Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
October 15, 2008
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ Ọ̀SẸ̀:
December 1-7
Ojú Jèhófà “Títàn Yanran” Ń Ṣàyẹ̀wò Gbogbo Èèyàn
OJÚ ÌWÉ 3
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 160, 34
December 8-14
OJÚ ÌWÉ 7
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 81, 80
December 15-21
Jèhófà Dáhùn Àdúrà Àtọkànwá Tí Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Kan Gbà
OJÚ ÌWÉ 12
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 74, 90
December 22-28
Ṣé O Ń Mú Ipò Iwájú Nínú Bíbu Ọlá Fáwọn Èèyàn?
OJÚ ÌWÉ 21
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 216, 155
December 29–January 4
Kí Lo Máa Yááfì Kó O Lè Ní Ìyè Àìnípẹ̀kun?
OJÚ ÌWÉ 25
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 177, 212
Ohun Táwọn Àpilẹ̀kọ Tá a Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dá Lé
Àpilẹ̀kọ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ 1 àti 2 OJÚ ÌWÉ 3 sí 11
Àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí mú un dá wa lójú pé Jèhófà mọ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa. Ó mọrírì ìfaradà wa, ó sì mọ ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn. Ó mọ gbogbo iṣẹ́ takuntakun tá à ń ṣe, kò sì sóhun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó fara sin lójú rẹ̀. Èyí jẹ́ ohun tó ń tù wá nínú gan-an ni.
Àpilẹ̀kọ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ 3 OJÚ ÌWÉ 12 sí 16
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wa la mọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 83:18. Àmọ́ àwọn ẹsẹ tó kù ńkọ́? Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ bí Sáàmù 83 ṣe fún àwa Kristẹni òde òní ní ìṣírí gidigidi.
Àpilẹ̀kọ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ 4 OJÚ ÌWÉ 21 sí 25
Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” Kí ló túmọ̀ sí láti máa bọlá fáwọn èèyàn? Àwọn wo ló yẹ kó máa bọlá fúnni, àwọn wo ló sì yẹ ká máa bọlá fún? Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Bíbélì tó bá dọ̀rọ̀ ká bọlá fúnni? Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ tó yẹ ká máa fi sílò lórí ọ̀ràn bíbọlá fúnni.
Àpilẹ̀kọ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ 5 OJÚ ÌWÉ 25 sí 29
Lọ́jọ́ kan Jésù béèrè pé: “Kí ni ènìyàn kan yóò fi fúnni ní pàṣípààrọ̀ fún ọkàn rẹ̀?” Báwo lo ṣe máa dáhùn ìbéèrè yẹn? “Ọkàn” wo ni Jésù ń tọ́ka sí? Kí ni ọ̀nà tó ò ń gbà gbé ìgbé ayé rẹ fi hàn nípa bó o ṣe mọyì ọkàn rẹ sí? Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o lè ṣàṣàrò dáadáa lórí àwọn ìbéèrè Jésù tó gba ìrònújinlẹ̀ yẹn.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ:
“Orúkọ Ọlọ́run Tó Tóbi Tó sì Jẹ́ Mímọ́ Jù Lọ Rèé Lóòótọ́”
OJÚ ÌWÉ 16
OJÚ ÌWÉ 17
Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Títù, Fílémónì àti Hébérù
OJÚ ÌWÉ 30