ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w08 11/15 ojú ìwé 32
  • “Ìwé Orin Òkun” Ìwé Tí Wọ́n Kọ Láàárín Àkókò Méjì Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ìwé Orin Òkun” Ìwé Tí Wọ́n Kọ Láàárín Àkókò Méjì Kan
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iwe-afọwọkọ Bibeli kan Lede Heberu Ti Ó Jẹ́ Awokọṣe
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Awọn Iwe Akajọ Òkun Òkú—Àwárí Oniyebiye naa Ti A Buyìn Kún
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ohun Iyebíye Tí Wọ́n Rí Nínú Pàǹtírí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Awọn Iwe Akajọ Òkun Òkú—Iṣura Ti Kò Lẹ́gbẹ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
w08 11/15 ojú ìwé 32

“Ìwé Orin Òkun” Ìwé Tí Wọ́n Kọ Láàárín Àkókò Méjì Kan

WỌ́N pàtẹ àjákù àkájọ ìwé Hébérù kan tó ti wà láti nǹkan bí ọ̀rúndún keje tàbí ọ̀rúndún kẹjọ Sànmánì Kristẹni, sí ibi tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ń kó ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí nílùú Jerúsálẹ́mù ní May 22, ọdún 2007. Ìwé Ẹ́kísódù 13:19–16:1 tí wọ́n fọwọ́ kọ ni àjákù ìwé tí wọ́n pàtẹ náà. Lára ohun tó wà nínú ìwé náà ni orin tí wọ́n pè ní “Orin Òkun,” ìyẹn orin ìṣẹ́gun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá wọn nídè lọ́nà ìyanu ní Òkun Pupa. Kí nìdí tí ìpàtẹ àjákù àkájọ ìwé yìí fi ṣe pàtàkì?

Ohun tó mú kó ṣe pàtàkì ni ìgbà tí wọ́n kọ ìwé àfọwọ́kọ náà. Ó ṣẹlẹ̀ pé ní nǹkan bí ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn, wọ́n rí àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, èyí tí wọ́n kọ láàárín ọ̀rúndún kẹta ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni. Àmọ́ ṣáájú kí wọ́n tó rí àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú yìí, ìwé àfọwọ́kọ lédè Hébérù tí wọ́n rí tó pẹ́ jù láyé ni ìwé àfọwọ́kọ alábala tí wọ́n ń pè ní Aleppo Codex, èyí tí wọ́n kọ ní ọdún 930 Sànmánì Kristẹni. Yàtọ̀ sí àjákù àwọn ìwé bíi mélòó kan, kò tíì sí ìwé àfọwọ́kọ lédè Hébérù tí wọ́n rí pé wọ́n kọ láàárín ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni sí ọdún 930 Sànmánì Kristẹni, ìyẹn àkókò tó wà láàárín ìgbà tí wọ́n kọ Àkájọ Ìwé Òkun Òkú sí ìgbà tí wọ́n kọ ìwé àfọwọ́kọ alábala ti Aleppo Codex.

Ọ̀gbẹ́ni James S. Snyder tó jẹ́ olùdarí Ibi Ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ti Ísírẹ́lì sọ pé: “Ìwé Orin Òkun, ni ìwé àkájọ kan gbòógì tá a tún rí pé wọ́n kọ láàárín ìgbà tí wọ́n kọ Àkájọ Ìwé Òkun Òkú . . . àti ìgbà tí wọ́n kọ ìwé àfọwọ́kọ alábala Aleppo Codex.” Ó tún sọ pé ìwé àfọwọ́kọ yìí, àtàwọn ìwé inú Bíbélì yòókù tí wọ́n fọwọ́ kọ láyé ọjọ́un, “jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ tó fi hàn pé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kò yí pa dà látìgbà tí wọ́n ti kọ wọ́n.”

Wọ́n gbà pé àjákù àkájọ ìwé náà jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n ṣàwárí nínú sínágọ́gù ìlú Káírò ní Íjíbítì ní apá ìparí ọ̀rúndún kọkàndínlógún. Àmọ́ ṣá o, ọkùnrin kan tó máa ń ṣa àwọn ìwé àfọwọ́kọ lédè Hébérù jọ kò mọ bó ṣe ṣe pàtàkì tó, àfìgbà tó di àárín ọdún 1976 sí 1979 tó lọ fi han amọṣẹ́dunjú kan. Wọ́n ṣèwádìí láti mọ ìgbà tí àjákù àkájọ ìwé náà ti wà, wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ pa mọ́ títí dìgbà tí wọ́n pàtẹ rẹ̀ sí Ibi Ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ti Ísírẹ́lì.

Ọ̀gbẹ́ni Adolfo Roitman, tó jẹ́ ọ̀gá ní ẹ̀ka tí wọ́n ń pè ní Shrine of the Book, ní Ibi Ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, tó sì tún jẹ́ alábòójútó àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú sọ bí àjákù àkájọ ìwé náà ti ṣe pàtàkì tó, ó ní: “Ìwé Orin Òkun fi hàn pé àwọn Másórétì fòótọ́ inú ṣe iṣẹ́ ní gbogbo ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún tí wọ́n fi ń ṣàdàkọ Bíbélì, a sì lè fọkàn tán wọn. Ó gbàfiyèsí gan-an pé ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n gbà kọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Orin Òkun ti ọ̀rúndún keje sí ìkẹjọ kò yàtọ̀ sí tòde òní tó wà nínú Bíbélì.”

Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, Jèhófà fúnra rẹ̀ ló sì mú kí Bíbélì wà títí dòní. Bákan náà, àwọn tó ṣàdàkọ Ìwé Mímọ́ fara balẹ̀ kọ ọ́ dáadáa. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tá à ń lò lónìí ṣeé gbára lé gan-an.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Àwọn aláṣẹ Ibi Ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ti Ísírẹ́lì ló yọ̀ǹda àwòrán yìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́