ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 70 ojú ìwé 166-ojú ìwé 167 ìpínrọ̀ 2
  • Jésù La Ojú Ọkùnrin Kan Tí Wọ́n Bí Ní Afọ́jú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jésù La Ojú Ọkùnrin Kan Tí Wọ́n Bí Ní Afọ́jú
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mímú Ọkunrin kan Tí A Bí Ní Afọ́jú Láradá
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Awọn Farisi Mọ̀ọ́mọ̀ Ṣaigbagbọ
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Àwọn Farisí Gbọ́ Tẹnu Ọkùnrin Afọ́jú Náà
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Jésù Wo Ẹnì Kan Sàn Lọ́jọ́ Sábáàtì
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 70 ojú ìwé 166-ojú ìwé 167 ìpínrọ̀ 2
Ọkùnrin afọ́jú kan ríran lẹ́yìn tó lọ wẹ̀ nínú odò Sílóámù

ORÍ 70

Jésù La Ojú Ọkùnrin Kan Tí Wọ́n Bí Ní Afọ́jú

JÒHÁNÙ 9:1-18

  • JÉSÙ LA OJÚ ALÁGBE KAN TÍ WỌ́N BÍ NÍ AFỌ́JÚ

Jerúsálẹ́mù ni Jésù ṣì wà lọ́jọ́ Sábáàtì. Bí òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe ń gba àárín ìlú náà kọjá, wọ́n rí ọkùnrin afọ́jú kan tó ń tọrọ owó. Àtìgbà tí wọ́n ti bí ọkùnrin náà ló ti fọ́ lójú, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bi Jésù pé: “Rábì, ta ló ṣẹ̀ tí wọ́n fi bí ọkùnrin yìí ní afọ́jú, ṣé òun ni àbí àwọn òbí rẹ̀?”—Jòhánù 9:2.

Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbà pé ọkùnrin náà ò sí níbì kankan ṣáájú kí wọ́n tó bí i, síbẹ̀ wọ́n lè máa wò ó pé ó ṣeé ṣe kí ọmọ kan dẹ́ṣẹ̀ nígbà tó ṣì wà nínú ìyá rẹ̀. Jésù dáhùn pé: “Kì í ṣe ọkùnrin yìí ló ṣẹ̀, kì í sì í ṣe àwọn òbí rẹ̀, àmọ́ ó rí bẹ́ẹ̀ ká lè fi àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.” (Jòhánù 9:3) Torí náà, kì í ṣe ọkùnrin yìí tàbí àwọn òbí rẹ̀ ló hùwà burúkú tàbí dá ẹ̀ṣẹ̀ tó sọ ọkùnrin náà di afọ́jú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún ló sọ gbogbo èèyàn di aláìpé, ìyẹn ló sì ń jẹ́ ká ní àìlera bíi ti ọkùnrin tó fọ́ lójú yìí. Àmọ́ bí ọkùnrin náà ṣe jẹ́ afọ́jú mú kó ṣeé ṣe fún Jésù láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ bí Ọlọ́run ṣe lágbára tó. Ohun yìí kan náà ló sì ṣe nígbà tó wo onírúurú èèyàn sàn ṣáájú ìgbà yẹn.

Jésù wá tẹnu mọ́ bí iṣẹ́ Ọlọ́run ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó, nígbà tó sọ pé: “A gbọ́dọ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ Ẹni tó rán mi ní ojúmọmọ; òru ń bọ̀ nígbà tí èèyàn kankan ò ní lè ṣiṣẹ́. Tí mo bá ṣì wà ní ayé, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” (Jòhánù 9:4, 5) Òótọ́ sì ni, torí láìpẹ́ sí ìgbà yẹn Jésù máa kú, inú sàréè tí kò sí ìmọ́lẹ̀ ló máa wà, kò sì ní lè ṣe ohunkóhun níbẹ̀. Àmọ́ ní báyìí tí Jésù ò tíì kú, ó ń jẹ́ káwọn èèyàn rí ìmọ́lẹ̀.

Jésù fi nǹkan tó pò pọ̀ sí ojú ọkùnrin afọ́jú kan

Ṣé Jésù máa la ojú ọkùnrin náà, tó bá máa ṣe bẹ́ẹ̀, báwo ló ṣe máa ṣe é? Ohun tí Jésù ṣe ni pé, ó tutọ́ sílẹ̀, ó sì pò ó mọ́ iyẹ̀pẹ̀. Ó wá fi sí ojú ọkùnrin náà, ó sì sọ fún un pé: “Lọ wẹ̀ nínú odò Sílóámù.” (Jòhánù 9:7) Ọkùnrin náà ṣe ohun tí Jésù ní kó ṣe. Bó ṣe ṣe é báyìí ló ríran! Ẹ wo bí inú ẹ̀ ṣe máa dùn tó, torí ìgbà àkọ́kọ́ rèé tó máa ríran látìgbà tí wọ́n ti bí i!

Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn ará àdúgbò àtàwọn míì tó mọ ọkùnrin náà sí afọ́jú. Torí náà, wọ́n ń bi ara wọn pé: “Ṣebí ọkùnrin tó máa ń jókòó ṣagbe nìyí, àbí òun kọ́?” Àwọn kan dáhùn pé: “Òun ni.” Àmọ́ àwọn míì ò gbà gbọ́, wọ́n ní: “Rárá o, àmọ́ ó jọ ọ́.” Lọkùnrin yẹn fúnra ẹ̀ bá dá wọn lóhùn pé: “Èmi ni.”—Jòhánù 9:8, 9.

Wọ́n wá bi í pé: “Báwo wá ni ojú rẹ ṣe là?” Ó ní: “Ọkùnrin tí wọ́n ń pè ní Jésù ló po nǹkan kan, ó sì fi pa ojú mi, ó wá sọ fún mi pé, ‘Lọ wẹ̀ ní Sílóámù.’ Mo wá lọ wẹ̀, mo sì ríran.” Ni wọ́n bá bi í pé: “Ibo ni ọkùnrin náà wà?” Ọkùnrin alágbe náà dáhùn pé: “Mi ò mọ̀.”—Jòhánù 9:10-12.

Wọ́n wá mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisí, torí àwọn náà fẹ́ mọ bí ojú rẹ̀ ṣe là. Ó ṣàlàyé fún wọn pé: “Ó po nǹkan kan, ó sì fi sí ojú mi, mo wá lọ wẹ̀, mo sì ríran.” Dípò káwọn Farisí yẹn bá ọkùnrin alágbe náà yọ̀ pé ojú rẹ̀ ti là, ṣe làwọn kan lára wọn ń ṣàríwísí ohun tí Jésù ṣe. Wọ́n sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ ni ọkùnrin yìí ti wá, torí kì í pa Sábáàtì mọ́.” Àmọ́ àwọn míì sọ pé: “Báwo ni ọkùnrin tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe lè ṣe irú àwọn iṣẹ́ àmì bẹ́ẹ̀?” (Jòhánù 9:15, 16) Bó ṣe di pé ohùn wọn ò ṣọ̀kan nìyẹn.

Ní báyìí tọ́rọ̀ náà ti dà rú mọ́ wọn lójú, wọ́n yíjú sí ọkùnrin náà, wọ́n sì bi í pé: “Nígbà tó jẹ́ pé ojú rẹ ni ọkùnrin náà là, kí lo máa sọ nípa rẹ̀?” Kò ṣiyèméjì rárá nípa irú ẹni tí Jésù jẹ́, torí náà ó dá wọn lóhùn pé: “Wòlíì ni.”—Jòhánù 9:17.

Àwọn èèyàn náà ò gba ohun tó sọ gbọ́. Wọ́n lè máa rò ó pé ṣe ni Jésù àti ọkùnrin náà gbìmọ̀ pọ̀ kí wọ́n lè tan àwọn èèyàn jẹ. Torí náà, wọ́n gbà pé ohun tó máa yanjú ọ̀rọ̀ náà ni pé káwọn bi àwọn òbí ọkùnrin náà bóyá lóòótọ́ ni ojú rẹ̀ fọ́.

  • Kí ló mú kí ọkùnrin náà fọ́ lójú, àmọ́ kí ni kì í ṣe òótọ́ nípa ohun tó fà á?

  • Kí làwọn tó mọ ọkùnrin afọ́jú náà ṣe nígbà tí wọ́n rí i pé ojú rẹ̀ ti là?

  • Kí nìdí táwọn Farisí yẹn ò fi fohùn ṣọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́