ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w08 10/15 ojú ìwé 16
  • “Orúkọ Ọlọ́run Tó Tóbi Tó sì Jẹ́ Mímọ́ Jù Lọ Rèé Lóòótọ́”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Orúkọ Ọlọ́run Tó Tóbi Tó sì Jẹ́ Mímọ́ Jù Lọ Rèé Lóòótọ́”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Orukọ Ọlọrun ati “Majẹmu Titun” Naa
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
  • Ọlọ́run Ní Orúkọ Kan!
    Jí!—2004
  • Kí Nìdí Tí Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican Fi Ṣeyebíye?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
w08 10/15 ojú ìwé 16

“Orúkọ Ọlọ́run Tó Tóbi Tó sì Jẹ́ Mímọ́ Jù Lọ Rèé Lóòótọ́”

Ọ̀gbẹ́ni Nicholas ará Cusa tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Jámánì ló sọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí nínú ìwàásù kan tó ṣe lọ́dún 1430.a Ọ̀gbẹ́ni yìí fẹ́ láti mọ̀ nípa oríṣiríṣi ẹ̀ka ẹ̀kọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa èdè Gíríìkì àti Hébérù, ó tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ọgbọ́n orí, ẹ̀kọ́ ìsìn, ìṣirò àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà. Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìlélógún, ó di ọ̀mọ̀wé nínú òfin Kátólíìkì. Lọ́dún 1448 ó di kádínà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì.

Ní nǹkan bí àádọ́ta-dín-lẹ́gbẹ̀ta [550] ọdún sẹ́yìn, ọ̀gbẹ́ni Nicholas kọ́ ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó kan sí abúlé Kues, tá a wá mọ̀ sí ìlú Bernkastel-Kues báyìí. Ìlú yìí wà ní nǹkan bí àádóje [130] kìlómítà lápá gúúsù ìlú Bonn, lórílẹ̀-èdè Jámánì. Ibi ìkówèésí kan tí wọ́n sọ ní orúkọ ọ̀gbẹ́ni Cusa ti wà nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó yẹn báyìí. Àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n kó síbẹ̀ ju ọ̀ọ́dúnrún ó lé mẹ́wàá [310] lọ. Ọ̀kan lára àwọn ìwé náà ni ìwé àfọwọ́kọ alábala tí wọ́n ń pè ní Cusanus 220. Nínú ìwé yìí, èèyàn lè rí ìwàásù tí Nicholas ará Cusa ṣe lọ́dún 1430. Nínú ìwàásù yẹn tí àkọlé rẹ̀ sọ pé, In principio erat verbum (èyí tó túmọ̀ sí: Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni Ọ̀rọ̀ náà wà) Ọ̀gbẹ́ni Nicholas lo ẹyọ ọ̀rọ̀ náà, Iehoua látinú èdè Látìn fún orúkọ Jèhófà.b Lójú ìwé 56 nínú ìwé náà, ọ̀rọ̀ kan wà níbẹ̀ tó sọ nípa orúkọ Ọlọ́run, ó kà pé: “Ọlọ́run ló fún ara rẹ̀ ní orúkọ yìí. Òun ni lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run. . . . Orúkọ Ọlọ́run tó tóbi tó sì jẹ́ mímọ́ jù lọ rèé lóòótọ́.” Ọ̀rọ̀ Nicholas yìí tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́ ni orúkọ Ọlọ́run wà nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù ti ìpilẹ̀ṣẹ̀.—Ẹ́kís. 6:3.

Látìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún ni wọ́n ti kọ ìwé àfọwọ́kọ alábala yìí, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé tí ọjọ́ rẹ̀ tíì pẹ́ jù lọ tí wọ́n ti túmọ̀ orúkọ Jèhófà látinú lẹ́tà Hébérù mẹ́rin náà sí “Iehoua.” Àkọsílẹ̀ yìí jẹ́ ẹ̀rí síwájú sí i pé kíkọ orúkọ Ọlọ́run lọ́nà tó fara jọ “Jèhófà” jẹ́ ọ̀nà tí wọ́n sábà máa ń gbà ṣe àdàkọ orúkọ Ọlọ́run láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wa.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn orúkọ mìíràn tí wọ́n tún mọ ọ̀gbẹ́ni Nicholas ará Cusa sí ni Nikolaus Cryfts (Krebs), Nicolaus Cusanus àti Nikolaus von Kues. Orúkọ abúlé tí wọ́n ti bí i lórílẹ̀-èdè Jámánì ló ń jẹ́ Kues.

b Ọ̀gbẹ́ni Nicholas ṣe ìwàásù yìí láti fi ti ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan lẹ́yìn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ibi ìkówèésí Cusa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́