Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
January 15, 2009
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ Ọ̀SẸ̀:
March 2-8
OJÚ ÌWÉ 3
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 200, 172
March 9-15
Máa Rí Ìdùnnú Nínú Iṣẹ́ Sísọni Dọmọ Ẹ̀yìn
OJÚ ÌWÉ 7
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 130, 211
March 16-22
Ǹjẹ́ ‘Ìríjú Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run’ Ni Ọ́?
OJÚ ÌWÉ 12
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 50, 58
March 23-29
Wò Ó! Ìránṣẹ́ Tí Jèhófà Tẹ́wọ́ Gbà
OJÚ ÌWÉ 21
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 168, 4
March 30–April 5
Ìránṣẹ́ Jèhófà Tí Wọ́n ‘Gún Nítorí Ìrélànàkọjá Wa’
OJÚ ÌWÉ 25
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 224, 214
Ohun Táwọn Àpilẹ̀kọ́ Tá a Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dá Lé
Àpilẹ̀kọ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ 1 sí 3 OJÚ ÌWÉ 3 sí 16
Kí la ó máa ṣe táá fi hàn pé ọmọlẹ́yìn Kristi ni wá? A ó máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi ní ti bó ṣe lo àwọn ànímọ́ rẹ̀ títayọ, irú bí ọgbọ́n rẹ̀ àti ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀. Ó tún gba pé ká máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Ara rẹ̀ sì tún ni pé ká máa fi ìfẹ́ àtọkànwá hàn sáwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Àwọn àpilẹ̀kọ yìí jíròrò bó o ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi láwọn ọ̀nà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí.
Àpilẹ̀kọ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ 4 àti 5 OJÚ ÌWÉ 21 sí 29
Àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Aísáyà tó ṣẹ sí Jésù Kristi lára. Àgbéyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí á mú ká túbọ̀ mọrírì ohun ńlá tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa nípasẹ̀ ikú àti àjíǹde Jésù. Nítorí náà, àwọn àpilẹ̀kọ yìí á jẹ́ ká lè máa fọkàn múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ṣe ní alẹ́ April 9, ọdún yìí.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ:
“Èyí Ni Ọ̀nà. Ẹ Máa Rìn Nínú Rẹ̀”
OJÚ ÌWÉ 17
Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìṣípayá—Apá Kìíní
OJÚ ÌWÉ 30