Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ June 1
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 1
Orin 13 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 25 ìpínrọ̀ 9 sí 16 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 16-18 (8 min.)
No. 1: 2 Sámúẹ́lì 17:14-20 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Tó Fi Ojúlówó Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Ṣèwà Hù Nínú Bíbélì (5 min.)
No. 3: Báwo Lo Ṣe Lè Fọgbọ́n Lo Ohun Ìní Rẹ?—igw ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 1 sí 4 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Ran onírúurú èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.—1 Tím. 2:3, 4.
10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Lóṣù June. Ìjíròrò. Kọ́kọ́ fi àwọn àbá tó wà lójú ìwé yìí ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin.
10 min: Máa Lo Àwọn Ìwé Ìkésíni Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́. Ìjíròrò. Nínú lẹ́tà tá a kọ́ sí gbogbo ìjọ ní November 27, 2014, a sọ fún wa pé a ti tẹ ìwé ìkésíni tuntun kan jáde tó máa wúlò lọ́nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀; a ó máa fi pe àwọn èèyàn láti wá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wa, “bóyá láwọn ìpàdé wa tàbí kí ẹnì kan máa wá kọ́ wọn.” Ìwé ìkésíni tuntun náà ní “àwòrán àwọn ará tó wà nípàdé àti ẹnì kan tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Bóyá ẹ ti gba ìwé ìkésíni yìí tàbí ẹ ò tíì gbà á, sọ bó ṣe máa wúlò tó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tàbí láti fi pe àwọn tó bá fìfẹ́ hàn wá sí àwọn ìpàdé wa. (km 12/05 ojú ìwé 4) Bi àwọn ará láwọn ìbéèrè yìí: (1) Ǹjẹ́ ẹ ní ìrírí kan tó gbádùn mọ́ni nígbà tẹ́ ẹ lo ìwé ìkésíni? (2) Lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, báwo la ṣe lè lò ó láti sọ ẹni tá a jẹ́ àti ìdí tá a fi wá fún àwọn èèyàn, ká sì bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú wọn? (3) Báwo la ṣe lè fi ìwé ìkésíni yìí ṣàlàyé tó nítumọ̀ nípa bí a ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́? (4) Kí làwọn òbí lè ṣe kí àwọn ọmọ wọn náà lè lo ìwé ìkésíni yìí lóde ẹ̀rí? (5) Báwo làwọn akéde tó ń fi lẹ́tà jẹ́rìí ṣe lè lo ìwé ìkésíni láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa àwọn ìpàdé wa? (6) Ọ̀nà tó gbéṣẹ́ wo lo ti gbà fi ìwé ìkésíni pe àwọn tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn tó fìfẹ́ hàn wá sí àwọn ìpàdé wa? Gba àwọn ará níyànjú láti máa lo ìwé ìkésíni tí wọ́n bá ń jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà, kí wọ́n sì máa ròyìn àwọn ìwé ìkésíni tí wọ́n bá fi sóde bí wọ́n ṣe ń ròyìn àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú.
10 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí? Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní nígbà tí wọ́n lo àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bó O Ṣe Lè Jẹ́rìí fún Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Míì.” Ní kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní.
Orin 25 àti Àdúrà