ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/15 ojú ìwé 2-3
  • Ran Àwọn Afọ́jú Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Mọ Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ran Àwọn Afọ́jú Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Mọ Jèhófà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Máa Wàásù fún Àwọn Afọ́jú
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Lílajú Sí Ìhìnrere
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìrètí Wo Ni Ó Wà Fún Àwọn Afọ́jú?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Awọn Farisi Mọ̀ọ́mọ̀ Ṣaigbagbọ
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
km 5/15 ojú ìwé 2-3

Ran Àwọn Afọ́jú Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Mọ Jèhófà

1. Báwo ni Jésù ṣe fi ìyọ́nú hàn sí àwọn afọ́jú?

1 Ọjọ́ díẹ̀ péré ló kù tí wọ́n máa pa Jésù. Bó ṣe ń kúrò ní ìlú Jẹ́ríkò, àwọn afọ́jú méjì kan tó ń ṣagbe ké jáde sí i pé: “Olúwa, ṣàánú fún wa!” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àdánwò tí Jésù máa tó kojú ló gbà á lọ́kàn gan-an, ó dúró, ó ní kí wọ́n wá, ó sì la ojú wọn. (Mát. 20:29-34) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìyọ́nú tí Jésù ní sí àwọn afọ́jú?

2. Báwo la ṣe lè wàásù fún afọ́jú tá a bá rí níbi tí àwọn èèyàn pọ̀ sí?

2 Máa Ṣaájò Wọn: Tó o bá pà dé afọ́jú bóyá níbi táwọn èèyàn pọ̀ sí, sọ orúkọ rẹ fún un kò o sì ṣaájò rẹ̀. Torí pé àwọn èèyàn kì í sábà kà wọ́n sí, ẹni náà lè kọ́kọ́ máa fura sí ọ. Àmọ́, ojúlówó ìfẹ́ tó o bá fi hàn sí i àti bó o ṣe yọ̀ mọ́ ọn lè fí i lọ́kàn balẹ̀. Má ṣe gbàgbé pé ìṣòro ojú tí àwọn kan ní yàtọ̀ sí ti àwọn míì, ìyẹn sì lè pinnu ibi tó o máa ran onítọ̀hún lọ́wọ́ dé. Lẹ́yìn tó bá ti ṣaájò ẹni náà tàbí tó o ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un, o lè wá sọ fún pé o máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. O lè ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan fun un, irú bíi Sáàmù 146:8 tàbí Aísáyà 35:5, 6. Tí ẹni náà bá lè ka ìwé àwọn afọ́jú, béèrè pé ṣé ó máa fẹ́ gba ìtẹ̀jáde kan tá a ṣe fún àwọn afọ́jú tó máa jẹ́ kó mọ̀ sí i nípa Bíbélì. Ó sì tún lè bá a wa àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbohùn wọn sílẹ̀ jáde lórí ìkànnì jw.org/yo. Tí kọ̀ǹpútà rẹ̀ bá ní ètò orí kọ̀ǹpútà kan tó máa ń ka ohun tó wà lójú kọ̀ǹpútà síta, ìyẹn screen reader, ó máa jẹ́ kó gbádùn àwọn àpilẹ̀kọ tó wà lórí ìkànnì jw.org/yo àti àwọn ìtẹ̀jáde tó ṣeé wà jáde ní ẹ̀dà RTF (Rich Text Format).—Wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ohun Tó O Lè Ṣe Láti Ran Afọ́jú Lọ́wọ́.”

3. Báwo la ṣe lè wá àwọn afọ́jú ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa?

3 Máa Wá Àwọn Afọ́jú: A kì í sábà rí àwọn afọ́jú nígbà tá a bá ń wàásù láti ilé-dé-ilé, torí pé ọ̀pọ̀ lára wọn kì í fẹ́ bá àwọn èèyàn tí wọn ò mọ̀ rí tó wá bá wọn nílé sọ̀rọ̀. Torí náà, ó gba ìsapá gidi láti ‘wá wọn kàn’ ká lè wàásù fún wọn. (Mát. 10:11) Ǹjẹ́ o mọ ẹnì kan tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí ọmọ iléèwé rẹ kan tó jẹ́ afọ́jú? Lo ìdánúṣe, kó o bá wọn sọ̀rọ̀. Tí ilé ẹ̀kọ́ àwọn afọ́jú bá wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, o lè lọ fún wọn ní àwọn ìtẹ̀jáde wa tá a ṣe fún àwọn afọ́jú, ìyẹn Braille, kí wọ́n kó wọn sí yàrá ìkówèésí wọn. Ǹjẹ́ o mọ ẹnì kan tí ará ilé rẹ̀ kan jẹ́ afọ́jú? Ǹjẹ́ àwọn àjọ kan wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín tí wọ́n ń pèsè ìrànwọ́ fún àwọn afọ́jú tàbí tí wọ́n ní ilé tí wọ́n gba àwọn afọ́jú sí? Ṣàlàyé fún àwọn ará ilé ẹni náà, olùgbàlejò ilé iṣẹ́ náà tàbí olùdarí ilé iṣẹ́ náà pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ ran àwọn afọ́jú lọ́wọ́, a sì fẹ́ máa fún wọn ní àwọn ìtẹ̀jáde tá a ṣe fún àwọn afọ́jú tàbí àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbohùn wọn sílẹ̀. Fi ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì hàn án, jẹ́ kó mọ̀ pé Ọlọ́run máa fòpin sí ìṣòro ojú pátápátá. O tún lè fi fídíò kan tó wà lórí ìkànnì hàn án. A pe àkọlé rẹ̀ ní “Ọpẹ́lọpẹ́ Rẹ̀ Lára Mi.” Ó sọ nípa ọkùnrin afọ́jú kan tó jàǹfààní nínú Bíbélì tá a ṣe fún àwọn afọ́jú. Tó o bá ṣàlàyé ìdí tó o fi wá, àǹfààní lè ṣí sílẹ̀ fún ọ láti bá àwọn afọ́jú tó wà níbẹ̀ sọ̀rọ̀.

4. Kí la rí kọ́ nínú ìrírí Janet?

4 Arábìnrin afọ́jú kan tó ń jẹ́ Janet lọ sí ilé kan tí àwọn afọ́jú ń gbé. Ọ̀dọ́bìnrin kan ló kọ́kọ́ bá sọ̀rọ̀. Janet sọ fún un pé: “Jésù la ojú àwọn afọ́jú ká lè mọ̀ ohun tó máa ṣe fún gbogbo àwọn afọ́jú lọ́jọ́ iwájú.” Àwọn méjèèjì jọ ka Ìṣípayá 21:3, 4, lẹ́yìn náà Janet ṣàlàyé bí Ìjọba Ọlọ́run á ṣe mú ìlérí tí wọ́n kà yìí ṣẹ. Obìnrin náà kọ́kọ́ dákẹ́ lọ, ó wá sọ pé: “Mi ò tíì gbọ́ irú ọ̀rọ̀ yìí rí látẹnu afọ́jú bíi tèmi. Ọ̀pọ̀ èèyàn tí kì í ṣe afọ́jú gbà pé ohun tó mú kí ẹnì kan di afọ́jú ni pé onítọ̀hún tàbí àwọn baba ńlá rẹ̀ ti ṣe nǹkan burúkú kan nígbà kan.” Janet wá fi ìlujá tó ń ṣí ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ránṣẹ́ sí obìnrin náà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ní báyìí ẹ̀ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ ló ń kọ́ obìnrin náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

5. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè la ojú àwọn afọ́jú bíi ti Jésù, àwọn ìbùkún wo la máa rí tá a bá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn afọ́jú?

5 Lóòtọ́, a ò lè la ojú àwọn afọ́jú bíi ti Jésù, àmọ́ a lè ṣèrànwọ́ fún gbogbo àwọn tí ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí ti fọ́ èrò inú wọn lójú, títí kan àwọn afọ́jú. A lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (2 Kọ́r. 4:4) Jésù la ojú àwọn afọ́jú méjì náà nítòsí ìlú Jẹ́ríkò torí pé ‘àánú wọn ṣe é.’ (Mát. 20:34) Bíi ti Jésù, táwa náà bá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn afọ́jú, èyí á jẹ́ ká lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, ẹni tó máa fòpin sí ìṣòro ojú títí láé.

Ohun Tó O Lè Ṣe Láti Ran Afọ́jú Lọ́wọ́

  • Bá ẹni náà sọ̀rọ̀ ní tààràtà, àmọ́ má ṣe gbóhùn sókè. Àwọn afọ́jú ò lè ríran, àmọ́ wọ́n máa ń gbọ́rọ̀ dáadáa.

  • Gbé ọwọ́ rẹ wálẹ̀, jẹ́ kí ẹni náà di ọwọ́ rẹ mú tó o bá fẹ́ mú un rìn. Ó máa tẹ̀ lé ọ bó o ṣe rọra ń gbé ẹsẹ̀ bí ẹ ṣe rọra ń rìn. Ó ṣe pàtàkì pé kó o máa sọ fún ẹni náà kí ẹ tó dé etí gọ́tà, ibi tí òpó wà, tí nǹkan bá wà lójú ọ̀nà tàbí tó o bá rí nǹkan míì tó lè gbé e ṣubú.

  • Tẹ́ ẹ bá ń sọ̀rọ̀, o lè máa lo àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ohun téèyàn lè fojú rí, irú bíi “rí” tàbí “wo.” Àwọn afọ́jú náà máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. Wọ́n máa fi ojú inú “rí” ohun tí ò ń ṣàpèjúwe fún wọn, wọ́n sì tún máa ń lo agbára ìmòye míì tí wọ́n ní.

  • Ẹ jọ máa sọ̀rọ̀ níbi tí kò sí ariwo. Àwọn afọ́jú kì í sábà fẹ́ sọ̀rọ̀ níbi tí ariwo ti ń lọ lábẹ́lẹ̀ torí ìyẹn á jẹ́ kó ṣòro fún wọn láti mọ ohun tó ń lọ láyìíká wọn.

  • Tó o bá fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, jẹ́ kó mọ̀. Èyí ò ní jẹ́ kó máa dá nìkan sọ̀rọ̀ nígbà tí kò sí èèyàn lọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́.

  • Kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù Padà-Lọ-Ṣèbẹ̀wò (S-43), kó o sì fún akọ̀wé ìjọ yín tí ẹni náà bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ àmọ́ tí kì í ṣe ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín ló ń gbé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́