ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 8/15 ojú ìwé 3-4
  • Ìrètí Wo Ni Ó Wà Fún Àwọn Afọ́jú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrètí Wo Ni Ó Wà Fún Àwọn Afọ́jú?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Líla Ojú Àwọn Afọ́jú ní Ọjọ́ Jesu
  • Lílajú Sí Ìhìnrere
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ran Àwọn Afọ́jú Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Mọ Jèhófà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Jésù La Ojú Ọkùnrin Kan Tí Wọ́n Bí Ní Afọ́jú
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Mímú Ọkunrin kan Tí A Bí Ní Afọ́jú Láradá
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 8/15 ojú ìwé 3-4

Ìrètí Wo Ni Ó Wà Fún Àwọn Afọ́jú?

JOHN MILTON ṣàkójọ ewì rẹ̀ Paradise Lost àti Paradise Regained bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fọ́jú pátápátá. Jíjẹ́ afọ́jú àti adití kò dá Helen Keller dúró nínú ìsapá rẹ̀ láti kọ́ àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ abirùn kí ó sì ṣèrànwọ́ fún wọn. Bẹ́ẹ̀ni, ọ̀pọ̀ àwọn afọ́jú ń kojú ìṣòro náà dáradára. Ṣùgbọ́n ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ohun àgbàyanu tó bí gbogbo ènìyàn bá lè gbádùn agbára ìríran dídára! Ìwọ lè gbà ní pàtàkì bí o bá ní olólùfẹ́ tàbí ọ̀rẹ́ kan tí ó jẹ́ afọ́jú tàbí tí ojú ń dùn.

Lóòótọ́, ní àwọn ilẹ̀ kan ètò amúlerasọjí ń kọ́ àwọn ènìyàn tí ojú ń dùn ní òye-iṣẹ́ gbígbé ìgbésí-ayé ojoojúmọ́. Ìwé àwọn afọ́jú àti àwọn ajá afinimọ̀nà tí a ti dálẹ́kọ̀ọ́ ń ṣèrànwọ́ fún àwọn afọ́jú láti bójútó ọ̀pọ̀ àwọn àìní wọn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn wo ìfọ́jú gẹ́gẹ́ bí àbùkù-ara dídáyàfoni jùlọ. Òǹkọ̀wé kan kéde pẹ̀lú ìtẹnumọ́ pé: “Ẹni tí ó fọ́jú pàdánù òmìnira láti lo apá ṣíṣe pàtàkì jùlọ nínú àgbáyé wa tí a lè róye rẹ̀.” Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ níláti túbọ̀ gbáralé àwọn ẹlòmíràn.

O lè ṣe kàyéfì pé, èéṣe tí ìfọ́jú fi gbilẹ̀ tóbẹ́ẹ̀? Ó dára, ṣé o ti gbọ́ nípa àrùn ojú pípọ́n tí ń ṣepin? Òun ní okùnfà fún iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó million mẹ́sàn-án ọ̀ràn ìfọ́jú. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ nípa rẹ̀ pé: “Àrùn náà ń ranni ó sì ń gbèèràn ní agbègbè tí kò sí ìmọ́tótó tí àwùjọ àwọn ènìyàn ti hámọ́ra gádígádí. Àìtó omi fún fífọ nǹkan, àti ẹgbàágbèje eṣinṣin tí ń kun ìgbẹ́ ènìyàn, ń ṣèrànwọ́ láti pín àrùn náà káàkiri. Ní àwọn ọ̀nà kan àrùn ojú pípọ́n tí ń ṣepin tanmọ́ ìṣòro ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ju ti ìṣègùn; bí a bá lè mú ipò ìgbésí-ayé sunwọ̀n síi, tí a dín híhámọ́ra gádígádí kù, tí a kò gba eṣinṣin láàyè, tí a sì rí sí i pé ìpèsè omi tí ó tó wà, ìwọ̀n tí àrùn ojú pípọ́n tí ń ṣepin fi ń yára tànkálẹ̀ yóò dínkù gidigidi.” Nǹkan bíi million kan mìíràn ń jìyà lọ́wọ́ àrùn onchocerciasis, tàbí ìfọ́jú inú odò. Tàbí kí ni nípa ti àrùn ẹbọ́ ojú? Ó jẹ́ okùnfà wíwọ́pọ̀ fún ìfọ́jú.

Àrùn àtọ̀gbẹ, gbọ̀fun gbọ̀fun, èéyi, ibà amáraléròrò, àti àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń tàtaré rẹ̀ tún lè jálẹ̀ sí ìfọ́jú.

Bí a ti ń dàgbà síi, agbára ìríran wa lè máa jó rẹ̀yìn gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí àwọn ìṣiṣẹ́gbòdì bíi ojú dídáranjẹ̀ àti àrùn ojú ṣíṣú, bẹ́ẹ̀ sì ni a kò le fojú kékeré wo àfòta. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica ṣàlàyé pé: “Àfòta ṣì wa ní ipò iwájú nínú àkọsílẹ̀ àwọn okùnfà ìfọ́jú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lágbàáyé, èyí sì túbọ̀ ń fa ìbànújẹ́ nítorí tí ó rọrùn láti fi iṣẹ́-abẹ wò ó sàn.”

Láìka àwọn àwárí titun nínú ẹ̀kọ́ nípa ìṣiṣẹ́ àti àrùn ojú sí, kíkásẹ̀ ìfọ́jú nílẹ̀ dàbí ohun jíjìnnà réré. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan náà sọ pé: “Ìtẹ̀síwájú nínú dídènà àrùn àti fífi egbòogi àti iṣẹ́-abẹ bójútó ìfọ́jú lè ṣàǹfààní fún kìkì àwọn àwùjọ ènìyàn tí wọ́n ní àǹfààní ìtọ́jú ìṣègùn. Ìfọ́jú tí ó ṣe é dènà yóò ṣì wà ní ìwọ̀n gíga rẹ̀ ti ìsinsìnyí, títí di ìgbà tí a bá tó mú ipò ìṣètò oúnjẹ àti ìmọ́tótó ti apá tí ó pọ̀ jùlọ nínú iye ènìyàn lágbàáyé sunwọ̀n síi.”

Nígbà tí ó dájú pé iṣẹ́-abẹ àti àwọn oògùn agbógun-ti-kòkòrò-àrùn ní àyè tiwọn nínú gbígbógunti ìfọ́jú, ìrètí ìwòsàn wíwàpẹ́títí níí ṣe pẹ̀lú ohun kan tí ó ṣẹlẹ̀ ní ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn.

Líla Ojú Àwọn Afọ́jú ní Ọjọ́ Jesu

Fojú inú wo ọkùnrin kan tí ó lé díẹ̀ ní 30 ọdún tí ń rìn lójú ọ̀nà eléruku. Bí wọn ṣe gbọ́ pé ó ń kọjá lọ, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tí wọ́n wà lẹ́bàá ọ̀nà kígbe sókè pé: “Ṣàánú fún wa.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òǹwòran pàṣẹ pé kí wọ́n panumọ́, àwọn afọ́jú náà túbọ̀ kígbe lóhùn rara pé: “Ṣàánú fún wa.” Ọkùnrin náà fi pẹ̀lú inúrere béèrè pé “Kí ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi kí ó ṣe fún yín?” Wọ́n fi ìháragàgà dáhùn pé: “Kí ojú wa kí ó lè là.” Rò ó wò nísinsìnyí: Ọkùnrin náà fi ọwọ́ tọ́ wọn ní ojú, ojú wọn sì là lọ́gán!​—⁠Matteu 20:​29-⁠34.

Ẹ wo bí ayọ̀ àwọn ọkùnrin afọ́jú tẹ́lẹ̀rí yìí ti kún tó! Síbẹ̀, ìfọ́jú wọ́pọ̀ gan-⁠an. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan péré ní èyí jẹ́. Èéṣe tí ó fi yẹ kí ó gba àfiyèsí rẹ? Nítorí pé Jesu ti Nasareti ni ó ṣíjú àánú wo àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn nípa mímú kí wọ́n ríran. Ní tòótọ́, yàtọ̀ sí jíjẹ́ ẹni tí a fi ‘àmì-òróró yàn láti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì,’ Jesu ni a ‘rán láti pèsè ìtúnríran fún awọn afọ́jú.’​—⁠Luku 4:⁠18.

Irú ìwòsàn lọ́nà ìyanu tí ẹ̀mí mímọ́ lílágbára ti Ọlọrun ṣe yìí ya àwọn ènìyàn lẹ́nu. A kà pé: “Ẹnu ya ìjọ ènìyàn náà, nígbà tí wọ́n rí tí odi ń fọhùn, tí arọ ń di ọ̀tọtọ, tí amọ́kùn-⁠ún ń rìn, tí afọ́jú sì ń ríran: wọ́n sì yin Ọlọrun Israeli lógo.” (Matteu 15:31) Láì gbowó tàbí ṣe àṣehàn ara-ẹni tàbí wá ògo ti araarẹ̀ nínú irú ìmúláradá bẹ́ẹ̀, Jesu fi ìfẹ́ àti àánú Jehofa Ọlọrun hàn gbangba. Bí ó tiwù kí ó rí, Jesu tún ní ìyọ́nú fún àwọn afọ́jú nípa tẹ̀mí àti àwọn ènìyàn aláìlólùrànlọ́wọ́ tí wọ́n “túká kiri bí àwọn àgùtàn tí kò ní olùṣọ́.”​—⁠Matteu 9:⁠36.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irú ọ̀rọ̀-ìtàn yẹn lè jẹ́ èyí tí o fani lọ́kàn mọ́ra, o lè ṣe kàyéfì pé, Lónìí ńkọ́? Níwọ̀n bí kò ti sí ẹnikẹ́ni lónìí tí ń wonisàn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣe, àwọn ìmúláradá wọnnì ha ní ìtumọ̀ kan fún wa bí? Ìrètí èyíkéyìí ha wà fún àwọn afọ́jú bí? Jọ̀wọ́ ka ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

“Ìfọ́jú tí ó ṣe é dènà yóò ṣì wà ní ìwọ̀n gíga rẹ̀ ti ìsinsìnyí, títí di ìgbà tí a bá tó mú ipò ìṣètò oúnjẹ àti ìmọ́tótó ti apá tí ó pọ̀ jùlọ nínú iye ènìyàn lágbàáyé sunwọ̀n síi.”​—⁠Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́