Iwe-afọwọkọ Bibeli kan Lede Heberu Ti Ó Jẹ́ Awokọṣe
ṢAAJU ṣiṣawari Ìwé-kíká ti Òkun Òkú ni 1947, iwe-afọwọkọ Bibeli Lede Heberu ti a kọ́kọ́ mọ̀—yatọ sí awọn àjákù diẹ—jẹ́ lati ipari ọrundun kẹsan-an si ikọkanla C.E. Eyiini fẹrẹẹ tó ẹgbẹrun ọdun kan sẹhin. Eyi ha tumọsi pe ṣaaju 1947 awọn ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ iwe Bibeli Lede Heberu kò daju bi? Eesitiṣe ti ó fi jẹ́ pe iwọnba awọn iwe-afọwọkọ igbaani Lede Heberu ni ó wa?
Lati gbé ibeere ti ó gbẹhin yẹn yẹwo lakọọkọ, labẹ eto awọn Ju ti a tẹwọgba, eyikeyii ninu iwe-afọwọkọ Lede Heberu ti a bá kà si eyi ti ó ti gbó ju fun lílò ni a maa ń sémọ́ inu genizah, ibi ìkẹ́rùsí kan ninu sinagogu. Lẹhin naa, awọn iwe-afọwọkọ ogbologboo ti a tojọ pelemọ naa a di eyi ti a kó jade ti a sì bomọlẹ. Awọn Ju ṣe eyi lati ṣe idiwọ fun sisọ Iwe Mimọ wọn di alaimọ tabi eyi ti a ṣilo. Eeṣe? Nitori pe wọn ní Tetragrammaton, awọn lẹta èdè Heberu ti wọn duro fun orukọ mímọ́ Ọlọrun, eyi ti a sábà maa ń fihàn ninu Bibeli Lede Yoruba gẹgẹ bii “Jehofa.”
“Ade” Naa
Fun apá ti ó pọ̀ julọ, awọn ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ iwe Heberu igbaani ni a ti fi tootọtootọ ta àtaré wọn lati ìgbà pípẹ́ sẹhin wa. Fun apẹẹrẹ, iwe-afọwọkọ pataki kan Lede Heberu wà ti a pè ni Keter, “Ade,” naa ti o ní gbogbo Iwe Mimọ Lede Heberu, tabi “Majẹmu Laelae” ninu ni ipilẹ. A pa á mọ́ sinu sinagogu atijọ kan ti o jẹ ti awujọ kekere awọn Ju igbaani, ti wọn ń gbé ni Aleppo, Syria, ilu kan ti o kún fun awọn Musulumi. Ni iṣaaju, iwe-afọwọkọ yii ni a ti fisilẹ si ikawọ awọn Ju Karaite ni Jerusalemu, ṣugbọn awọn Ajagun-isin fipá gbà á ni 1099. Lẹhin naa, wọn rí iwe-afọwọkọ naa gbà pada ti wọn sì mú un lọ si Cairo Atijọ, Egipti. Ó dé Aleppo ni ọrundun kẹẹdogun ó keretan ti a sì wá mọ̀ ọ́n ni kẹrẹkẹrẹ sí Aleppo Codex. Iwe-afọwọkọ yii, ti ọjọ-ori rẹ̀ lọ pada sẹhin si 930 C.E., ni a kà si ade awọn ọmọwe akẹkọọ Masoret, gẹgẹ bi orukọ rẹ̀ ti fihàn. Ó jẹ́ apẹẹrẹ didara lati ṣakawe iṣọra ti a lo ninu títa àtaré ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ iwe Bibeli ti ó sì ti jẹ́, niti gidi, iwe-afọwọkọ Lede Heberu ti o jẹ́ awokọṣe.
Ni akoko ode-oni, bi awọn olutọju iwe-afọwọkọ alailẹgbẹ yii, ti ń fi igbagbọ ninu ohun asán bẹru sisọ ohun mímọ́ wọn di aláìmọ́, wọn kì yoo yọnda lati jẹ ki awọn ọmọwe akẹkọọ dé ibẹ. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, niwọn bi o ti jẹ́ pe kìkì oju-iwe kanṣoṣo ni a yà ni fọto ri, ẹ̀dà iru rẹ̀ gẹlẹ ni a kò lè tẹjade fun iwadii àyẹ̀wò.
Nigba ti awọn ará Britain kuro ni Palestine ni 1948, rogbodiyan bẹ́ silẹ ni Aleppo lodisi awọn Ju. Sinagogu wọn ni a jó; iwe afọwọkọ alabala ṣiṣeyebiye naa pòórá ti wọn sì gbà pe ó ti parun. Bawo ni ó ti yanilẹnu tó, nigba naa, ní nǹkan bii ọdun mẹwaa lẹhin naa, lati gbọ́ pe nǹkan bii idamẹta rẹ̀ ti laaja ti a sì ti ṣe fàyàwọ́ rẹ̀ kuro ni Syria lọ si Jerusalemu! Ni 1976 ẹ̀dà itẹjade iru rẹ̀ ti ó jẹ 500 ni irisi mèremère ni a ṣe jade.
Iṣẹ Ọ̀gá Kan
Eeṣe ti iwe-afọwọkọ yii fi ṣe pataki tobẹẹ? Nitori pe awọn ọ̀rọ̀ konsonanti ipilẹṣẹ rẹ̀ ni a tunṣe ti a sì fi àmì si ní nǹkan bii 930 C.E. lati ọwọ́ Aaron ben Asher, ọ̀kan lara awọn ọmọwe akẹkọọ ti o lokiki julọ ti a kọ́ lẹkọọ ṣiṣe àdàkọ ati títa Bibeli Lede Heberu látaré. Nitori naa ó jẹ́ awokọṣe iwe-afọwọkọ alábala, ti ó fi ọ̀pá idiwọn lélẹ̀ fun awọn ẹ̀dà ọjọ-iwaju tí awọn akọwe ti wọn kò loye tó o ṣe.
Ni ipilẹṣẹ ó ní 380 awẹ́ (760 oju-iwe) a sì kọ ọ ni gbogbogboo ni òpó ìlà mẹta lori abala ìwé-awọ. Ni bayii ó ni 294 awẹ́ kò sì ní Iwe-marun-un Akọkọ Bibeli ati apá ipin ti ó gbẹhin, eyi ti o ni ninu Ẹkun Jeremiah, Orin Solomoni, Danieli, Esteri, Esra, ati Nehemiah. A tọka si i gẹgẹ bii “Al” ninu New World Translation of the Holy Scriptures—Reference Bible (Joṣua 21:37, akiyesi ẹsẹ-iwe). Moses Maimonides (ti a yaworan rẹ̀ sihin-in), ọmọwe akẹkọọ Ju ti a mọ̀ bi ẹni mowó ni sanmani agbedemeji ti ọrundun 12 C.E., pe Aleppo Codex ni eyi ti o dara julọ ti oun tíì rí rí.a
Awọn ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ iwe Heberu ti a fi ọwọ ṣe àdàkọ wọn lati ọrundun ikẹtala si ikẹẹdogun jẹ́ àdàpọ̀ ti a fayọ lati inu ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ iwe ti Masoret meji pataki, ti Ben Asher ati ti Ben Naphtali. Ni ọrundun kẹrindinlogun, Jacob ben Hayyim mú ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ iwe jade fun Bibeli ti a tẹ̀ Lede Heberu lati inu aṣa ìlúpọ̀mọ́ra yii, eyi sì di ipilẹ fun ohun ti o fẹrẹẹ jẹ gbogbo Bibeli Lede Heberu ti a tẹjade fun 400 ọdun ti o tẹle e.
Pẹlu ẹ̀dà itẹjade kẹta ti Biblia Hebraica ni 1937 (ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ iwe Heberu ti a tẹ̀), aṣa-atọwọdọwọ Ben Asher ni a kàn sí niwọn bi a ti pa a mọ sinu iwe-afọwọkọ kan ti a tọju si Russia, ti a mọ̀ si Leningrad B 19A. Leningrad B 19A ti wà sẹhin lati 1008 C.E. Hebrew University ti o wà ni Jerusalemu ń wéwèé lati tẹ ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ iwe Heberu Aleppo jade ni kikun fun ọpọ akoko kan, papọ pẹlu awọn iwe kíkà lati inu awọn iwe-afọwọkọ pataki miiran ati awọn ẹ̀dà itumọ, ti ó ni Ìwé-kíká Òkun Òkú ninu.
Ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ iwe Bibeli ti a ń lò lonii ṣeé gbarale. A mí sí i lati ọrun wá a sì ta àtaré rẹ̀ nipasẹ awọn akọwe aṣàdàkọ awọn ẹni ti wọn ṣiṣẹ pẹlu òye iṣẹ àfìṣọ́raṣe jalẹ awọn ọrundun. Iṣọra dé gongo awọn adàwékọ wọnyi ni a rí niti pe ifiwera ìwé-kíká Isaiah ti a rí nitosi Òkun Òkú ni 1947 ati ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ iwe Masoret lọna ti o jọniloju fi iyatọ diẹ hàn, àní bi o tilẹ jẹ pe Ìwé-kíká Òkun Òkú naa fi ẹgbẹrun ọdun ju Bibeli Masoret ti ó wà lọ. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, nisinsinyi ti Aleppo Codex ti wà larọọwọto fun awọn ọmọwe akẹkọọjinlẹ, yoo tun pese idi siwaju sii fun níní igbẹkẹle ninu ijojulowo awọn ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ Iwe Mimọ Lede Heberu. Nitootọ, “ọ̀rọ̀ Ọlọrun wa yoo duro laelae.”—Isaiah 40:8.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun awọn ọdun diẹ awọn ọmọwe kan ṣiyemeji pe Aleppo Codex jẹ iwe-afọwọkọ tí Ben Asher fami si. Bi o ti wu ki o ri, niwọn bi iwe-afọwọkọ alábala naa ti wà larọọwọto fun kíkà, ẹ̀rí ti wà pe iwe-afọwọkọ Ben Asher ti Maimonides mẹnuba gan-an ni.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]
Bibelmuseum, Münster
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 29]
Jewish Division / The New York Public Library / Astor, Lenox, and Tilden Foundations