ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w10 2/1 ojú ìwé 3
  • Bá A Ṣe Lè Mọ Òtítọ́ Nípa Bí Ọ̀run Ṣe Rí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Mọ Òtítọ́ Nípa Bí Ọ̀run Ṣe Rí
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Ọ̀run Ṣe Rí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ṣé Gbogbo Kristẹni Olóòótọ́ Ló Ń Lọ sí Ọ̀run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
w10 2/1 ojú ìwé 3

Bá A Ṣe Lè Mọ Òtítọ́ Nípa Bí Ọ̀run Ṣe Rí

Ó WU àwọn èèyàn gan-an láti lọ sọ́run! Àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí, àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù, àwọn ẹlẹ́sìn Búdà àtàwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì títí kan ọ̀pọ̀ àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn ló ní oríṣiríṣi ìgbàgbọ́ pé èèyàn lè wà láàyè lẹ́yìn ikú. Ojú táwọn èèyàn fi ń wo ọ̀run ni pé, ó jẹ́ ibi ìdẹ̀ra àti ẹwà táwọn á ti bọ́ lọ́wọ́ ìjìyà, táwọn á sì láǹfààní láti tún máa gbé pẹ̀lú àwọn èèyàn àwọn tó ti kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló ń fẹ́ lọ sọ́run, síbẹ̀ kò sẹ́ni tó fẹ́ kú. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

Tó bá jẹ́ pé a dá wa láti kú ká sì lọ sọ́run ni, kí ló dé tí kì í wu ọ̀pọ̀ èèyàn bó ṣe máa ń wu àwọn ọmọdé pé káwọn dàgbà tàbí bó ṣe máa ń wu àwọn ọ̀dọ́ pé lọ́jọ́ kan káwọn ṣègbéyàwó? Ìdí tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn kò fi fẹ́ kú ni pé a ò dá wa bẹ́ẹ̀.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ò fẹ́ kú, àwọn oníwàásù kan ṣì máa ń sọ pé ayé lọjà ọ̀run nilé. Bí àpẹẹrẹ, Theodore Edgar McCarrick tó jẹ́ Kádínà, tó sì tún jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù àgbà tó ti fẹ̀yìn tì ní Washington, D.C., lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ayé yìí kì í ṣe tiwa, ọ̀run ni tiwa.” Ọ̀kan lára ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn ajíhìnrere lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀ rí sọ pé: “Ìdí tá a fi wà láyé ni láti yin Ọlọ́run lógo, ká sì lọ sọ́run . . . nítorí ọ̀run ni ilé wa.”

Orí nǹkan tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ làwọn tó gbà gbọ́ pé èèyàn ń lọ sọ́run lẹ́yìn ikú sábà máa ń gbé ìgbàgbọ́ wọn kà. Ọ̀gbẹ́ni George Barna tó jẹ́ ààrẹ àjọ kan tó máa ń ṣèwádìí nípa ohun tó jẹ́ èrò àwọn ẹlẹ́sìn rí i pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó gbà pé “èèyàn máa ń wàláàyè lẹ́yìn ikú ló jẹ́ pé ohun tí wọ́n ń wò nínú fíìmù, tí wọ́n ń gbọ́ nínú orin àtèyí tí wọ́n ń kà nínú ìwé ló jẹ́ kí wọ́n nírú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀.” Ní Florida, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì Episcopal kan sọ pé: “Ohun tá a mọ̀ nípa ọ̀run kò ju pé ibẹ̀ ni Ọlọ́run ń gbé.”

Àmọ́ Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀run nítorí ó jẹ́ ọ̀kan lára kókó pàtàkì tó wà nínú Bíbélì. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe sọ pé ọ̀run rí? Ǹjẹ́ Ọlọ́run dá èèyàn láti gbé ní ọ̀run? Báwọn èèyàn bá ń lọ sí ọ̀run, kí ni wọ́n máa ṣe níbẹ̀?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]

Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ fi fẹ́ láti lọ sọ́run àmọ́ tó jẹ́ pé díẹ̀ làwọn tó fẹ́ láti kú kí wọ́n lè lọ síbẹ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́