ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w09 8/15 ojú ìwé 12-16
  • Bí Ìrètí Ìyè Àìnípẹ̀kun Lórí Ilẹ̀ Ayé Ṣe Pa Dà Wá Sójú Táyé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Ìrètí Ìyè Àìnípẹ̀kun Lórí Ilẹ̀ Ayé Ṣe Pa Dà Wá Sójú Táyé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìrètí Tí Wọ́n Bò Mọ́lẹ̀
  • Ìmọ́lẹ̀ Òtítọ́ Tàn Nínú Òkùnkùn
  • ‘Ìmọ̀ Tòótọ́ Yóò Di Púpọ̀ Yanturu’
  • “Òmìnira Ológo” Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé!
  • Ṣé Ìyè Àìnípẹ̀kun Lórí Ilẹ̀ Ayé Jẹ́ Ìrètí Tó Wà Fáwọn Kristẹni?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Nígbà Tí Ìmọ̀ Ọlọrun Yóò Bo Ilẹ̀-Ayé
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”
    “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”
  • A Bí Ìjọba Ọlọ́run ní Ọ̀run
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
w09 8/15 ojú ìwé 12-16

Bí Ìrètí Ìyè Àìnípẹ̀kun Lórí Ilẹ̀ Ayé Ṣe Pa Dà Wá Sójú Táyé

“Dáníẹ́lì, ṣe àwọn ọ̀rọ̀ náà ní àṣírí, . . . títí di àkókò òpin. Ọ̀pọ̀ yóò máa lọ káàkiri, ìmọ̀ tòótọ́ yóò sì di púpọ̀ yanturu.”—DÁN. 12:4.

1, 2. Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

LÓDE òní, ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé yé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn dáadáa. (Ìṣí. 7:9, 17) Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn ọmọ aráyé, Ọlọ́run jẹ́ kó di mímọ̀ pé òun kò dá àwọn èèyàn láti lo ọdún díẹ̀ láyé kí wọ́n sì kú, àmọ́ ńṣe lòun dá wọn pé kí wọ́n wà láàyè títí láé.—Jẹ́n. 1:26-28.

2 Ara ìrètí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ni pé ọmọ aráyé ṣì máa pa dà wá sí ipò ìjẹ́pípé irú èyí tí Ádámù wà tẹ́lẹ̀. Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe máa ṣe é tí aráyé yóò fi ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Kí ló wá fà á tí ìrètí yìí fi dèyí tá a tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ní láti mú pa dà wá sójú táyé? Báwo ló ṣe dohun tá a ṣí payá tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn sì wá mọ̀ ọ́n?

Ìrètí Tí Wọ́n Bò Mọ́lẹ̀

3. Kí nìdí tí kò fi yani lẹ́nu pé ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé dohun tí wọ́n bò mọ́lẹ̀?

3 Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn wòlíì èké yóò sọ ẹ̀kọ́ òun dìbàjẹ́ àti pé wọn yóò ṣi èyí tó pọ̀ jù lọ láàárín àwọn èèyàn lọ́nà. (Mát. 24:11) Àpọ́sítélì Pétérù sọ fáwọn Kristẹni pé: “Àwọn olùkọ́ èké yóò . . . wà pẹ̀lú láàárín yín.” (2 Pét. 2:1) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sọ̀rọ̀ nípa “àkókò kan [tí àwọn èèyàn] kò ní gba ẹ̀kọ́ afúnni-nílera, ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn, wọn yóò kó àwọn olùkọ́ jọ fún ara wọn láti máa rìn wọ́n ní etí.” (2 Tím. 4:3, 4) Sátánì ń lọ́wọ́ nínú bí wọ́n ṣe ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà yìí, ó sì ń lo àwọn apẹ̀yìndà tí wọ́n sọ pé àwọn ń ṣe ẹ̀sìn Kristẹni láti bo òtítọ́ amọ́kànyọ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé àti ilẹ̀ ayé mọ́lẹ̀.—Ka 2 Kọ́ríńtì 4:3, 4.

4. Ìrètí tó wà fún aráyé wo làwọn apẹ̀yìndà olórí ẹ̀sìn kọ̀ sílẹ̀?

4 Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé pé Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba gidi kan tó wà lọ́run tó máa fọ́ gbogbo ìjọba tí ẹ̀dá èèyàn gbé kalẹ̀ túútúú tó sì máa fòpin sí wọn. (Dán. 2:44) Nígbà ìṣàkóso tí Kristi máa fi ẹgbẹ̀rún ọdún ṣe, yóò sọ Sátánì sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, yóò jí àwọn òkú dìde, àwọn ọmọ aráyé yóò sì pa dà di ẹni pípé ní ayé. (Ìṣí. 20:1-3, 6, 12; 21:1-4) Àmọ́ àwọn apẹ̀yìndà olórí ṣọ́ọ̀ṣì mú àwọn ìgbàgbọ́ míì wọnú ẹ̀kọ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, Origen ará ìlú Alẹkisáńdíríà tó jẹ́ Bàbá Ìjọ ní ọ̀rúndún kẹta bẹnu àtẹ́ lu àwọn tó gbà gbọ́ pé Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi yóò mú ìbùkún wá sáyé. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Catholic Encyclopedia sọ pé ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kátólíìkì kan tó ń jẹ́ Augustine ará ìlú Hippo (tó gbé ayé láàárín ọdún 354 sí 430 Sànmánì Kristẹni) “gbà gbọ́ pé kò sí ìṣàkóso ẹgbẹ̀rún ọdún kankan tó ń bọ̀.”a

5, 6. Kí ló fà á tí Origen àti Augustine fi ta ko ẹ̀kọ́ nípa ìṣàkóso ẹgbẹ̀rún ọdún?

5 Kí ló fà á tí Origen àti Augustine fi ta ko ẹ̀kọ́ nípa ìṣàkóso ẹgbẹ̀rún ọdún? Ohun tó fà á ni pé ọ̀dọ́ Clement ará Alẹkisáńdíríà ni Origen ti kẹ́kọ̀ọ́. Clement yìí sì gba ẹ̀kọ́ kan tó wá látinú èrò orí Gíríìkì pé ọkàn èèyàn kì í kú. Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan tó ń jẹ́ Werner Jaeger sọ pé níwọ̀n bí ẹ̀kọ́ Plato nípa ọkàn ti kó sí Origen lórí, Origen “mú ẹ̀kọ́ Plato nípa ọkàn àtohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọkàn wọ inú ẹ̀sìn Kristẹni.” Èyí ló mú kí Origen máa kọ́ni pé kì í ṣe ayé yìí làwọn èèyàn ti máa gba ìbùkún èyíkéyìí tí Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún bá máa mú wá.

6 Kó tó di pé Augustine bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ẹ̀sìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, ó ti di agbátẹrù ẹ̀kọ́ èrò orí Plato tí Plotinus gbé jáde ní ọ̀rúndún kẹta. Lẹ́yìn tí Augustine sì wọnú ẹ̀sìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tán, ẹ̀kọ́ èrò orí Plato kò kúrò lọ́kàn rẹ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Augustine ló lànà fún ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ tí Plato mú látinú àbá èrò orí àwọn Gíríìkì tí ẹ̀kọ́ náà fi ráyè wọnú ẹ̀sìn Májẹ̀mú Tuntun.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Catholic Encyclopedia sọ pé Augustine ṣàlàyé pé “òwe lásán ni” Ìṣípayá orí ogún fi Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi pa. Ìwé náà fi kún un pé: ‘Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn nílẹ̀ Yúróòpù àti nílẹ̀ Amẹ́ríkà fara mọ́ àlàyé tó ṣe yìí, èyí sì mú kí ẹ̀kọ́ nípa ìṣàkóso ẹgbẹ̀rún ọdún tí wọ́n gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀ wá dohun tí kò tà létí aráyé mọ́.’

7. Ẹ̀kọ́ èké wo ló mú kí ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun tó wà fún aráyé dohun tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ mọ́, báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?

7 Ẹ̀kọ́ tó mú kí ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun tó wà fún aráyé dohun tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ mọ́ ni ẹ̀kọ́ kan tó wọ́pọ̀ nílẹ̀ Bábílónì ayé àtijọ́, tó sì wá tàn kárí ayé. Ìyẹn ni ẹ̀kọ́ pé èèyàn ní ọkàn tàbí ẹ̀mí tí kò lè kú, tó kàn ń gbé inú ara èèyàn lásán. Nígbà táwọn Ṣọ́ọ̀ṣì gba ẹ̀kọ́ yìí, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn wọn lọ́ Ìwé Mímọ́ lọ́rùn tó fi mú káwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa ọ̀run dà bí èyí tó ń kọ́ni pé gbogbo èèyàn pátá ló máa lọ sọ́run. Èrò tí wọ́n gbé yọ látinú ìyẹn ni pé ìgbà díẹ̀ ni èèyàn yóò lò láyé, ohun tó bá sì ṣe láyé ló máa pinnu bóyá ó máa rí ọ̀run wọ̀ àbí kò ní rí ọ̀run wọ̀. Ohun kan tó fara jọ ìyẹn ṣẹlẹ̀ tó nípa lórí ìrètí táwọn Júù ní nípa ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. Bí àwọn Júù ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í fara mọ́ ẹ̀kọ́ àwọn Gíríìkì pé ọkàn kì í kú, ó di pé wọn ò fi taratara nígbàgbọ́ nínú ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé mọ́. Ẹ ò rí bí èyí ṣe yàtọ̀ pátápátá sóhun tí Bíbélì sọ nípa èèyàn! Èèyàn kì í ṣe ẹ̀dá ẹ̀mí, ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara ni. Jèhófà sọ fún ọkùnrin àkọ́kọ́ pé: “Ekuru ni ọ́.” (Jẹ́n. 3:19) Ayé yìí, ni ibùgbé ayérayé fún èèyàn, kì í ṣe ọ̀run.—Ka Sáàmù 104:5; 115:16.

Ìmọ́lẹ̀ Òtítọ́ Tàn Nínú Òkùnkùn

8. Kí làwọn ọ̀mọ̀wé kan tó ń ṣèwádìí nípa Bíbélì, tí wọ́n gbé ayé láàárín ọdún 1601 sí 1700, sọ nípa ìrètí aráyé?

8 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ẹlẹ́sìn tó pe ara wọn ní Kristẹni ni kò gbà pé ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ìrètí ẹ̀dá, síbẹ̀ gbogbo ìgbà kọ́ ni Sátánì máa ń rí òtítọ́ yẹn bò mọ́lẹ̀. Látìgbà láéláé la ti máa ń ráwọn kéréje kan tó ń fara balẹ̀ ka Bíbélì tí wọ́n sì ń rí ìmọ́lẹ̀ òótọ́ bí wọ́n ṣe ń lóye apá kan nínú bí Ọlọ́run ṣe máa dá aráyé pa dà sí ìjẹ́pípé. (Sm. 97:11; Mát. 7:13, 14; 13:37-39) Bí wọ́n ṣe ń túmọ̀ Bíbélì àti bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ ẹ́ jáde láàárín ọdún 1601 sí 1700 mú kí iye Bíbélì tó wà bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i tí aráyé sì ń lè rí i kà. Lọ́dún 1651, ọ̀mọ̀wé kan kọ̀wé pé níwọ̀n bó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ Ádámù, àwọn èèyàn “ti pàdánù Párádísè àti Ìyè Àìnípẹ̀kun Lórí Ilẹ̀ Ayé,” nípasẹ̀ Kristi, “gbogbo èèyàn yóò dẹni tí a óò mú pa dà wá gbé lórí Ilẹ̀ Ayé; tí ọ̀rọ̀ náà ò bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ìfiwéra yẹn kò bójú mu.” (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:21, 22.) Ọ̀kan lára àwọn akéwì èdè Gẹ̀ẹ́sì tó lókìkí kárí ayé, Ọ̀gbẹ́ni John Milton (tó gbé ayé láàárín ọdún 1608 sí ọdún 1674) kọ ìwé Paradise Lost, tó dá lórí bí aráyé ṣe pàdánù Párádísè, ó sì tún wá kọ ìwé Paradise Regained, tó dá lórí bí aráyé á ṣe jèrè Párádísè pa dà. Nínú àwọn ìwé tí Ọ̀gbẹ́ni Milton kọ yìí, ó sọ̀rọ̀ nípa èrè táwọn olóòótọ́ máa rí gbà nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀kọ́ Bíbélì ni Milton fi èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀ kọ́, ó mọ̀ pé àwọn òtítọ́ kan wà nínú Ìwé Mímọ́ táráyé ò ní lè lóye wọn dáadáa títí dìgbà wíwàníhìn-ín Kristi.

9, 10. (a) Kí ni Isaac Newton kọ nípa ìrètí tó wà fún aráyé? (b) Kí nìdí tí Newton fi rò pé ìgbà wíwàníhìn-ín Kristi ṣì jìnnà?

9 Alàgbà Isaac Newton, tó jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká oníṣirò (tó gbé ayé láàárín ọdún 1642 sí 1727), náà nífẹ̀ẹ́ tó pọ̀ sí Bíbélì. Ó róye pé a óò jí àwọn ẹni mímọ́ dìde sí ìyè ti ọ̀run, wọn yóò sì máa bá Kristi jọba, láìní ṣeé fojú rí. (Ìṣí. 5:9, 10) Ohun tó kọ nípa àwọn tó máa wà lábẹ́ Ìjọba yẹn ni pé: “Àwọn èèyàn yóò ṣì máa gbé orí ilẹ̀ ayé yìí lọ lẹ́yìn ọjọ́ ìdájọ́, kì í sì í ṣe ẹgbẹ̀rún ọdún péré ni wọ́n á lò, bí kò ṣe títí láé.”

10 Newton gbà pé ìgbà wíwàníhìn-ín Kristi ṣì di ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lọ́jọ́ iwájú. Òpìtàn Stephen Snobelen sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ìdí tí Newton fi gbà pé Ìjọba Ọlọ́run di ọjọ́ iwájú ni pé ó gbà pé àwọn apẹ̀yìndà tó gba ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan gbọ́ pọ̀ lọ jàra, ẹ̀kọ́ yìí sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ṣókùnkùn sáwọn èèyàn.” Ìhìn rere ṣì wà ní bíbò mọ́lẹ̀ ní gbogbo àkókò yẹn. Newton ò sì rí ẹ̀ya ìsìn kankan tó pe ara wọn ní Kristẹni tó lè wàásù rẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Kò sẹ́ni tó máa lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì àti ti Jòhánù [èyí tó wà nínú ìwé Ìṣípayá] yìí títí di àkókò òpin.” Nínú àlàyé Newton, ó ní: “Dáníẹ́lì sọ pé, ‘Ọ̀pọ̀ yóò máa lọ káàkiri, ìmọ̀ tòótọ́ yóò sì di púpọ̀ yanturu.’ Ìdí ni pé a gbọ́dọ̀ wàásù Ìhìn Rere náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè kí ìpọ́njú ńlá náà àti òpin ayé tó dé. Tá ò bá wàásù Ìhìn Rere náà kí ìpọ́njú ńlá tó dé, iye àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá láti gbogbo orílẹ̀-èdè tó máa mú imọ̀ ọ̀pẹ dání tí wọ́n máa jáde wá látinú ìpọ́njú ńlá náà kò ní pọ̀ débi tí a kò fi ní lè mọ iye wọn.”—Dán. 12:4; Mát. 24:14; Ìṣí. 7:9, 10.

11. Kí nìdí tí ìrètí tó wà fún aráyé fi ṣókùnkùn sí ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà ayé Milton àti Newton?

11 Ní ìgbà ayé Milton àti Newton, ọ̀ràn ńlá lẹni tó bá sọ pé òun lérò kan tó ta ko ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì dá. Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé ẹ̀yìn tí Milton àti Newton kú ni wọ́n tó gbé ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwé tí wọ́n kọ nípa Bíbélì jáde. Láàárín ọdún 1601 sí 1700, àwọn kan yapa kúrò nínú ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì wọ́n sì lọ dá àwọn ṣọ́ọ̀ṣì míì sílẹ̀ torí pé wọ́n fẹ́ ṣàtúnṣe sí ẹ̀sìn. Síbẹ̀, kò ṣeé ṣe fáwọn wọ̀nyí láti ṣàtúnṣe sí ẹ̀kọ́ pé ọkàn kì í kú. Àwọn onísìn yìí tún ṣì ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Augustine pé Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún kì í ṣohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, pé ó ti kọjá sẹ́yìn. Ṣé ìmọ̀ ti wá di púpọ̀ yanturu ní àkókò òpin yìí?

‘Ìmọ̀ Tòótọ́ Yóò Di Púpọ̀ Yanturu’

12. Ìgbà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ pé ìmọ̀ tòótọ́ yóò di púpọ̀ ní ìmúṣẹ?

12 Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé ní “àkókò òpin,” ohun rere kan yóò máa ṣẹlẹ̀. (Ka Dáníẹ́lì 12:3, 4, 9, 10.) Jésù náà sọ pé: “Ní àkókò yẹn, àwọn olódodo yóò máa tàn yòò bí oòrùn.” (Mát. 13:43) Báwo ni ìmọ̀ tòótọ́ ṣe di púpọ̀ yanturu ní àkókò òpin? Jẹ́ ká wo ìtàn àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láàárín ọdún 1870 sí ọdún 1914 tí àkókò òpin bẹ̀rẹ̀.

13. Kí ni Charles Taze Russell kọ lẹ́yìn tóun àtàwọn tí wọ́n jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ ti ṣàgbéyẹ̀wò ẹ̀kọ́ nípa bí aráyé ṣe máa pa dà sí ipò ìjẹ́pípé?

13 Ní bí ọdún mélòó kan ṣáájú ọdún 1900, àwọn mélòó kan tó nífẹ̀ẹ́ òótọ́ ń wá bí wọ́n ṣe máa lóye “àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera.” (2 Tím. 1:13) Ọ̀kan lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Charles Taze Russell. Lọ́dún 1870, òun àtàwọn mélòó kan tó ń wá òótọ́ dá àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílẹ̀. Nígbà tó di ọdún 1872, wọ́n ṣàgbéyẹ̀wò ẹ̀kọ́ nípa bí aráyé ṣe máa pa dà sí ipò ìjẹ́pípé tí Ádámù wà tẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn náà, Russell kọ̀wé pé: “Ṣáájú ká tó ṣàgbéyẹ̀wò ẹ̀kọ́ yìí, a kò rí i kedere pé ìyàtọ̀ ńlá ló wà láàárín èrè tó wà fún ṣọ́ọ̀ṣì (ìyẹn ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró) tó wà lábẹ́ àdánwò nísinsìnyí àti èrè àwọn olóòótọ́ tó wà láàárín ọmọ aráyé.” Èrè tó wà fáwọn olóòótọ́ láàárín ọmọ aráyé ni pé “wọ́n á pa dà di ẹ̀dá èèyàn pípé gẹ́gẹ́ bí Ádámù baba ńlá wọn tí wọ́n tara rẹ̀ jáde ṣe jẹ́ nígbà tó wà nínú ọgbà Édẹ́nì.” Russell kò fi bò pé àwọn kan ti ran òun lọ́wọ́ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì òun. Àwọn wo nìyẹn?

14. (a) Báwo ni Henry Dunn ṣe lóye ohun tó wà nínú Ìṣe 3:21? (b) Àwọn wo ni Dunn sọ pé wọ́n á máa gbé orí ilẹ̀ ayé títí láé?

14 Henry Dunn wà lára wọn. Ó kọ̀wé nípa “ìmúpadàbọ̀sípò ohun gbogbo èyí tí Ọlọ́run sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ ti ìgbà láéláé.” (Ìṣe 3:21) Dunn mọ̀ pé ara ìmúpadàbọ̀sípò náà ni bí aráyé ṣe máa pa dà sí ipò ìjẹ́pípé nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi. Dunn tún ṣàyẹ̀wò ìbéèrè kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń wá ìdáhùn sí, ìyẹn ni pé, Àwọn wo gan-an ni yóò máa gbé orí ilẹ̀ ayé títí láé? Ó ṣàlàyé pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló máa ní àjíǹde, tá ó máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tí wọ́n sì máa láǹfààní láti lo ìgbàgbọ́ nínú Kristi.

15. Òye wo ni George Storrs ní nípa àjíǹde?

15 Ẹlòmíì ni George Storrs tó ṣèwádìí lọ́dún 1870, tó sì rí i pé àwọn aláìṣòdodo yóò jíǹde kí wọ́n lè láǹfààní ìyè àìnípẹ̀kun. Ó lóye rẹ̀ látinú Ìwé Mímọ́ pé “ikú ló máa gbẹ̀yìn” àwọn tó bá kọ̀ láti lo àǹfààní yìí lára àwọn tó bá jíǹde “‘bí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà bá tilẹ̀ jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún.’” (Aísá. 65:20) Ìlú Brooklyn ní ìpínlẹ̀ New York ni Storrs gbé, òun sì ni olóòtú ìwé ìròyìn tí wọ́n ń pè ní Bible Examiner.

16. Kí ló fìyàtọ̀ sáàárín àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì?

16 Russell náà lóye rẹ̀ látinú Bíbélì pé ó ti tó àkókò láti polongo ìhìn rere náà. Nítorí náà lọ́dún 1879, ó bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower and Herald of Christ’s Presence, tá à ń pè ní Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà báyìí. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ìwọ̀nba àwọn kéréje ló lóye ìrètí tó wà fún aráyé, àmọ́ nígbà tó yá, àwùjọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ń gba ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́, wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Ìgbàgbọ́ kan tó fìyàtọ̀ sáàárín àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni ìgbàgbọ́ pé àwọn èèyàn díẹ̀ ló máa lọ sọ́run nígbà tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn máa rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn pípé.

17. Báwo ni ìmọ̀ tòótọ́ ṣe di púpọ̀?

17 “Àkókò òpin” tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914. Ǹjẹ́ ìmọ̀ tòótọ́ nípa ìrètí tó wà fáráyé di púpọ̀? (Dán. 12:4) Ní ọdún 1913, wọ́n tẹ àwọn ìwàásù Russell sínú ẹgbàá [2,000] ìwé ìròyìn, àpapọ̀ iye àwọn tó sì kà á jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Nígbà tí ọdún 1914 fi máa parí, mílíọ̀nù mẹ́sàn-án èèyàn láti apá ibi tó pọ̀ láyé ló ti wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ “Photo-Drama of Creation,” ìyẹn àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò nípa ìṣẹ̀dá, tó ṣàlàyé Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi. Láti ọdún 1918 sí ọdún 1925, ó ju ọgbọ̀n èdè lọ tí wọ́n fi sọ àsọyé náà, “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tí Ó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kì Yóò Kù Láé” fáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kárí ayé. Àsọyé yìí ṣàlàyé ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. Lọ́dún 1934, ó di mímọ̀ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé àwọn tó bá ń retí àtiní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi. Òye tí wọ́n ní yìí mú kí ìtara wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run sọ jí. Lónìí yìí, ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé ń mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà látọkàn wá.

“Òmìnira Ológo” Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé!

18, 19. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Aísáyà 65:21-25 ṣe sọ pé ìgbésí ayé máa rí?

18 Ọlọ́run mí sí wòlíì Aísáyà láti kọ̀wé nípa irú ìgbádùn táwọn èèyàn Ọlọ́run máa jẹ lórí ilẹ̀ ayé. (Ka Aísáyà 65:21-25.) Lónìí, a ṣì lè rí àwọn igi tí wọ́n ti wà ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìnlá [2,700] ọdún sẹ́yìn tí Aísáyà kọ ọ̀rọ̀ yẹn. Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí ná nígbà tí ẹ̀mí tìrẹ náà bá gùn tó báyẹn pẹ̀lú ara líle?

19 Kò ní sí irú ìgbésí ayé kúkúrú ìsinsìnyí mọ́, léyìí tó jẹ́ pé gbogbo rẹ̀ ò ju ká bí èèyàn, kó lo ìwọ̀nba ọdún tó máa lò láyé kó sì kú. Ẹ̀mí àwọn èèyàn máa gùn títí láé, tó fi jẹ́ pé wọ́n á lè kọ́ irú ilé tó wù wọ́n, wọ́n á lè gbin ohun tó wù wọ́n, wọ́n á sì lè kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ohun tó bá wù wọ́n. Ronú nípa irú àwọn ọ̀rẹ́ tí wàá lè yàn nígbà yẹn. Ńṣe ni ọ̀rẹ́ yín á túbọ̀ máa wọ̀ títí láé. “Òmìnira ológo” mà ni “àwọn ọmọ Ọlọ́run” yóò máa gbádùn láyé nígbà yẹn o!—Róòmù 8:21.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Augustine sọ pé Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún ti Ìjọba Ọlọ́run kì í tún ṣe ọ̀rọ̀ ọjọ́ iwájú mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ó ti bẹ̀rẹ̀ nígbà tí wọ́n dá ṣọ́ọ̀ṣì [Kátólíìkì] sílẹ̀.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Báwo ni ìrètí tó wà fún aráyé ṣe dohun tí wọ́n bò mọ́lẹ̀?

• Òye wo làwọn kan tó ń ka Bíbélì ní láàárín ọdún 1601 sí 1700?

• Báwo ni ìrètí tó wà fún aráyé ṣe túbọ̀ ń ṣe kedere bí ọdún 1914 ṣe ń sún mọ́lé?

• Báwo ni ìmọ̀ nípa ìrètí ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé ṣe di púpọ̀?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

John Milton akéwì rèé (lápá òsì) pẹ̀lú Isaac Newton oníṣirò (lápá ọ̀tún); wọ́n mọ̀ pé ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé wà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ìṣáájú lóye rẹ̀ látinú Ìwé Mímọ́ pé ó ti tó àkókò láti polongo kárí ayé kí aráyé lè mọ ìrètí tó wà fún ọmọ èèyàn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́