Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
January 15, 2010
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ Ọ̀SẸ̀:
March 1-7
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ya Ara Rẹ sí Mímọ́ fún Jèhófà?
OJÚ ÌWÉ 3
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 13, 217
March 8-14
Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ni fún Wa Láti Jẹ́ Ti Jèhófà
OJÚ ÌWÉ 7
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 207, 194
March 15-21
Fi Hàn Pé Ojúlówó Ọmọlẹ́yìn Kristi Ni Ẹ́
OJÚ ÌWÉ 12
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 172, 156
March 22-28
Ìṣàkóso Sátánì Máa Forí Ṣánpọ́n
OJÚ ÌWÉ 24
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 171, 195
March 29–April 4
OJÚ ÌWÉ 28
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 21, 187
Ohun Táwọn Àpilẹ̀kọ Tá a Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dá Lé
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1 àti 2 OJÚ ÌWÉ 3 sí 11
Àwọn àpilẹ̀kọ yìí ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó túmọ̀ sí láti ya ara ẹni sí mímọ́ fún Jèhófà àti ìdí tó fi yẹ kéèyàn ya ara rẹ̀ sí mímọ́. A óò tún jíròrò ìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé a lè ṣe ohun tí Jèhófà retí pé ká máa ṣe. A ó sì tún rí àwọn ìbùkún tí gbogbo àwọn tó jẹ́ ti Jèhófà máa ń gbádùn.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3 OJÚ ÌWÉ 12 sí 16
Àpilẹ̀kọ yìí ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀nà pàtàkì márùn-ún tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ti gbọ́dọ̀ sapá láti fara wé Kristi. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ la fi lè fi ara wa hàn gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ọmọlẹ́yìn Kristi, a ó sì lè ran àwọn ẹni bí àgùntàn lọ́wọ́ láti mọ ìjọ Kristẹni tòótọ́.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4 àti 5 OJÚ ÌWÉ 24 sí 32
Àpilẹ̀kọ kẹrin ṣàgbéyẹ̀wò ìdí tó fi jẹ́ pé pàbó ni ìṣàkóso èèyàn, tí kò ní ọwọ́ Ọlọ́run nínú, máa ń já sí, ó sì tún jẹ́ ká rí bó ṣe jẹ́ pé ìṣàkóso Jèhófà ló dára jù lọ. Àpilẹ̀kọ karùn-ún ṣàlàyé bá a ṣe lè fi hàn pé ìṣàkóso Jèhófà la fara mọ́.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ:
Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Kojú Àwọn Ìṣòro Tó Ń Bá Wọn Fínra 16
Jẹ́ Kí Ìgbé Ayé Rẹ Ojoojúmọ́ Máa Fi Ògo fún Ọlọ́run 21