Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìdúróṣinṣin Ítítáì
“TÍTÓBI àti àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè. Òdodo àti òótọ́ ni àwọn ọ̀nà rẹ, Ọba ayérayé. Ta ni kì yóò bẹ̀rù rẹ ní ti gidi, Jèhófà, tí kì yóò sì yin orúkọ rẹ lógo, nítorí pé ìwọ nìkan ni adúróṣinṣin?” “Àwọn tí ó jagunmólú lọ́wọ́ ẹranko ẹhànnà náà àti lọ́wọ́ ère rẹ̀” ló kọ orín yìí ní ọ̀run, èyí sì jẹ́ ká mọ̀ pé adúróṣinṣin ni Jèhófà. (Ìṣí. 15:2-4) Jèhófà fẹ́ káwọn olùjọsìn rẹ̀ pẹ̀lú máa fi ànímọ́ fífanimọ́ra yìí hàn.—Éfé. 4:24.
Àmọ́, ńṣe ni Sátánì Èṣù ń sapá gidigidi láti ya àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ń sìn. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ló jẹ́ adúróṣinṣin, kódà lábẹ́ àwọn ipò lílekoko. Inú wa dùn pé Jèhófà mọrírì irú ìfọkànsìn bẹ́ẹ̀ gidigidi! Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi dá wa lójú pé: “Olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà, òun kì yóò sì fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀.” (Sm. 37:28) Kí Jèhófà bàa lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin, ó jẹ́ kí ìtàn ọ̀pọ̀ àwọn adúróṣinṣin wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọ̀kan lára irú àwọn ìtàn bẹ́ẹ̀ ni ti Ítítáì ará Gátì.
‘Ọmọ Ilẹ̀ Òkèèrè àti Ìgbèkùn’
Ó jọ pé ọmọ ìlú Gátì tó lókìkí nílẹ̀ Filísínì ni Ítítáì, ọmọ ìlú yìí náà ni Gòláyátì ọkùnrin òmìrán náà, àtàwọn ọ̀tá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì míì. Ìgbà àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa Ítítáì tó jẹ́ jagunjagun akíkanjú yìí ni ìgbà tí Ábúsálómù ṣọ̀tẹ̀ sí Dáfídì Ọba. Àgbègbè Jerúsálẹ́mù ni Ítítáì àtàwọn ẹgbẹ̀ta [600] ọmọ Filísínì tí wọ́n tẹ̀ lé e ń gbé gẹ́gẹ́ bí ìgbèkùn nígbà yẹn.
Ipò tí Ítítáì àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wà yìí lè mú kí Dáfídì rántí ìgbà tóun àti ẹgbẹ̀ta [600] àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì wà nígbèkùn, ní àgbègbè ilẹ̀ Filísínì tí wọ́n sì wọ ìpínlẹ̀ Ákíṣì, ọba ìlú Gátì. (1 Sám. 27:2, 3) Kí ni Ítítáì àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ máa ṣe nígbàtí Ábúsálómù ọmọkùnrin Dáfídì ṣọ̀tẹ̀ sí Dáfídì? Ṣé ẹ̀yìn Ábúsálómù ni wọ́n máa wà ni àbí wọ́n ò tiẹ̀ ní gbè sẹ́yìn ẹnì kankan, àbí ṣe ni wọ́n máa dára pọ̀ mọ́ Dáfídì àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?
Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀, Dáfídì sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù, ó dúró ní ibì kan tí wọ́n ń pè ní Bẹti-méhákì, tó túmọ̀ sí “Ilé tó Jìnnà.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ilé yẹn ló gbẹ̀yìn nílùú Jerúsálẹ́mù ní ìdojúkọ ìhà Òkè Ólífì, kéèyàn tó sọdá àfonífojì Kídírónì. (2 Sám. 15:17) Ibẹ̀ ni Dáfídì ti yẹ àwọn ọmọ ogun ẹ̀ wò bí wọ́n ṣe ń kọjá. Kì í ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ adúróṣinṣin nìkan ló wà pẹ̀lú ẹ̀, àwọn Kérétì àti gbogbo àwọn Pẹ́lẹ́tì tún wà níbẹ̀. Bákan náà, gbogbo àwọn ará Gátì, ìyẹn Ítítáì àti ẹgbẹ̀ta [600] àwọn ọmọ ogun ẹ̀.—2 Sám. 15:18.
Pẹ̀lú ìgbatẹnirò, Dáfídì sọ fún Ítítáì pé: “Èé ṣe tí ìwọ alára pẹ̀lú fi ní láti bá wa lọ? Padà, kí o sì lọ máa gbé pẹ̀lú ọba; [ìyẹn Ábúsálómù] nítorí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ni ọ́, àti pé, ní àfikún sí èyí, ìgbèkùn ni ọ́ láti àgbègbè rẹ. Àná ni ìgbà tí ìwọ dé, èmi yóò ha sì mú kí o máa bá wa rìn káàkiri lónìí, láti lọ nígbà tí mo bá ń lọ sí ibikíbi tí mo bá ń lọ? Padà, kí o sì mú àwọn arakùnrin rẹ padà pẹ̀lú rẹ, kí Jèhófà sì ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ìṣeégbẹ́kẹ̀lé sí ọ!”—2 Sám. 15:19, 20.
Ítítáì wa sọ ọ̀rọ̀ kan tó fi hàn pé adúróṣinṣin ni. Ó dáhùn pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ àti bí olúwa mi ọba ti ń bẹ, ibi tí olúwa mi ọba bá wà, yálà fún ikú tàbí fún ìyè, ibẹ̀ ni ibi tí ìránṣẹ́ rẹ yóò wà!” (2 Sám. 15:21) Èyí lè mú kí Dáfídì rántí ọ̀rọ̀ kan tó jọ èyí tí ìyá ńlá rẹ̀ Rúùtù sọ. (Rúùtù 1: 16, 17) Ọ̀rọ̀ tí Ítítáì sọ wọ Dáfídì lọ́kàn, ló bá sọ fún un pé: “Lọ, kí o sì sọdá” àfonífojì Kídírónì. Látàrí ìyẹn, “Ítítáì ará Gátì sọdá, àti gbogbo àwọn ọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú àti gbogbo àwọn ọmọ kéékèèké tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.”—2 Sám. 15:22.
“Fún Ìtọ́ni Wa”
Róòmù 15:4 sọ pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa.” Nítorí náà, á dáa ká bi ara wa pé, Kí la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Ítítáì? Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó mú kó jẹ́ adúróṣinṣin sí Dáfídì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ítítáì jẹ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó sì tún jẹ́ ìgbèkùn láti Filísíà, ó mọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run alààyè, ó sì mọ̀ pé ẹni àmì òróró Jèhófà ni Dáfídì. Ítítáì kì í ṣe ẹlẹ́tanú, kò ro tìjà tó wà láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn Filísínì. Ítítáì ò wo ti pé Dáfídì ló pa akọgun Filísínì náà Gòláyátì àti ọ̀pọ̀ lára àwọn aráàlú òun. (1 Sám. 18:6, 7) Àmọ́, Ítítáì rí Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì dájú pé ó ti kíyè sí àwọn ànímọ́ fífanimọ́ra tí Dáfídì ní. Nítorí èyí, Dáfídì náà ò kóyán Ítítáì kéré rárá. Kódà, Dáfídì fi ìdá mẹ́ta nínú àwọn ọmọ ogun ẹ̀ sí “ìkáwọ́ Ítítáì” nígbà tí wọ́n fẹ́ lọ bá àwọn ọmọ ogun Ábúsálómù jagun!—2 Sám. 18:2.
Àwa náà ò gbọ́dọ̀ máa ṣe ẹ̀tanú sáwọn èèyàn tàbí ká máa bá wọn jà, torí pé àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, ìran tàbí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ sí tiwa. Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni ká máa wo àwọn ànímọ́ tó dára tí wọ́n ní. Bó ṣe di pé àárín Dáfídì àti Ítítáì wá gún dáadáa fi hàn pé mímọ̀ tá a mọ Jèhófà tá a sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lè mú ká borí ìṣòro ẹ̀tanú.
Bá a ṣe ń ronú lórí àpẹẹrẹ Ítítáì, a lè bi ara wa pé: ‘Ṣé èmi náà jẹ́ adúróṣinṣin sí Dáfídì Ńlá náà, Kristi Jésù? Ṣé mò ń fi hàn pé mo jẹ́ adúróṣinṣin nípa wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn?’ (Mát. 24:14; 28:19, 20) ‘Báwo ni mo ṣe lè sapá tó láti fi hàn pé lóòótọ́ ni mo jẹ́ adúróṣinṣin?’
Àwọn olórí ìdílé pẹ̀lú lè jàǹfààní tí wọ́n bá ṣàṣàrò lórí àpẹẹrẹ ìdúróṣinṣin Ítítáì. Bí Ítítáì ṣe tẹrí ba fún Dáfídì tó sì pinnu láti tẹ̀ lé ọba tí Ọlọ́run ti fòróró yàn, nípa lórí àwọn ìránṣẹ́ Ítítáì. Bákan náà, ìpinnu táwọn olórí ìdílé ṣe torí kí wọ́n lè rọ̀ mọ́ ìjọsìn tòótọ́ lè ní ipa tó dáa lórí gbogbo ìdílé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè fa ìṣòro fúngbà díẹ̀. Àmọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi dá wa lójú pé: “[Jèhófà] yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin.”—Sm. 18:25.
Lẹ́yìn tí Dáfídì ti bá Ábúsálómù jagun, Ìwé Mímọ́ ò tún sọ nǹkan kan nípa Ítítáì mọ́. Síbẹ̀, ìwọ̀nba ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa rẹ̀ jẹ́ ká mọ púpọ̀ nípa ìwà rẹ̀ láàárín àkókò lílekoko nínú ìgbésí ayé Dáfídì. Bó ṣe jẹ́ pé orúkọ Ítítáì wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà ń kíyè sí irú ẹ̀mí ìdúróṣinṣin bẹ́ẹ̀, ó sì máa ń sanni lẹ́san.—Héb. 6:10.