ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 6/15 ojú ìwé 30
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jésù Kọ́ Nikodémù Lẹ́kọ̀ọ́ ní Òru
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Nikodémù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Kíkọ́ Nikodemu Lẹkọọ
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Awọn Wo Ni A Túnbí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 6/15 ojú ìwé 30

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún Nikodémù pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó sọ kalẹ̀ láti ọ̀run, Ọmọ ènìyàn”?—Jòhánù 3:13.

Jésù ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé nígbà tó sọ̀rọ̀ yẹn, kò tíì padà sọ́run níbi tó ti wá. Àmọ́, irú ẹni tá a mọ Jésù sí àti ohun tó ń sọ lọ́wọ́ nígbà tó sọ̀rọ̀ yìí lè jẹ́ ká mọ ohun tó ní lọ́kàn.

Nígbà tí Jésù sọ pé òun “sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run,” ohun tó ń sọ ni pé ọ̀run lòun wà tẹ́lẹ̀ lọ́dọ̀ Baba òun, àmọ́ nígbà tí àkókò tí Ọlọ́run dá tó, Ọlọ́run fi ìwàláàyè Ọmọ rẹ̀ yìí sínú ilé ọlẹ̀ Màríà, èyí tó jẹ́ kó lè bí Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn. (Lúùkù 1:30-35; Gálátíà 4:4; Hébérù 2:9, 14, 17) Lẹ́yìn ikú Jésù, Jèhófà yóò jí i dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí, yóò sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Abájọ tó fi jẹ́ pé nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n pa Jésù, ó gbàdúrà pé: “Baba, ṣe mí lógo lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara rẹ pẹ̀lú ògo tí mo ti ní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ kí ayé tó wà.”—Jòhánù 17:5; Róòmù 6:4, 9; Hébérù 9:24; 1 Pétérù 3:18.

Jésù ò tíì padà sọ́run nígbà tó ń bá Nikodémù tó jẹ́ Farisí àti olùkọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀. Àní, ṣáájú ìgbà yẹn, kò tíì sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó kú tó sì gòkè re ọ̀run níbi táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí wà. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé kò sí wòlíì tó dà bíi Jòhánù Oníbatisí nínú gbogbo àwọn wòlíì Ọlọ́run, síbẹ̀ ó sọ pé “ẹni tí ó kéré jù nínú ìjọba ọ̀run tóbi jù ú.” (Mátíù 11:11) Àpọ́sítélì Pétérù náà ṣàlàyé pé Dáfídì Ọba tó ti kú pàápàá ṣì wà nínú sàréè títí di àkókò yẹn, kò gòkè re ọ̀run. (Ìṣe 2:29, 34) Ìdí pàtàkì kan wà tí Dáfídì, Jòhánù Oníbatisí àtàwọn ọkùnrin mìíràn tí ìgbàgbọ́ wọn ta yọ, àmọ́ tí wọ́n ti kú kí Jésù tó wá sáyé, kò fi lọ sọ́run. Ìdí náà ni pé wọ́n ti kú kí Jésù tó ṣí ọ̀nà tàbí àǹfààní sílẹ̀ fún àwọn ẹ̀dá èèyàn láti di ẹni tó jíǹde sí ọ̀run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé Jésù tó jẹ́ aṣíwájú “ṣe ìfilọ́lẹ̀ . . . ọ̀nà tuntun àti ọ̀nà ààyè” sí ọ̀run.—Hébérù 6:19, 20; 9:24; 10:19, 20.

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jésù kò tíì kú débi pé yóò jíǹde lákòókò yẹn, kí ló wá ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún Nikodémù pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó sọ kalẹ̀ láti ọ̀run, Ọmọ ènìyàn”? (Jòhánù 3:13) Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀rọ̀ tí Jésù ń bá Nikodémù sọ lọ́wọ́ lásìkò náà.

Nígbà tí Nikodémù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alákòóso àwọn Júù wá bá Jésù lọ́wọ́ alẹ́, Jésù sọ fún un pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, láìjẹ́ pé a tún ẹnikẹ́ni bí, kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.” (Jòhánù 3:3) Nikodémù wá bi í pé: ‘Báwo ni ìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe? Báwo ni wọ́n ṣe lè tún èèyàn bí ?’ Ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Jésù ń kọ́ ọ nípa béèyàn ṣe lè dé inú Ìjọba Ọlọ́run ò yé e rárá. Ǹjẹ́ ọ̀nà èyíkéyìí wà tó fi lè lóye ọ̀rọ̀ yìí? Ó wà, àmọ́ kò sí ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ran ara tó lè ṣàlàyé rẹ̀ nítorí pé yàtọ̀ sí Jésù, kò tún sẹ́lòmíì tó tíì lọ sọ́run rí tó máa lè ṣe àlàyé yékéyéké fún un nípa béèyàn ṣe lè wọ Ìjọba ọ̀run. Nítorí náà, Jésù ló kúnjú ìwọ̀n láti ṣàlàyé fún Nikodémù àtàwọn mìíràn nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀ torí pé ọ̀run ló ti sọ̀ kalẹ̀ wá.

Ìbéèrè tó jẹ yọ lórí ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká rí kókó pàtàkì kan tó yẹ ká máa fi sọ́kàn tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Òun ni pé, kò bọ́gbọ́n mu ká kọminú sí ọ̀rọ̀ Bíbélì kan kìkì nítorí pé ó dà bíi pé ó ṣòroó lóye nígbà tá a kà á. Ńṣe ló yẹ ká máa fi ohun tí Bíbélì sọ níbì kan wé ohun tó sọ láwọn ibòmíràn, ká sì rí bí wọ́n ṣe bára mu. Ìyẹn nìkan kọ́ o, lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń bá bọ̀ kí wọ́n tó débi tá à ń kà lè jẹ́ ká ní òye tó ṣe kedere nípa ẹsẹ Bíbélì kan tó rúni lójú.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́