbékalẹ̀ gbọ́ bí?
Nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú, a ṣàyẹ̀wò apá tí ó jẹmọ́ ti ìfọ́jú níti ara ìyára. Nísinsìnyí ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò irú ìríran kan tí ó ṣe pàtàkì jù. Ó wémọ́ ayọ̀ wa wíwàpẹ́títí àti ọjọ́-ọ̀la àwọn olólùfẹ́ wa.
Láìsí iyèméjì, a dojúkọ “awọn àkókò lílekoko tí ó nira lati bálò.” (2 Timoteu 3:1, NW) Kí ni ń ṣẹlẹ̀ bí àwọn ènìyàn ti ń jìjàkadì láti gbé ìgbésí-ayé, tí wọ́n ń fàyàrán àwọn àìlera lílekoko àti àwọn ìṣòro ìdílé, tí wọ́n sì ń kojú àìsí-ìdájọ́ òdodo láàárín ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà àti àìsí ìfẹ́? Lọ́nà bíbaninínújẹ́, ọ̀pọ̀ rí i pé ìgbẹ́kẹ̀lé wọn nínú àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn, ìsìn, àti ìṣàkóso ti ń wọ̀ọ̀kùn. Ní rírí i pé kò sí ọ̀nà àbájáde, àwọn kan parí èrò pé a kò lè yanjú ìṣòro wọn lọ́nà tààrà. Nínú ìwé ìròyìn ilẹ̀ Brazil náà Jornal da Tarde, Jacob Pinheiro Goldberg ṣàkíyèsí pé: “Lójú ipò lílekoko, àwọn ènìyàn máa ń bínú gidigidi nítorí àwọn àṣìṣe débi pé wọn kìí ronú lọ́nà tí ó bọ́gbọ́nmu, wọ́n sì máa ń gbáralé ìsìn awo tí ń jánikulẹ̀.” Síbẹ̀, nígbà tí àwọn nǹkan bá ṣàìtọ́ pàápàá, a ń fẹ́ láti lo orí pípé, àbí a kìí fẹ́ bẹ́ẹ̀?
Fojú inú wò ó fún ìṣẹ́jú kan pé o nílò ilé kan fún ìdílé rẹ, owó kò sì jẹ́ ìṣòro. Bóyá o tilẹ̀ wò yíká tí o sì ṣèbẹ̀wò sí ọ̀kan-kò-jọ̀kan ilé ní àwọn àdúgbò yíyàtọ̀síra. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣojú talétalé gbìyànjú láti gba èrò rẹ rò, o kò rí irú ilé tí ó wù ọ́. Síbẹ̀, níwọ̀n bí ìtẹ́lọ́rùn àti ire ìdílé rẹ ti wémọ́ ọn, ìwọ kò jẹ́ juwọ́sílẹ̀, àbí? Nísinsìnyí wá wo bí ayọ̀ rẹ yóò ti pọ̀ tó nígbẹ̀yìn gbẹ́yín tí o bá rí irú ilé tí o ti ń lálàá rẹ̀.
Gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ yóò ti lo àkókò fún wíwá ilé titun kan, èéṣe tí o kò fi ṣàyẹ̀wò Bibeli láti rí ojútùú sí àwọn ìṣòro rẹ? Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ṣe níláti gbé àwọn òtítọ́ sórí ìwọ̀n nígbà tí a bá ń ṣe ìpinnu nípa ilé kan, bákan náà ni a gbọ́dọ̀ ronú lọ́nà yíyèkooro lórí ohun tí a bá kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Èyí tí ó sì tún ṣàǹfààní ju rírí ilé kan ni rírí àti gbígbà tí a gba òtítọ́ nípa Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi. Jesu wí pé: “Ìyè àìnípẹ̀kun náà sì ni èyí, kí wọn kí ó lè mọ̀ ọ́, ìwọ nìkan Ọlọrun òtítọ́, àti Jesu Kristi, ẹni tí ìwọ rán.”—Johannu 17:3
Ṣùgbọ́n bí ìhìn-iṣẹ́ Bibeli bá níyelórí tóbẹ́ẹ̀, èéṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi fọ́jú sí ìhìnrere rẹ̀ síbẹ̀síbẹ̀? Ìdí kan, tí ó sì lè ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́nu, ni pé, “gbogbo ayé ni ó wà ní agbára ẹni búburú nì.” (1 Johannu 5:19) Ní ìyọrísí rẹ̀, Satani Eṣu “ti sọ ọkàn àwọn tí kò gbàgbọ́ di afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere Kristi tí ó lógo, ẹni tíí ṣe àwòrán Ọlọrun, kí ó máṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn.” (2 Korinti 4:4) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú wa ni a fi ń ríran, ọpọlọ ni ó ń túmọ̀ ìmọ́lẹ̀ tí ń wọ inú ojú wa. Nítorí náà, jíjẹ́ afọ́jú ni a tún túmọ̀sí jíjẹ́ “ẹni tí kò ní agbára tàbí ìmúratán láti wòyemọ̀ tàbí ṣe ìdíyelé.” Èyí mú wa rántí àṣàyàn ọ̀rọ̀ lílókìkí kan pé: “Kò sí afọ́jú tí ó dàbí àwọn tí kò fẹ́ ríran.”
Ẹnìkan tí ó fọ́jú kò lè rí ohun tí ó wà níwájú rẹ̀, nítorí náà, ó wà nínú ewu fífarapa. Kò ṣeéṣe láti ṣàtúnṣe ìfọ́jú ọ̀pọ̀lọpọ̀ níti ara ìyára nísinsìnyí, síbẹ̀síbẹ̀ kò sí ẹnìkan tí ó pọndandan fún láti wà ní afọ́jú nípa tẹ̀mí.
Bíborí Ìfọ́jú Nípa Tẹ̀mí
Gan-an gẹ́gẹ́ bí àìsí ìmọ́tótó tí ó yẹ ṣe lè kó àárẹ̀ bá ojú ìríran, àyíká asọnidìbàjẹ́ lè pakún ìfọ́jú níti ọ̀nà-ìwàhíhù. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jesu Kristi ṣe kìlọ̀kìlọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dá àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́. Ó mú un ṣe kedere pé àwọn aṣáájú ìsìn nígbà náà lọ́hùn-ún ń ṣi agbo wọn lọ́nà: “Afọ́jú tí ń fọ̀nà han afọ́jú ni wọ́n. Bí afọ́jú bá sì ń fọ̀nà han afọ́jú, àwọn méjèèjì ni yóò ṣubú sínú ihò.”—Matteu 15:14.
Dípò dídi ẹni tí àwọn afọ́jú aṣáájú tànjẹ, ẹ wo bí àwọn wọnnì tí wọ́n la ojú wọn sí ìhìnrere nípa Ìjọba Ọlọrun ti jẹ́ aláyọ̀ tó! Jesu polongo pé: “Nítorí ìdájọ́ ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran, lè ríran.” (Johannu 9:39) Ṣùgbọ́n, báwo ni àwọn afọ́jú nípa tẹ̀mí ṣe lè ríran? Ó dára, ẹ jẹ́ kí a máa bá ìgbéyẹ̀wò wa nípa ìfọ́jú níti ara ìyára nìṣó.
Onírúurú àwọn ìpèsè ti wà ní àrọ́wọ́tó nísinsìnyí fún àwọn tí ojú ń dùn. Èyí kò fi ìgbà gbogbo rí bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀. Kò sí ìgbìdánwò kan pàtàkì tí a ṣe láti ṣèrànwọ́ fún àwọn afọ́jú ṣáájú kí Valentin Haüy tó dá àkànṣe ilé-ẹ̀kọ́ sílẹ̀ fún àwọn afọ́jú ní 1784. Lẹ́yìn èyí, Louis Braille hùmọ̀ ètò-ìgbékalẹ̀ ìwé àwọn afọ́jú; ó ṣe bẹ́ẹ̀ láti lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ojú ń dùn lati kàwé.
Àwọn tí wọ́n fọ́jú nípa tẹ̀mí ńkọ́? Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí a ti ṣe ìsapá gidigidi láti polongo ìhìnrere náà àní ní àwọn apá ibi tí ó jẹ́ àdádó jùlọ ní ayé. (Matteu 24:14) Ó dùn mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nínú láti mú ìrètí wá fún àwọn afọ́jú lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ àti àwọn afọ́jú nípa ti ara.
Obìnrin ará Brazil kan kọ̀wé pé: “Àní láìka àìlera mi nípa ti ara sí, mo lè ríran—nípa ti ẹ̀mí. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ Ọlọrun ìyanu tó! A láyọ̀ láti mọ̀ pé ‘Jehofa yóò ṣí ọwọ́ rẹ̀ yóò sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.’” (Orin Dafidi 145:16) Jorge pẹ̀lú, tí ó jẹ́ afọ́jú nípa ti ara, rántí pé: “A lè pín ìgbésí-ayé mi sí ipa méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀: ṣáájú àti lẹ́yìn àwọn Ẹlẹ́rìí náà. . . . Nípasẹ̀ wọn, mo bẹ̀rẹ̀ sí róye ayé lọ́nà ṣíṣe kedere tí ó sì kún fún ìrètí. Mo gbádùn ìrẹ́pọ̀ pípegedé pẹ̀lú gbogbo ènìyàn nínú ìjọ.” Bí ìyẹn ti jẹ́ ohun gbígbádùnmọ́ni tó, Bibeli fún wa ní ìdánilójú pé láìpẹ́ kò ní sí afọ́jú kankan mọ́ lórí ilẹ̀-ayé—níti ara ìyára tàbí nípa tẹ̀mí. Báwo ni ìyẹn yóò ṣe wáyé? Báwo ni yóò ṣe jásí òtítọ́ jákèjádò ayé pé “Oluwa ṣí ojú àwọn afọ́jú”?—Orin Dafidi 146:8.
Ìwòsàn Wíwàpẹ́títí Kanṣoṣo—Ìjọba Ọlọrun
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òye jíjáfáfá nínú ìmọ̀ ìṣègùn túbọ̀ ń gbilẹ̀ síi, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn àìsàn ń báa nìṣó láti máa ṣokùnfà ìfọ́jú, ìrora, àti ikú. Kí ni a nílò nígbà náà, láti rẹ́yìn àìjẹunrekánú, àwọn ipò àìsí ìmọ́tótó tí ó yẹ, àti ìkìmọ́lẹ̀ tí ń gba ojú àti ayọ̀ ìgbésí-ayé lọ́wọ́ ẹni? Iṣẹ́ ìwòsàn Jesu fún àwọn afọ́jú àti àwọn mìíràn jẹ́ àpẹẹrẹ kékeré nípa ọjọ́-ọ̀la. Lọ́nà tí ó múniláyọ̀, ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ ìmúláradá rẹ̀ jẹ́ àmì àpẹẹrẹ àwọn ìbùkún tí a óò nasẹ̀ rẹ̀ dé orí ilẹ̀-ayé lábẹ́ àkóso Ìjọba Ọlọrun.
Ìmúláradá lọ́nà tí ó kárí-ayé kù sí dẹ̀dẹ̀.a Ètò ìmúláradá àtọ̀runwá yìí ní aposteli Johannu ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà rírẹwà pé: “Ó sì fi odò omi ìyè kan hàn mí, tí ó mọ́ bí Kristali, tí ń ti ibi ìtẹ́ Ọlọrun àti ti Ọ̀dọ́-Àgùtàn jáde wá. Ní àárín ìgboro rẹ̀, àti níhà ìkínní kejì odò náà, ni igi ìyè gbé wà, tíí máa so onírúurú èso méjìlá, a sì máa so èso rẹ̀ ní oṣooṣù: ewé igi náà sì ni fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè láradá.”—Ìfihàn 22:1, 2.
Àwọn gbólóhùn bíi “omi ìyè” àti “igi ìyè” ń fihàn pé lẹ́yìn tí ètò-ìgbékalẹ̀ búburú tòní bá ti wá sópin, àwọn ìpèsè awonisàn ti Ìjọba Ọlọrun yóò gbé aráyé ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ dé ipò ìjẹ́pípé. Ní tòótọ́, àwọn àǹfààní ẹbọ ìràpadà Jesu (títíkan ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ pátápátá), papọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ nípa Jesu Kristi àti Baba rẹ̀, yóò mú ìlera pípé àti ìyè àìnípẹ̀kun wá.—Johannu 3:16.
Ayọ̀ Nínú Ayé Titun Ọlọrun
Nígbà náà, fojú inú wo ilẹ̀-ayé náà nínú èyí tí kò ti sí ìwà-ọ̀daràn, bíba àyíká jẹ́, tàbí òṣì mọ́. Wo ìdílé rẹ tí ń gbé lálàáfíà nínú Paradise tí a mú padàbọ̀sípò náà. (Isaiah 32:17, 18) Ẹ wo bí yóò ti gbádùnmọ́ni tó láti wo onírúurú àwọ̀ pẹ̀lú ọkàn àti orí pípé!
Faber Birren sọ pé, “Ó jẹ́ ìwà ẹ̀dá ènìyàn láti máa gbé lábẹ́ ipò àyíká kan—tí ìmọ́lẹ̀, àwọ̀, àti ìrísí rẹ̀ ń yípadà nígbà gbogbo. Kò sí ohun kan bí àyíká tí kìí yípadà tí kò sì fanimọ́ra nínú ìṣẹ̀dá. Àwọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun gbígbádùnmọ́ni nínú ìṣẹ̀dá ti ayé yìí. Ó jẹ́ ìlànà wíwọ́pọ̀ ti ìṣẹ̀dá, kò ní àyàfi kankan, púpọ̀ lára àwọn adùn ìgbésí-ayé sì sinmi lé e.”
Ẹ wo bí ẹ̀bùn ìríran ti ṣeyebíye tó! Ẹ sì wo bí yóò ti jẹ́ ìdùnnú tó nígbà tí ojú tí ó ti fọ́ nígbà kan rí—níti ara ìyára tàbí nípa tẹ̀mí—bá là!
Bẹ́ẹ̀ni, nínú Paradise tí a múpadàbọ̀sípò tí ń bọ̀ náà, ìfọ́jú àti àwọn àbùkù-ara mìíràn kí yóò mú àìláyọ̀ wá mọ́! Kò sí ẹni tí a óò ṣì lọ́nà mọ́. Níwọ̀n bí ojúlówó ìfẹ́ yóò ti tànkálẹ̀, a óò la gbogbo ènìyàn lóye nípa tẹ̀mí. Ìyẹn, àti ọ̀pọ̀ jaburata síi, wà gẹ́rẹ́ níwájú, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ni àkókò náà láti di ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ẹni náà tí yóò mú ìlérí alásọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣẹ pé: “Nígbà náà ni ojú àwọn afọ́jú yóò là”!—Isaiah 35:5.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Jọ̀wọ́ ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí tí a pèsè nínú ìwé náà Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, orí 18, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Nígbà náà ni ojú àwọn afọ́jú yóò là!