Kí Ni Ìwé Àwọn Masorete?
ÈDÈ yòówù tí o ti ń ka Bibeli, ó ṣeé ṣe kí a ti túmọ̀ apákan ìwé náà láti inú ìwé àwọn Masorete ní tààràtà tàbí láìṣe tààràtà, èyí tí ó parapọ̀ di Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu, tàbí “Májẹ̀mú Láéláé.” Dájúdájú, ìwé àwọn Masorete tí ó wà ju ẹyọkan lọ. Nítorí náà èwo ni a yàn, èésìtiṣe? Níti tòótọ́, kí ni ìwé àwọn Masorete, báwo sì ni a ṣe mọ̀ pé ó ṣeé gbáralé?
Ọ̀rọ̀ Jehofa
Kíkọ Bibeli bẹ̀rẹ̀ ní Òkè Sinai ní 1513 B.C.E. Eksodu 24:3, 4 sọ fún wa pé: “Mose . . . wá ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ OLUWA, àti gbogbo ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn: gbogbo ènìyàn sì fi ohun kan dáhùn wí pé, Gbogbo ọ̀rọ̀ ti OLUWA wí ni àwa óò ṣe, Mose sì kọ̀wé gbogbo ọ̀rọ̀ OLUWA.”
Wọ́n ń bá ṣíṣe àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu nìṣó fún ohun tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún, láti 1513 B.C.E. títí di nǹkan bí 443 B.C.E. Níwọ̀n bí Ọlọrun ti mí sí àwọn alákọsílẹ̀ náà, ó lọ́gbọ́n nínú pé òun yóò darí àwọn ọ̀ràn kí a baà lè pa ìhìn-iṣẹ́ rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú ìṣòtítọ́. (2 Samueli 23:2; Isaiah 40:8) Bí ó ti wù kí ó rí, èyí ha túmọ̀ sí pé Jehofa yóò dènà gbogbo àṣìṣe ẹ̀dá ènìyàn kí ó má baà jẹ́ pé a óò yí ẹyọ ọ̀rọ̀ kan padà nígbà tí a bá ń ṣe àdàkọ bí?
Ọ̀nà Àbáwọlé Sí Àìpéye Ṣí Sílẹ̀ Díẹ̀
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣe àdàkọ rẹ̀ láti ìrandíran, síbẹ̀síbẹ̀ àwọn àṣìṣe ẹ̀dá ènìyàn díẹ̀ yọ́ wọ inú àwọn ìwé àfọwọ́kọ. A mí sí àwọn tí ó kọ Bibeli, ṣùgbọ́n àwọn adàwékọ kò ṣe iṣẹ́ wọn lábẹ́ ìmísí àtọ̀runwá.
Lẹ́yìn pípadà dé láti ìgbèkùn Babiloni ní 537 B.C.E., àwọn Júù ṣàmúlò ọ̀nà ìkọ̀wé titun tí ń lo ọ̀rọ̀ onígun mẹ́rin tí wọ́n kọ́ ní Babiloni. Ìyípadà pàtàkì yìí mú ìṣòro àjogúnbá náà wá pé wọ́n lè ṣi àwọn ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n rí bákan náà gbé fún ara wọn. Níwọ̀n bí Heberu ti jẹ́ èdè kan tí a gbékarí kọ́ńsónáǹtì, tí òǹkàwé náà yóò sì máa fi àwọn ohùn fáwẹ̀lì tí ó bá yẹ kún un ní ìbámu pẹ̀lú bí òye rẹ̀ nípa àyíká ọ̀rọ̀ náà bá ti rí, ó rọrùn kí ìyípadà kọ́ńsónáǹtì kan yí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ kan padà. Bí ó ti wù kí ó rí, nínú àwọn ọ̀ràn tí ó pọ̀ jùlọ, irú àwọn àṣìṣe bẹ́ẹ̀ ni a óò ti rí tí a óò sì ti túnṣe.
Ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn Júù kò padà sí Israeli lẹ́yìn ìṣubú Babiloni. Nípa bẹ́ẹ̀, sinagogu di ojúkò tẹ̀mí fún ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn Júù jákèjádò Middle East àti Europe.a Sinagogu kọ̀ọ̀kan nílò àwọn ẹ̀dà àkájọ Ìwé Mímọ́. Bí àwọn ẹ̀dà ti ń pọ̀ síi, bẹ́ẹ̀ náà ni ṣíṣeéṣe náà pé kí àwọn adàwékọ ṣe àṣìṣe ń pọ̀ síi.
Ìgbìdánwò Láti Ti Ọ̀nà Àbáwọlé Náà
Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀rúndún kìn-ínní C.E., àwọn akọ̀wé ní Jerusalemu gbìdánwò láti gbé ojúlówó ẹsẹ̀-ìwé kalẹ̀ èyí tí a lè fi máa tún àwọn àkájọ Iwé Mímọ́ Lédè Heberu mìíràn ṣe. Síbẹ̀, kò sí ètò kan pàtó fún dídá ojúlówó ẹsẹ̀-ìwé mọ̀ yàtọ̀ sí àwọn ìwé-àfọwọ́kọ tí ó ní àṣìṣe àwọn adàwékọ nínú. Láti ọ̀rúndún kejì C.E. síwájú, ó dàbí ẹni pé a ti mú àwọn ọ̀rọ̀ kọ́ńsónáǹtì ti Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu bá ọ̀pá-ìdiwọ̀n mu dé àyè kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò tí ì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú ọlá-àṣẹ. Àwọn ẹsẹ̀ tí a fàyọ láti inú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu tí ó fara hàn nínú Talmud (tí a kójọ ní ọ̀rúndún kejì àti ìkẹfà C.E.) sábà máa ń fi orísun mìíràn hàn tí ó yàtọ̀ sí ohun tí a wá mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwé àwọn Masorete.
Ọ̀rọ̀ náà “àṣà àtọwọ́dọ́wọ́” ní èdè Heberu ni ma·soh·rahʹ tàbí ma·soʹreth. Nígbà tí yóò fi di ọ̀rúndún kẹfà C.E., àwọn wọnnì tí ń dáàbòbo àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ti dída Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu kọ lọ́nà tí ó péye ni a wá mọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn Masorete. Àwọn ẹ̀dà tí wọ́n ṣe ni a ń tọ́ka sì gẹ́gẹ́ bí ìwé àwọn Masorete. Kí ni ó jẹ́ ohun bàbàrà nípa iṣẹ́ wọn àti àwọn ìwé tí wọ́n ṣètò?
Heberu ti parẹ́, gẹ́gẹ́ bí èdè orílẹ̀-èdè kan, ọ̀pọ̀ àwọn Júù kò sì lóye rẹ̀ mọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, òye náà gan-an nípa àwọn kọ́ńsónáǹtì inú Bibeli ni a ti jìn lẹ́sẹ̀. Láti dáàbò bò ó, àwọn Masorete ṣe ìgbékalẹ̀ ètò fífi àwọn àmì tóó-tòò-tó àti dáàṣì tàbí àmì ìdánudúrópẹ́ ṣojú fún àwọn fáwẹ̀lì. Àwọn wọ̀nyí ni a ń fi sókè tàbí sísàlẹ̀ àwọn kọ́ńsónáǹtì. Àwọn Masorete tún ṣe ìgbékalẹ̀ ètò dídíjú tí ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìfàmìsọ̀rọ̀ àti gẹ́gẹ́ bí atọ́nà fún pípe àwọn ọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó péye síi.
Níbi tí àwọn Masorete bá ti rò pé a ti yí ẹsẹ̀ ìwé náà padà tàbí tí ìran àwọn akọ̀wé tí ó ti wà ṣáájú dà á kọ lọ́nà tí kò tọ̀nà, dípò yíyí ẹsẹ̀ ìwé náà padà, wọn yóò kọ ọ̀rọ̀ sí àlàfo tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ìwé. Wọ́n ṣàkọsílẹ̀ ṣíṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ àti jíjó ọ̀rọ̀ pọ̀ lọ́nà tí ó ṣàjèjì àti bí àwọn wọ̀nyí ṣe fara hàn léraléra tó nínú ìwé kọ̀ọ̀kan tàbí nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu lódiidi. Wọ́n tún ṣàkọsílẹ̀ àwọn àfikún àlàyé láti ran àwọn adàwékọ lọ́wọ́ ní yíyẹ ìwé wò síra wọn. Wọ́n ṣe ìgbékalẹ̀ ètò “ọ̀rọ̀-aṣojú-ọ̀rọ̀” tí a gé kúrú láti ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìsọfúnni yìí bí ó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó kúrú tó. Ní àlàfo tí ó wà lókè àti nísàlẹ̀, atọ́ka kékeré kan wà tí ó tó apákan nínú àwọn ẹsẹ̀ tí ó jọra tí a ti sọ̀rọ̀ lé lórí nínú àwọn àkọsílẹ̀ ní àwọn àlàfo ẹ̀gbẹ́ ìwé.
Ètò tí ó gbajúmọ̀ jùlọ ni àwọn Masorete mú dára ní Tiberia, ní Òkun Galili. Àwọn ìdílé Ben Asher àti Ben Naphtali ti ọ̀rúndún kẹsàn-án àti ìkẹwàá C.E., tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ àwọn Karaite, di olókìkí lọ́nà títayọ.b Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìyàtọ̀ wà nínú àwọn ọ̀nà pípe ọ̀rọ̀ àti àkọsílẹ̀ láàárín àwọn méjèèjì tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn olójú-ìwòye kan náà wọ̀nyí, àwọn kọ́ńsónáǹtì inú ìwé wọn yàtọ̀ síra ní ibi tí kò tó mẹ́wàá nínú gbogbo odiidi Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu.
Àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ olójú-ìwòye kan náà ti Masorete méjèèjì, ti Ben Asher àti ti Ben Naphtali, ṣe gudugudu méje fún ìmọ̀ ìkọ̀wé nígbà ayé wọn. Lẹ́yìn tí Maimonides (ògúnná gbòǹgbò ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ní Talmud ti ọ̀rúndún kejìlá) ti gbóríyìn fún ẹsẹ̀-ìwé Ben Asher, àwọn mìíràn yàn án láàyò. Èyí rí bẹ́ẹ̀ débi pé kò sí èyíkéyìí nínú ìwé àfọwọ́kọ ti Ben Naphtali tí a lè rí mọ́ ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Kìkì ohun tí ó ṣẹ́kù ní àkójọ ìyàtọ̀ láàárín àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ olójú-ìwòye kan náà méjèèjì. Àbájáde òdì tí ó ní ni pé, àlàyé Maimonides níí ṣe pẹ̀lú ṣíṣàgbéyẹ̀wò ọ̀nà ìgbàkọ-ọ̀rọ̀, irú bí àlàfo ìpínrọ̀ sí ìpínrọ̀, kì í sìí ṣe sí apá tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ti títa àtagbà ọ̀rọ̀ lọ́nà pípéye.
A Ha Lè Rí “Ojúlówó” Ìwé Àwọn Masorete Bí?
Àríyànjiyàn púpọ̀ ń bẹ láàárín àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa pé èwo nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtayébáyé tí ó wà lónìí ni “ojúlówó” ẹsẹ̀-ìwé Ben Asher, bóyá èyí yóò lè fún wa ní ìwé àwọn Masorete “tòótọ́.” Dájúdájú, kò fìgbà kankan sí ìwé àwọn Masorete tí ó jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, “ojúlówó,” tí ó sì ní ọlà-àṣẹ. Dípò bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ìwé àwọn Masorete wà, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ síra. Gbogbo àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtayébáyé tí kò parun jẹ́ àdàlù ẹṣẹ-ìwé, pẹ̀lú àwọn ìwé Ben Asher àti Ben Naphtali.
Ẹrù-iṣẹ́ tí ó dojúkọ olùtúmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu èyíkéyìí jẹ́ èyí tí ń banilẹ́rù. Kì í ṣe ẹsẹ̀-ìwé Heberu nìkan ni òun yóò mọ̀ dunjú ṣùgbọ́n gbogbo yíyàn lílọ́gbọ́n nínú níbi tí àṣìṣe àwọn adàwékọ tàbí nǹkan mìíràn ti lè mú kí a yí ẹsẹ̀-ìwé náà padà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú ìwé àwọn Masorete ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀, ó níláti ṣàyẹ̀wò àwọn orísun mìíràn tí ó jẹ́ òtítọ́ tí ó lè ṣojú fún àwọn ìtumọ̀ tí ó ti pẹ́ àti bóyá àwọn ẹsẹ̀-ìwé oníkọ́ńsónáǹtì tí ó péye lọ́nà tí ó lọ́gbọ́n nínú.
Nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ìwé rẹ̀ The Text of the Old Testament, Ernst Würthwein ṣàlàyé pé: “Nígbà tí a bá dojúkọ ẹsẹ̀ kan tí ó ṣòro a kò lè wulẹ̀ kó onírúurú àwọn ìwé jọ kí a sì yan ọ̀kan tí ó dàbí ẹni pé ó pèsè ojútùú tí ó rọrùn jùlọ, nígbà mìíràn a lè nífẹ̀ẹ́ sí ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ lédè Heberu jùlọ, nígbà mìíràn ó lè jẹ́ Septuagint, nígbà mìíràn ó sì lè jẹ́ ìtumọ̀ apákan Májẹ̀mú Láéláé Lédè Aramaic. Kì í ṣe gbogbo àwọn ẹ̀rí inú ẹsẹ̀-ìwé ni kò ṣeé gbáralé. Ìkọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà ìkọ̀wé tirẹ̀ àti ìtàn tirẹ̀ tí ó yàtọ̀. A gbọ́dọ̀ mọ àwọn wọ̀nyí dunjú bí a bá retí láti yẹra fún àwọn ojútùú tí kò dára tó tàbí tí ó jẹ́ awúrúju.”
A ní ìdí tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún ìgbọ́kànlé kíkún pé Jehofa ti pa Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́. Nípasẹ̀ ìsapá tí àwọn ènìyàn olóòótọ́ ọkàn pawọ́pọ̀ ṣe ní àwọn ọ̀rúndún, àwọn ohun tí a fi ṣe é, ọ̀rọ̀ inú rẹ̀, àti kúlẹ̀kúlẹ̀ ìhìn-iṣẹ́ Bibeli pàápàá wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa. Ìyàtọ̀ kín-ún nínú ọ̀nà ìkọ̀wé tàbí ọ̀rọ̀ kò tí ì nípa lórí agbára wa láti lóye Ìwé Mímọ́. Wàyí o, ìbéèrè pàtàkì náà ni pé, Àwa yóò ha máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli bí?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Níwọ̀n bí púpọ̀ lára àwọn Júù tí ó wà lẹ́yìn òde Israeli kò ti lè ka èdè Heberu lọ́nà jíjágaara mọ́, irú ẹgbẹ́ àwùjọ Júù bẹ́ẹ̀ bí èyí tí ó wà ní Alexandria, Egipti, tètè rí àìní náà láti túmọ̀ Bibeli sí èdè ìbílẹ̀. Láti lè kájú àìní yìí, a ṣètò ẹ̀dà-ìtumọ̀ Septuagint lédè Griki ní ọ̀rúndún kẹta B.C.E. Ìtumọ̀ yìí yóò di orísun pàtàkì fún ṣíṣe ìfiwéra àwọn ẹsẹ̀ ìwé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
b Ní nǹkan bí ọdún 760 C.E., àwùjọ àwọn Júù kan tí a mọ̀ sí àwọn Karaite fi dandangbọ̀n béèrè fún títúbọ̀ tòròpinpin mọ́ Ìwé Mímọ́. Nítorí pé wọ́n kọ ọláàṣẹ àwọn rabbi, “Òfin Ọlọ́rọ̀-Ẹnu,” àti Talmud, wọ́n ní ìdí púpọ̀ síi láti dáàbòbo àwọn ẹsẹ̀ Bibeli ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé. Àwọn ìdílé kan láti inú ẹgbẹ́ àwùjọ yìí di awọn Masorete ògbógi adàwékọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ìwé Àfọwọ́kọ Àtayébáyé ti Aleppo ní ẹsẹ̀-ìwé àwọn Masorete nínú
[Credit Line]
Bibelmuseum, Münster