MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Wàásù fún Àwọn Afọ́jú
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Ọ̀pọ̀ àwọn afọ́jú ni kì í fẹ́ bá àwọn tí wọn ò mọ̀ rí sọ̀rọ̀. Torí náà, ó máa ń gba ọgbọ́n ká tó lè wàásù fún wọn. Jèhófà ò fọ̀rọ̀ àwọn afọ́jú ṣeré rárá. (Le 19:14) Àwa náà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ tá a bá ń wá bá a ṣe máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Ọlọ́run.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
“Wá” àwọn afọ́jú lọ. (Mt 10:11) Ṣé o mọ ẹnì kan tí afọ́jú wà nínú ìdílé rẹ̀? Ṣé ilé ìwé àwọn afọ́jú wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín tàbí àwọn àjọ tó ń pèsè ìrànwọ́ fún àwọn afọ́jú tàbí ibi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn afọ́jú? Ṣé ó ṣeé ṣe kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìwé wa tó wà lédè àwọn afọ́jú?
Fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ wọn. Tó o bá ṣe ohun tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ ẹ́ lọ́kàn, tó o sì fi tẹ̀rín tọ̀yàyà bá wọn sọ̀rọ̀, ìyẹn á jẹ́ kára tù wọ́n. O lè fi ohun tí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ sí bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò rẹ
Ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Jèhófà. Ètò Ọlọ́run ti pèsè onírúurú ìtẹ̀jáde ká lè ṣèrànwọ́ fáwọn afọ́jú àtàwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ríran dáadáa. O lè bi í pé èwo ló nífẹ̀ẹ́. Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn rí i pé ìránṣẹ́ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ béèrè fún irú èyí tí afọ́jú tó wà ládùúgbò yín bá nífẹ̀ẹ́ sí