Báwo Ni Ìwé Náà Ṣe Là á Já?
Àwọn ìwé ìgbàanì ní àwọn ọ̀tá àdánidá—iná, ọ̀rinrin, àti èbíbu. Bíbélì kò bọ́ lọ́wọ́ irú àwọn ewu bẹ́ẹ̀. Àkọsílẹ̀ nípa bí ó ṣe la irú ìbàjẹ́ nípasẹ̀ àkókò bẹ́ẹ̀ já láti wá di ìwé tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó jù lọ láyé jẹ́ èyí tí ó ta yọ láàárín àwọn ìwé ìgbàanì. Ìtàn yẹn yẹ fún ohun tí ó ju kìkì ìfẹ́ ọkàn bínńtín lọ.
ÀWỌN òǹkọ̀wé Bíbélì kò fín àwọn ọ̀rọ̀ wọn sára òkúta; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọ wọ́n sórí àwọn wàláà amọ̀ tí ó lè wà pẹ́. Dájúdájú wọ́n kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọn sórí àwọn ohun èlò tí ó lè bà jẹ́—ìwé òrépèté (tí a ṣe láti ara koríko yẹn tí ó wà ní Íjíbítì) àti ìwé awọ (tí a fi awọ àwọn ẹranko ṣe).
Kí ní ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìwé tí a kọ́kọ́ kọ? Bóyá ṣe ni ọ̀pọ̀ nínú wọn ti jẹrà tipẹ́tipẹ́ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ọ̀mọ̀wé Oscar Paret ṣàlàyé pé: “Àwọn ohun ìkọ̀wésí méjèèjì yí [ìwé òrépèté àti ti awọ] ni ọ̀rinrin, èbíbu, àti àwọn ìdin lónírúurú pẹ̀lú ń wu léwu gidigidi lọ́nà kan náà. Láti inú ìrírí ojoojúmọ́, a mọ bí ó ti rọrùn tó pé kí bébà, àti awọ tí ó lágbára pàápàá jẹrà ní gbalasa ìta tàbí nínú yàrá kan tí ó ní ọ̀rinrin.”1
Bí àwọn tí a kọ́kọ́ kọ kò bá sí mọ́, báwo wá ni ọ̀rọ̀ àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì ṣe là á já di ọjọ́ wa?
Àwọn Adàwékọ tí Wọ́n Ń Ṣe Nǹkan Fínní-Fínní Pa Á Mọ́
Kété lẹ́yìn tí a kọ àwọn tí a kọ́kọ́ kọ, a bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn ẹ̀dà àfọwọ́kọ jáde. Ní ti gidi, ṣíṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́ di iṣẹ́ àkọ́mọ̀-ọ́nṣe ní Ísírẹ́lì ìgbàanì. (Ẹ́sírà 7:6; Sáàmù 45:1) Àmọ́ o, àwọn ẹ̀dà náà pẹ̀lú ni a kọ sórí àwọn ohun èlò tí ó lè bà jẹ́. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó di dandan pé kí a fi àwọn ẹ̀dà míràn tí a fọwọ́ kọ rọ́pò ìwọ̀nyí. Nígbà tí àwọn tí a kọ́kọ́ kọ pòórá, àwọn ẹ̀dà wọ̀nyí di èyí tí a gbé àwọn ìwé àdàkọ aláfọwọ́kọ ẹ̀yìn ìgbà náà kà. Ṣíṣe àdàkọ àwọn ẹ̀dà náà jẹ́ ìgbésẹ̀ tí ń bá a lọ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Ǹjẹ́ àwọn àṣìṣe tí àwọn adàwékọ ṣe láàárín àwọn ọ̀rúndún wọ̀nyí ha yí àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì pa dà lọ́nà tí ó gadabú bí? Ẹ̀rí sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́.
Àwọn adàwékọ amọṣẹ́dunjú fi ara wọn fún un gidigidi. Wọ́n ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n dà kọ. Wọ́n sì tún máa ń ṣe nǹkan fínní-fínní. Ọ̀rọ̀ Hébérù náà tí a túmọ̀ sí “adàwékọ” ni so·pherʹ, tí ó tọ́ka sí kíka iye nǹkan àti ṣíṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀. Láti ṣàpèjúwe ìpéye àwọn adàwékọ, ṣàgbéyẹ̀wò àwọn Masorete.a Ọ̀mọ̀wé Thomas Hartwell Horne ṣàlàyé nípa wọn pé: “Wọ́n . . . ṣàkọsílẹ̀ èwo ni lẹ́tà tí ó wà láàárín Pentateuch [ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì], èwo ni awẹ́ gbólóhùn tí ó wà láàárín ìwé kọ̀ọ̀kan, àti iye ìgbà mélòó ni lẹ́tà [Hébérù] kọ̀ọ̀kan fara hàn nínú gbogbo Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.”3
Nípa báyìí, àwọn ọ̀jáfáfá adàwékọ máa ń lo ọ̀pọ̀ ọ̀nà láti ṣàtúnyẹ̀wò ìpéye iṣẹ́ wọn. Láti lè yẹra fún pípa kódà lẹ́tà kan nínú Bíbélì jẹ, wọ́n lọ jìnnà débi pé ohun tí wọ́n kà kì í ṣe àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n dà kọ nìkan ṣùgbọ́n àti àwọn lẹ́tà rẹ̀ pẹ̀lú. Ṣàgbéyẹ̀wò ìbaralẹ̀-ṣe-nǹkan kínní-kínní tí èyí ní nínú: A ròyìn rẹ̀ pé wọ́n tọpa 815,140 àwọn lẹ́tà kọ̀ọ̀kan tí ó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù!4 Irú ìsapá aláápọn bẹ́ẹ̀ mú kí ìpéye iṣẹ́ wọn lọ́nà gíga ṣeé ṣe.
Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn adàwékọ wọ̀nyí kì í ṣe àwọn tí kò lè ṣàṣìṣe. Ẹ̀rí kankan ha wà pé, láìka àdàkọ lórí àdàkọ tí a ń ṣe fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sí, ọ̀rọ̀ Bíbélì ṣì wà láìyingin bí?
Ìdí Tí Ó Fìdí Múlẹ̀ Gbọn-in fún Níní Ìgbọ́kànlé
Ìdí tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ wà láti gbà gbọ́ pé ọ̀nà pípéye ni a gbà fi ń tàtaré Bíbélì títí di ọjọ́ wa. Ẹ̀rí èyí fara hàn láti inú àwọn ìwé àdàkọ tí a fọwọ́ kọ—a fojú díwọ̀n iye tí ó tó 6,000 odindi tàbí apá kan lára Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti nǹkan bí 5,000 ti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Lára ìwọ̀nyí ni ìwé àdàkọ aláfọwọ́kọ kan ti Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí a rí ní 1947 èyí tí ó fi àpẹẹrẹ bí ṣíṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́ ṣe péye tó gan-an hàn. A ti wá pè é ní “àwárí títayọ jù lọ lóde òní ní ti ìwé àdàkọ aláfọwọ́kọ.”5
Bí ọ̀dọ́kùnrin olùṣọ́ àgùntàn tí ó jẹ́ Bedouin kan ṣe ń tọ́jú agbo ẹran rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yẹn, ó ṣàwárí ihò inú àpáta kan nítòsí Òkun Òkú. Nínú rẹ̀ ni ó ti rí àwọn ìṣà mélòó kan tí púpọ̀ jù lọ nínú wọn ṣófo. Ṣùgbọ́n, nínú ọ̀kan lára àwọn ìṣà náà, tí a dé pa, ni ó ti rí àkájọ awọ kan tí a rọra fi aṣọ ọ̀gbọ̀ wé, tí ó sì ní odindi ìwé Aísáyà inú Bíbélì nínú. Àmì pé a ti ṣàtúnṣe sí i wà lára àkájọ ìwé tí ó ti gbó ṣùgbọ́n tí a tọ́jú dáradára yìí. Ọ̀dọ́kùnrin olùṣọ́ àgùntàn yí kò mọ̀ pé ògbólógbòó àkájọ ìwé tí ó wà lọ́wọ́ òun yìí yóò di ohun tí yóò gba àfiyèsí jákèjádò ayé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
Kí ni ohun tí ó ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ nínú ìwé àdàkọ aláfọwọ́kọ yìí? Ní 1947, àwọn ìwé àdàkọ aláfọwọ́kọ ti odindi Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí ó lọ́jọ́ lórí jù lọ ni ọjọ́ orí wọn bẹ̀rẹ̀ láti nǹkan bí ọ̀rúndún kẹwàá Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n àkájọ ìwé yìí ni a ṣírò ọjọ́ orí rẹ̀ lọ dé ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Tiwa—tí ó fi ohun tí ó ju ẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú ìyẹn.b Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nífẹ̀ẹ́ gidigidi sí wíwo bí àkájọ ìwé yìí yóò ṣe rí ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn ìwé àdàkọ aláfọwọ́kọ tí a mú jáde ní ìgbà pípẹ́ lẹ́yìn rẹ̀.
Nínú ìwádìí kan, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ fi orí kẹtàléláàádọ́ta Aísáyà nínú Àkájọ Ìwé Òkun Òkú wéra pẹ̀lú ìwé tí àwọn Masorete mú jáde ní ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn rẹ̀. Ìwé náà, A General Introduction to the Bible, ṣàlàyé àbájáde ìwádìí náà pé: “Nínú ọ̀rọ̀ 166 tí ó wà nínú Aísáyà 53, kìkì lẹ́tà mẹ́tàdínlógún ni a gbé ìbéèrè dìde sí. Mẹ́wàá lára lẹ́tà wọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn bí a ṣe ń kọ lẹ́tà ọ̀rọ̀, tí kò nípa lórí òye ohun tí ó ń sọ. Lẹ́tà mẹ́rin mìíràn jẹ́ àyípadà tí kò tó nǹkan nínú ọ̀nà ìgbàkọ̀wé, irú bí àwọn ọ̀rọ̀ aso-ọ̀rọ̀-pọ̀. Lẹ́tà mẹ́ta yòó kù ni ọ̀rọ̀ náà ‘ìmọ́lẹ̀,’ tí a fi kún Ais 53 ẹsẹ 11, kò sì fi bẹ́ẹ̀ nípa tí ó pọ̀ lórí ìtumọ̀ rẹ̀. . . . Nípa báyìí, nínú orí kan tí ó ní ọ̀rọ̀ 166 nínú, kìkì ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo (lẹ́tà mẹ́ta) ni a gbé ìbéèrè dìde sí lẹ́yìn títa á látaré fún ẹgbẹ̀rún ọdún—ọ̀rọ̀ yí kò sì fi bẹ́ẹ̀ yí ìtumọ̀ àyọkà náà pa dà.”7
Ọ̀jọ̀gbọ́n Millar Burrows, tí ó ṣèwádìí lórí àwọn àkájọ ìwé náà fún ọ̀pọ̀ ọdún, ní ṣíṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun tí ó wà nínú rẹ̀, dé ìparí èrò tí ó jọ èyí pé: “Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìyàtọ̀ láàárín . . . àkájọ ìwé Aísáyà àti ìwé àwọn Masorete ni a lè ṣàlàyé pé ó jẹ́ àṣìṣe nínú àdàkọ ṣíṣe. Yàtọ̀ sí ìwọ̀nyí, ìṣọ̀kan tí ó ga púpọ̀, lápapọ̀, ni ó ní pẹ̀lú ọ̀rọ̀ inú àwọn ìwé àdàkọ aláfọwọ́kọ ti sànmánì agbedeméjì. Irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ nínú ìwé àdàkọ aláfọwọ́kọ tí ó lọ́jọ́ lórí tó bẹ́ẹ̀ ń fúnni ní ẹ̀rí amóhundáni-lójú nípa ìpéye àwọn ọ̀rọ̀ ìwé àtayébáyé náà lódindi.”8
A tún lè mú “ẹ̀rí amóhundáni-lójú” jáde nípa bí a ṣe ṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gírí ìkì. Fún àpẹẹrẹ, Codex Sinaiticus, ìwé àdàkọ aláfọwọ́kọ kan tí a fi awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ ṣe, tí ọjọ́ orí rẹ̀ lọ dé ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa, èyí tí a ṣàwárí rẹ̀ ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ṣèrànwọ́ láti f ìdí ìpéye àwọn ìwé àdàkọ aláfọwọ́kọ ti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gírí ìkì tí a mú jáde ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà múlẹ̀. Àjákù ìwé òrépèté tí a kọ Ìhìn Rere Jòhánù sí, èyí tí a ṣàwárí rẹ̀ ní àgbègbè Faiyūm, ní Íjíbítì, ni a ṣírò ọjọ́ orí rẹ̀ lọ dé ìdajì ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa, ó dín ní 50 ọdún lẹ́yìn tí a kọ ti àkọ́kọ́. Inú ilẹ̀ gbígbẹ ni a ti pa á mọ́ sí fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún. Ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn tí a rí nínú àwọn ìwé àdàkọ aláfọwọ́kọ tí a ṣe nígbà pípẹ́ lẹ́yìn náà.9
Ẹ̀rí tipa báyìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn adàwékọ, ní ti tòótọ́, ṣiṣẹ́ tí ó péye gidigidi. Àmọ́ ṣáá o, wọ́n ṣe àwọn àṣìṣe. Kò sí ìwé àdàkọ aláfọwọ́kọ kọ̀ọ̀kan tí ó dá wà láìyingin—títí kan Àkájọ Ìwé Òkun Òkú ti Aísáyà. Ní ti ìyẹn náà, ó ti ṣeé ṣe fún àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ láti ṣàwárí tí wọ́n sì ti ṣe àtúnṣe irú àwọn ìyàbàrá kúrò nínú ti èyí tí a kọ́kọ́ kọ bẹ́ẹ̀.
Ṣíṣe Àtúnṣe Àṣìṣe Àwọn Adàwékọ
Ká ní a sọ pé kí 100 ènìyàn fi ọwọ́ ṣe àdàkọ ìwé kan tí ó gùn. Láìṣiyèméjì, ó kéré tán, àwọn kan lára àwọn adàwékọ náà yóò ṣe àwọn àṣìṣe. Bí ó ti wù kí ó rí, gbogbo wọn kì yóò ṣe irú àwọn àṣìṣe kan náà. Ká ní pé o kó gbogbo 100 ẹ̀dà náà tí o sì fara balẹ̀ fi wọ́n wéra, yóò ṣeé ṣe fún ọ láti wá àwọn àṣìṣe náà jáde kí o sì dá ohun tí ọ̀rọ̀ inú èyí tí a kọ́kọ́ kọ jẹ́ mọ̀, kódà bí o kò bá tí ì rí i rí pàápàá.
Bákan náà, gbogbo àwọn tí ó ṣe àdàkọ Bíbélì kò ṣe irú àwọn àṣìṣe kan náà. Bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìwé àdàkọ aláfọwọ́kọ ti Bíbélì ti wà ní ti gidi nísinsìnyí fún ṣíṣe ìfiwéra fún àyẹ̀wò, ó ti ṣeé ṣe fún àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé láti wá àwọn tí ó jẹ́ àṣìṣe jáde, kí wọ́n dá bí èyí tí a kọ́kọ́ kọ ṣe kà mọ̀, kí wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ àwọn àtúnṣe tí ó yẹ. Nítorí irú àwọn ìwádìí tí a fara balẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé ti mú àwọn ògidì ìwé láti inú àwọn èdè ti èyí tí a kọ́kọ́ kọ jáde. Àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti ti Gírí ìkì wọ̀nyí lo àwọn ọ̀rọ̀ tí ọ̀pọ̀ jù lọ gbà pé ó jẹ́ ti èyí tí a kọ́kọ́ kọ, wọ́n sì sábà máa ń to àwọn ìyàtọ̀ tí ó wà tàbí ọ̀nà tí a tún lè gbà kà á tí ó lè wà nínú àwọn ìwé àdàkọ aláfọwọ́kọ kan sínú àwọn àlàyé ẹsẹ̀ ìwé. Àwọn ẹ̀dà tí a ti tún ṣe láti ọwọ́ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé ni àwọn olùtumọ̀ Bíbélì lò láti fi tú Bíbélì sí àwọn èdè òde òní.
Nítorí náà, nígbà tí o bá mú ìtumọ̀ Bíbélì ti òde òní, ìdí tí ó dájú wà láti ní ìgbọ́kànlé pé àwọn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti ti Gírí ìkì tí a gbé e kà dúró, lọ́nà pípéye tí ó ṣàrà-ọ̀tọ̀, fún àwọn ọ̀rọ̀ inú èyí tí àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì kọ ní àtètèkọ́ṣe.c Àkọsílẹ̀ nípa bí Bíbélì ṣe la ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tí a fi ń ṣe àdàkọ tí a fọwọ́ kọ já jẹ́ ohun tí ó gadabú ní tòótọ́. Nítorí náà, Alàgbà Frederic Kenyon, tí ó f ìgbà pípẹ́ jẹ́ alábòójútó Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, lè wá sọ pé: “Ìtẹnumọ́ kò lè pọ̀ jù pé, ní ti kókó ọ̀rọ̀, àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì dájú . . . A kò lè sọ èyí nípa òmíràn nínú èyíkéyìí nínú ìwé ìgbàanì tí ó wà láyé.”10
[Àwọ̀n àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn Masorete (tí ó túmọ̀ sí “Àwọn Ọ̀gá Nínú Àṣà Àtọwọ́dọ́wọ́”) ni àwọn olùṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, tí wọ́n gbé ayé láàárín ọ̀rúndún kẹfà sí ìkẹwàá Sànmánì Tiwa. Àwọn ẹ̀dà ìwé àdàkọ aláfọwọ́kọ tí wọ́n mú jáde ni a ń pè ní ìwé Masorete.2
b Ìwé Textual Criticism of the Hebrew Bible, láti ọwọ́ Emanuel Tov, sọ pé: “Nípasẹ̀ àyẹ̀wò tí a fi carbon 14 ṣe, 1QIsaa [Àkájọ Ìwé Òkun Òkú ti Aísáyà] ni a ṣírò ọjọ́ orí rẹ̀ sí àárín 202 àti 107 ṣáájú Sànmánì Tiwa (ìṣírò déètì nípa lílo ìlànà wíwo ọ̀nà ìgbàkọ̀wé ìgbàanì jẹ́: 125-100 ṣáájú Sànmánì Tiwa) . . . Ẹ̀rí fi hàn pé ọ̀nà ìgbàṣírò déètì nípa lílo ìlànà wíwo ọ̀nà ìgbàkọ̀wé ìgbàanì tí a mẹ́nu kàn yí, tí a ti mú sunwọ̀n sí i lẹ́nu àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, tí ó sì fàyè gba ṣíṣírò déètì kanlẹ̀ ko lórí ìpìlẹ̀ fífi bí àwọn lẹ́tà ṣe rí àti bí a ṣe tò wọ́n wéra pẹ̀lú ti àwọn orísun mìíràn bí àwọn ẹyọ owó àti àwọn àkọlé tí ó ní déètì, jẹ́ èyí tí ó ṣeé fọkàn tẹ̀.”6
c Ó dájú pé, olúkúlùkù olùtumọ̀ lè yàn láti ṣàìgbagbẹ̀rẹ́ tàbí kí ó fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú ọ̀nà tí ó gbà dìrọ̀ mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ ti èdè Hébérù àti ti Gírí ìkì ti èyí tí a kọ́kọ́ kọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn ọ̀jáfáfá adàwékọ ni wọ́n mú kí Bíbélì máa bá a lọ ní wíwà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àkájọ Ìwé Òkun Òkú ti Aísáyà (ẹ̀dà rẹ̀ tí a fi hàn) rí bákan náà délẹ̀ pẹ̀lú ìwé tí àwọn Masorete mú jáde ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn náà