Ẹ̀KỌ́ 85
Jésù Wo Ẹnì Kan Sàn Lọ́jọ́ Sábáàtì
Àwọn Farisí kórìíra Jésù, wọ́n sì ń wá bí wọ́n ṣe máa mú un. Wọ́n sọ pé kò gbọ́dọ̀ wo èèyàn sàn lọ́jọ́ Sábáàtì. Lọ́jọ́ Sábáàtì kan, Jésù rí afọ́jú kan tó ń tọrọ owó lójú ọ̀nà. Ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: ‘Ẹ máa rí bí agbára Ọlọ́run ṣe máa ran ọkùnrin yìí lọ́wọ́.’ Ni Jésù bá po itọ́ mọ́ iyẹ̀pẹ̀, ó sì fi sójú ọkùnrin náà. Lẹ́yìn náà, ó sọ fún un pé: ‘Lọ fọ ojú rẹ nínú adágún Sílóámù.’ Ọkùnrin yẹn ṣe bẹ́ẹ̀, bó ṣe ríran fún ìgbà àkọ́kọ́ láyé ẹ̀ nìyẹn.
Ẹnu ya àwọn èèyàn gan-an. Wọ́n sì ń sọ pé: ‘Ṣé ọkùnrin tó máa ń tọrọ owó nìyí àbí ẹni yìí kàn jọ ọ́ ni?’ Ọkùnrin náà sọ pé: ‘Èmi náà ni.’ Àwọn èèyàn wá bi í pé: ‘Báwo ló ṣe wá ríran?’ Nígbà tó ṣàlàyé fún wọn, wọ́n mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisí.
Ọkùnrin náà sọ fáwọn Farisí pé: ‘Jésù fi iyẹ̀pẹ̀ pa ojú mi, ó sì ní kí n lọ fọ̀ ọ́ kúrò. Mo ṣe bẹ́ẹ̀, mo sì ti ríran báyìí.’ Àwọn Farisí wá sọ pé: ‘Tí Jésù bá ń wo èèyàn sàn lọ́jọ́ sábáàtì, á jẹ́ pé kì í ṣe ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lagbára ẹ̀ ti wá.’ Àmọ́, àwọn kan sọ pé: ‘Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ lagbára ẹ̀ ti wá, kò ní lè woni sàn rárá.’
Àwọn Farisí pe àwọn òbí ọkùnrin náà, wọ́n sì bi wọ́n pé: ‘Báwo ni ọmọ yín ṣe ríran?’ Ẹ̀rù ń ba àwọn òbí ọkùnrin náà torí pé àwọn Farisí ti sọ pé tí ẹnikẹ́ni bá gba Jésù gbọ́, àwọn máa lé ẹni náà kúrò nínú sínágọ́gù. Torí náà, àwọn òbí ẹ̀ sọ pé: ‘A ò mọ bó ṣe ṣẹlẹ̀. Ẹ béèrè lọ́wọ́ ẹ̀.’ Àwọn Farisí wá bẹ̀rẹ̀ sí í da ìbéèrè bo ọkùnrin náà títí tó fi sọ pé: ‘Mo ti sọ gbogbo ohun tí mo mọ̀ fún yín, kí ló dé tí ẹ tún ń bi mí ní ìbéèrè? Inú bí àwọn Farisí yẹn gan-an, bí wọ́n ṣe ju ọkùnrin náà síta nìyẹn.
Jésù lọ wá ọkùnrin yẹn, ó sì bi í pé: ‘Ṣé o nígbàgbọ́ nínú Mèsáyà?’ Ọkùnrin náà sọ pé: ‘Màá nígbàgbọ́ nínú ẹ̀ tí mo bá mọ̀ ọ́n.’ Jésù wá sọ fún un pé: ‘Èmi ni Mèsáyà náà?’ Ẹ ò rí i pé Jésù láàánú àwọn èèyàn gan-an. Kì í ṣe pé Jésù kàn la ojú ọkùnrin yẹn nìkan, ó tún ràn án lọ́wọ́ kó lè nígbàgbọ́.
“Ẹ ti ṣàṣìṣe, torí pé ẹ ò mọ Ìwé Mímọ́, ẹ ò sì mọ agbára Ọlọ́run.”—Mátíù 22:29