ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 9/15 ojú ìwé 26-29
  • Àwọn Wo Ni Àwọn Masorete?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Wo Ni Àwọn Masorete?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdílé Ben Asher
  • Ó Béèrè Iyè Ìrántí Pípẹtẹrí
  • Kí Ni Wọ́n Gbàgbọ́?
  • Jíjàǹfààní Láti Inú Iṣẹ́ Wọn
  • Kí Ni Ìwé Àwọn Masorete?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Iwe-afọwọkọ Bibeli kan Lede Heberu Ti Ó Jẹ́ Awokọṣe
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Bíbélì Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Tó Fẹ́ Yí Ọ̀rọ̀ Inú Rẹ̀ Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Ìfẹ́ Mi fún Ilẹ̀ Ayé Yóò Ṣẹ Títí Láé
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 9/15 ojú ìwé 26-29

Àwọn Wo Ni Àwọn Masorete?

JEHOFA, “Ọlọrun òtítọ́,” ti pa Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli mọ́. (Orin Dafidi 31:5) Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí Satani, ọ̀tá òtítọ́, ti gbìyànjú láti sọ ọ́ dìbàjẹ́, kí ó sì pa á run, báwo ni Bibeli ṣe dé ọ̀dọ̀ wa, ní pàtàkì jù lọ, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́?—Wo Matteu 13:39.

Apá kan ìdáhùn náà ni a lè rí nínú ọ̀rọ̀ àkíyèsí láti ọwọ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n Robert Gordis pé: “Àṣeyọrí àwọn akọ̀wé Heberu, tí a ń pè ní àwọn masorete tàbí ‘àwọn olùpa àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ mọ́,’ ni a kò mọrírì tó. Àwọn akọ̀wé tí a kò mọ orúkọ wọn wọ̀nyí da Ìwé Mímọ́ Ọlọ́wọ̀ náà kọ pẹ̀lú ìṣọ́ra àti àníyàn onífẹ̀ẹ́.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn adàwékọ wọ̀nyí ni a kò mọ orúkọ wọn títí di òní, orúkọ ìdílé kan lára àwọn Masorete ni a ti kọ sílẹ̀ kedere—Ben Asher. Kí ni a mọ̀ nípa wọn àti àwọn Masorete ẹlẹgbẹ́ wọn?

Ìdílé Ben Asher

Apá Bibeli tí a kọ ní èdè Heberu ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, tí a sábà máa ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé, ni àwọn akọ̀wé Júù ṣe àdàkọ rẹ̀ pẹ̀lú ìṣòtítọ́. Láti ọ̀rúndún kẹfà sí ìkẹwàá C.E., àwọn adàwékọ wọ̀nyí ni a ń pè ní àwọn Masorete. Kí ni iṣẹ́ wọn ní nínú?

Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, èdè Heberu ni a ń kọ pẹ̀lú kọ́ńsónáǹtì nìkan, tí òǹkàwé náà yóò sì máa fi àwọn fáwẹ́ẹ̀lì kún un. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí yóò fi di àkókò àwọn Masorete, pípe ọ̀rọ̀ bí ó ti tọ́ ní èdè Heberu ti ń sọnù, nítorí pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù kò lè sọ èdè náà dáradára mọ́. Ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn Masorete ní Babiloni àti Israeli hùmọ̀ àwọn àmì ti a óò fi sáàárín àwọn kọ́ńsónáǹtì náà láti fi àmì ìpe ọ̀rọ̀ àti pípè tí ó tọ́ fún àwọn fáwẹ́ẹ̀lì hàn. Ó kéré pin ètò-ìgbékalẹ̀ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni a gbé dìde, ṣùgbọ́n èyí tí ó fi ẹ̀rí agbára ìdarí tí ó pọ̀ jù lọ hàn ni ti àwọn Masorete ní Tiberia, lẹ́bàá Òkun Galili, ilé ìdílé Ben Asher.

Ìtàn to ìran àwọn Masorete márùn-ún láti ìdílé aláìlẹ́gbẹ́ yìí, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Asher Alàgbà ti ọ̀rúndún kẹjọ C.E. Àwọn yòókù ni Nehemiah Ben Asher, Asher Ben Nehemiah, Moses Ben Asher, àti, níkẹyìn, Aaron Ben Moses Ben Asher ti ọ̀rúndún kẹwàá C.E.a Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ni aṣáájú nínú àwọn wọnnì tí ń ṣe ìsọdipípé àwọn àmì ìṣàpẹẹrẹ ìkọ̀wé tí ó lè ṣàlàyé lọ́nà tí ó dára jù lọ ohun tí wọ́n lóye pé ó jẹ́ pípè tí ó tọ́ fún àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ Bibeli Lédè Heberu. Láti mú àwọn àmì ìṣàpẹẹrẹ wọ̀nyí dàgbà, wọ́n ní láti pinnu ìpìlẹ̀ ètò ìgbékalẹ̀ gírámà Heberu. Kò tí ì sí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn òfin pàtó fún gírámà Heberu tí a tí ì kọ sílẹ̀ rí. Nítorí náà, ẹnì kan lè sọ pé àwọn Masorete wọ̀nyí wà lára àwọn onímọ̀ gírámà àkọ́kọ́ fún èdè Heberu.

Aaron, Masorete tí ó kẹ́yìn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ìdílé Ben Asher, ni àkọ́kọ́ láti ṣàkọsílẹ̀ àti láti ṣàtúnṣe ìsọfúnni yìí. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ nínú iṣẹ́ kan tí ó pe àkọlé rẹ̀ ní “Sefer Dikdukei ha-Te‘amim,” ìwé àkọ́kọ́ lórí àwọn òfin gírámà Heberu. Ìwé yìí di ìpìlẹ̀ fún iṣẹ́ àwọn onímọ̀ gírámà Heberu yòókù fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tí ń bọ̀. Ṣùgbọ́n èyí wulẹ̀ jẹ́ àfikún sí iṣẹ́ àwọn Masorete tí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì. Kí ni ìyẹn?

Ó Béèrè Iyè Ìrántí Pípẹtẹrí

Ohun tí ó jẹ àwọn Masorete lógún jù lọ ni títàtaré ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan lọ́nà tí ó péye, àní lẹ́tà kọ̀ọ̀kan tí ó wà nínú ẹsẹ ìwé Bibeli pàápàá. Láti rí i dájú pé ó péye, àwọn Masorete ṣàmúlò àwọn àlàfo ẹ̀gbẹ́ ìwé ní ojú ìwé kọ̀ọ̀kan, láti kọ ìsọfúnni tí yóò tọ́ka sí ìyípadà ẹsẹ ìwé èyíkéyìí tí ó ṣeé ṣe kí àwọn adàwékọ tí ó ti kọjá ti ṣèèṣì ṣe tàbí mọ̀ọ́mọ̀ ṣe. Nínú àwọn àkíyèsí àlàfo ìwé wọ̀nyí, àwọn Masorete tún ṣàkíyèsí àwọn ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ àti ìsopọ̀ ọ̀rọ̀ lọ́nà tí kò wọ́pọ̀, ní sísààmì sí bí àwọn wọ̀nyí ti hàn léraléra tó nínú ìwé kan tàbí nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu lápapọ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ àkíyèsí wọ̀nyí ni a kọ pẹ̀lú àmì tí ó kúrú gan-an, níwọ̀n bí àyè kò ti tó nǹkan. Gẹ́gẹ́ bí ohun èlò láti tún àyẹ̀wò ṣe síwájú sí i, wọ́n sàmì sí ọ̀rọ̀ tí ó wà láàárín àti lẹ́tà àwọn ìwé kan. Wọ́n lọ jìnnà débi pé wọ́n ka gbogbo lẹ́tà tí ó wà nínú Bibeli, kí wọ́n baà lè rí i dájú pé àdàkọ náà péye.

Nínú àwọn àlàfo ìwé tí ó wà ní òkè àti ìsàlẹ̀ ojú ìwé, àwọn Masorete ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ àkíyèsí tí ó túbọ̀ kún rẹ́rẹ́ sí i nípa àwọn àkíyèsí tí a gé kúrú ní àwọn àlàfo ẹ̀gbẹ́ ìwé.b Àwọn wọ̀nyí ṣèrànlọ́wọ́ ní ṣíṣe àtúnṣe àyẹ̀wò iṣẹ́ wọn. Níwọ̀n bí a kò ti fi nọ́ḿbà sí àwọn ẹsẹ nígbà yẹn, tí kò sì sí àwọn Bibeli atọ́ka, báwo ni àwọn Masorete ṣe ń tọ́ka sí àwọn apá tí ó ṣẹ́ kù nínú Bibeli, kí wọ́n ba lè ṣe àtúnṣe àyẹ̀wò yìí? Nínú àwọn àlàfo ìwé tí ó wà ní òkè àti ìsàlẹ̀, wọ́n to apá kan ẹsẹ tí ó jọra láti lè rán wọn létí ibi tí ọ̀rọ̀ tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tí a tọ́ka sí wà níbòmíràn nínú Bibeli. Ṣùgbọ́n nítorí àyè tí kò tó nǹkan, ní ọ̀pọ̀ ìgbà, wọn yóò wulẹ̀ kọ ọ̀rọ̀ kan tí ó ṣe kókó láti rán wọn létí ẹsẹ kọ̀ọ̀kan tí ó jọra. Kí àwọn àkíyèsí àlàfo ìwé wọ̀nyí ba lè wúlò, àwọn adàwékọ wọ̀nyí yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ ní láti mọ gbogbo Bibeli Lédè Heberu sórí.

Àwọn àkọsílẹ̀ tí ó bá ti gùn jù fún àlàfo ìwé ni a máa ń gbé lọ sí apá mìírán nínú ìwé àfọwọ́kọ náà. Fún àpẹẹrẹ, àkíyèsí àwọn Masorete tí ó wà ní àlàfo ẹ̀gbẹ́ ìwé ní Genesisi 18:3 fi lẹ́tà Heberu mẹ́ta hàn, קלד. Èyí ni ó dọ́gba ní èdè Heberu pẹ̀lú nọ́ḿbà náà 134. Ní apá mìíràn nínú ìwé àfọwọ́kọ náà, àkọsílẹ̀ kan wà níbẹ̀ tí ó tọ́ka sí àwọn ibi 134 tí àwọn adàwékọ tí ó ṣáájú àwọn Masorete ti mọ̀ọ́mọ̀ yọ orúkọ Jehofa kúrò nínú ẹsẹ ìwé Heberu, ní fífi ọ̀rọ̀ náà “Oluwa” rọ́pò rẹ̀.c Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ̀ nípa àwọn ìyípadà wọ̀nyí, àwọn Masorete kò lo agbára yíyàn tí wọ́n ní láti yí àwọn ẹsẹ ìwé tí a gbé lé wọn lọ́wọ́ padà. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n tọ́ka sí àwọn ìyípadà wọ̀nyí nínú àwọn àkíyèsí àlàfo ìwé wọn. Ṣùgbọ́n èé ṣe tí àwọn Masorete fi lo ìṣọ́ra tí ó lé kenkà bẹ́ẹ̀ láti má ṣe yí ẹsẹ ìwé náà nígbà tí àwọn adàwékọ tí ó ṣáájú yí i? Ọ̀nà ìgbàgbọ́ Júù tiwọn ha yàtọ̀ sí ti àwọn tí ó ṣáájú wọn bí?

Kí Ni Wọ́n Gbàgbọ́?

Ní àkókò tí àwọn Masorete ń tẹ̀ síwájú yìí, ìsìn àwọn Júù ti ń lọ́wọ́ nínú ogun ìdábàá èrò orí lọ́nà jíjinlẹ̀. Láti ọ̀rúndún kìíní C.E., ìsìn àwọn Júù ti rabi ti ń mú agbára ìdarí rẹ̀ pọ̀ sí i. Pẹ̀lú kíkọ Talmud àti ìtumọ̀ láti ọwọ́ àwọn rabi, ẹsẹ ìwé Bibeli ń bọ́ sí ipò kejì sí ìtumọ̀ tí àwọn rabi fún òfin àtẹnudẹ́nu.d Nítorí náà, ìfìṣọ́ra tọ́jú àwọn ẹsẹ ìwé Bibeli pamọ́ lè ti sọ ìjẹ́pàtàkì rẹ̀ nù.

Ní ọ̀rúndún kẹjọ, ẹgbẹ́ àwùjọ kan tí a mọ̀ sí àwọn Karaite ṣọ̀tẹ̀ lòdì sí ọ̀nà ìdarísí yìí. Ní títẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, wọ́n kọ ọlá àṣẹ àti ìtumọ̀ àwọn rabi àti ti Talmud. Wọ́n tẹ́wọ́ gba ẹsẹ ìwé Bibeli nìkan gẹ́gẹ́ bí ọlá àṣẹ wọn. Èyí dákún àìní náà fún títàtaré ẹsẹ ìwé náà lọ́nà tí ó péye, ìfisílò àwọn Masorete sì jèrè ìsúnṣe tí a sọ dọ̀tun.

Dé àyè wo ni ìgbàgbọ́ àwọn rabi tàbí ti àwọn Karaite ní agbára ìdarí lórí iṣẹ́ àwọn Masorete? M. H. Goshen-Gottstein, tí ó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nínú ìwé àfọwọ́kọ ti Bibeli Lédè Heberu, sọ pé: “Ó dá àwọn Masorete lójú gbangba . . . pé wọ́n ń pa àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ìgbàanì mọ́, àti pé lọ́dọ̀ wọn mímọ̀ọ́mọ̀ ta félefèle pẹ̀lú rẹ̀ yóò jẹ́ ìwà ọ̀daràn tí ó burú jùlọ tí ó ṣeé ṣe.”

Àwọn Masorete fojú wo ṣíṣe àdàkọ ẹsẹ Bibeli gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ mímọ́ kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ohun tí àwọn ìsìn mìíràn dàrò ti ní láti sún àwọn fúnra wọn gan-an, ó dà bí pé iṣẹ́ àwọn Masorete fúnra rẹ̀ ju ti àwọn ọ̀ràn ìdábàá èrò orí lọ. Àkọsílẹ̀ àlàfo ìwé tí ó ṣe pàtó fi àyè díẹ̀ sílẹ̀ fún àríyànjiyàn ẹ̀kọ́ ìsìn. Ẹsẹ ìwé Bibeli fúnra rẹ̀ jẹ́ àníyàn ìgbésí ayé wọn; wọn kì yóò dabarú rẹ̀.

Jíjàǹfààní Láti Inú Iṣẹ́ Wọn

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Israeli àbínibí kì í ṣe àwọn ènìyàn àyànfẹ́ Ọlọrun mọ́, àwọn Júù adàwékọ wọ̀nyí ti ya ara wọn sí mímọ́ fún títọ́jú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun pa mọ́ lọ́nà tí ó péye. (Matteu 21:42-44; 23:37, 38) Àṣeyọrí ìdílé Ben Asher àti àwọn Masorete yòókù ni Robert Gordis sọ̀ ní ṣókí, nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Àwọn òṣìṣẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ṣe é jẹ gàba lé lórí wọ̀nyẹn . . . ṣe iṣẹ́ wọn tí ó ṣòro gan-an ti pípa Ẹsẹ Bibeli mọ́ kí ó má ṣe sọnù tàbí yàtọ̀ lọ́nà tí kò lókìkí.” (The Biblical Text in the Making) Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, nígbà tí àwọn Aṣàtúnṣe ti ọ̀rúndún 16 bíi Luther àti Tyndale ṣàìka ọlá àṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì sí, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ Bibeli sí àwọn èdè tí ó wọ́ pọ̀ fún gbogbo ènìyàn láti kà, wọ́n ní ẹsẹ ìwé Heberu tí a pa mọ́ dáradára láti lò gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún iṣẹ́ wọn.

Iṣẹ́ àwọn Masorete ṣì ń bá a lọ láti máa wúlò fún wa lónìí. Ẹsẹ ìwé Heberu wọn ni ó jẹ́ ìpìlẹ̀ fún Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu ti New World Translation of the Holy Scriptures. Ìtumọ̀ yìí ni a ń bá a lọ láti máa túmọ̀ sí èdè púpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí kan náà ti ìfarajìn àti àníyàn fún pípéye tí àwọn Masorete ìgbàanì fi hàn. Yóò dára láti fi irú ẹ̀mí kan náà hàn nínú fífi àfiyèsí sí Ọ̀rọ̀ Jehofa Ọlọrun.—2 Peteru 1:19.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní èdè Heberu “ben” túmọ̀ sí “ọmọkùnrin.” Nítorí náà Ben Asher túmọ̀ sí “ọmọkùnrin Asher.”

b Àwọn àkíyèsí àwọn Masorete tí ó wà ní àlàfo ẹ̀gbẹ́ ìwé ni a ń pè ní Masora Kékeré. Àwọn àkíyèsí tí ó wà ní àlàfo ìwé ní òkè àti ìsàlẹ̀ ni a ń pè ní Masora Ńlá. Àwọn àkọsílẹ̀ tí a kọ sí apá mìíràn nínú ìwé àfọwọ́kọ náà ni a ń pè ní Masora Ìkẹyìn.

c Wo Àsomọ́ 1B nínú New World Translation of the Holy Scriptures—With References.

d Fún ìsọfúnni síwájú sí i lórí òfin àtẹnudẹ́nu àti ìsìn àwọn Júù ti rabi, wo ojú ìwé 8 sí 11 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà Will There Ever Be a World Without War?, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Ọ̀nà Ìgbà Pe Ọ̀rọ̀ ní Èdè Heberu

ÌWÁKIRI fún ọ̀nà dídára jù lọ fún ṣíṣe àkọsílẹ̀ àwọn àmì fáwẹ́ẹ̀lì àti àwọn àmì ìpe ọ̀rọ̀ gba ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún láàárín àwọn Masorete. Nítorí náà, kò yani lẹ́nu láti rí ìdàgbàsókè tí ń bá a lọ pẹ̀lú ìran kọ̀ọ̀kan ti ìdílé Ben Asher. Àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí ó wà báyìí ṣojú fún àwọn àrà àti ọ̀nà ti kìkì àwọn Masorete méjì tí ó kẹ́yìn ní ìdílé Ben Asher, Moses àti Aaron.e Ìkẹ́kọ̀ọ́ ìfiwéra àwọn ìwé àfọwọ́kọ wọ̀nyí fi hàn pé Aaron ṣàgbéjáde àwọn òfin lórí àwọn kókó kéékèèké kan ti pípe ọ̀rọ̀ àti àfiyèsí tí ó yàtọ̀ sí ti bàbá rẹ̀, Moses.

Ben Naphtali jẹ́ alájọgbáyé Aaron Ben Asher. Ìwé Àfọwọ́kọ Alábala Cairo ti Moses Ben Asher ní ọ̀pọ̀ àwọn ìtumọ̀ pàtó kan tí a kà sí ti Ben Naphtali nínú. Nítorí náà, yálà kí ó jẹ́ pé Ben Naphtali fúnra rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Moses Ben Asher tàbí kí ó jẹ́ pé àwọn méjèèjì tọ́jú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí ó túbọ̀ jẹ́ ti ìgbàanì tí ó wọ́ pọ̀ pa mọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín ètò ìgbékalẹ̀ ti Ben Asher àti ti Ben Naphtali, ṣùgbọ́n M. H. Goshen-Gottstein kọ̀wé pé: “Yóò dà bí ohun tí ó péye láti sọ̀rọ̀ nípa ètò ìgbékalẹ̀ kéékèèké méjì nínú ìdílé Ben Asher àti láti pé ìyàtọ̀ kíkà náà ní: Ben Asher ní ìlòdìsí Ben Asher.” Nítorí náà, kì yóò péye láti sọ̀rọ̀ ọ̀nà ti Ben Asher nìkan. Kì í ṣe ìyọrísí ìlọ́lájù àjogúnbá pé ọ̀nà ti Aaron Ben Asher di èyí tí a tẹ́wọ́ gbà nígbẹ̀yìn. Kìkì nítorí pé ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Talmud ní ọ̀rúndún 12, Moses Maimonides, gbóríyìn fún ẹsẹ ìwé Aaron Ben Asher ni a ṣe yàn án láàyò.

[Artwork—Hebrew characters]

Apá kan Eksodu 6:2 pẹ̀lú àwọn kókó fáwẹ́ẹ̀lì àti àmi ìpè ọ̀rọ̀ tí ó yàtọ̀ kedere àti láìsí wọn

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

e Ìwé Àfọwọ́kọ Alábala Cairo (895 C.E.), tí ó ní kìkì àwọn wòlíì ti ìṣáájú àti ti ìgbẹ̀yìn nínú, fúnni ní àpẹẹrẹ ọ̀nà ti Moses. Àwọn ìwé àfọwọ́kọ alábala ti Aleppo (c.930 C.E.) àti Leningrad (1008 C.E.) ni a mọ̀ sí àpẹẹrẹ àwọn ọ̀nà ti Aaron Ben Asher.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Tiberia, àárín gbùngbùn ìgbòkègbodò àwọn Masorete láti ọ̀rúndún kẹjọ sí ìkẹwàá

[Credit Line]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́