ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w10 3/1 ojú ìwé 24-25
  • Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́ Nípa Àánú Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́ Nípa Àánú Ọlọ́run
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọkùnrin Onírẹ̀lẹ̀ àti Onígboyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Bí Sódómù àti Gòmórà Ṣe Pa Run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Jésù Fi Iṣẹ́ Ìyanu Mú Àwọn Aláìsàn Lára Dá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Òye Jésù Ṣe Àwọn Tó Gbọ́rọ̀ Rẹ̀ Ní Kàyéfì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
w10 3/1 ojú ìwé 24-25

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́ Nípa Àánú Ọlọ́run

JÓNÀ—APÁ KEJÌ

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sáriwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA JÓNÀ 3:1–4:11.

Kí lo rò pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ èrò Jónà bó ṣe wọnú ìlú Nínéfè?

․․․․․

Kí lo kíyè sí nínú ohùn Jónà bó ṣe ń kéde ìdájọ́ Jèhófà?

․․․․․

Ìrora wo ló bá Jónà nígbà tó jókòó sóde ìlú ńlá náà? (Wo Jónà 4:5-8.)

․․․․․

2 ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Kí nìdí tí Jónà fi fẹ́ kí Jèhófà pa Nínéfè run gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tóun sọ?

․․․․․

Lo àwọn ìwé ìwádìí tó o mọ̀, ṣèwádìí nípa (1) bí ewéko akèrègbè ṣe rí, ibi tó ń hù sí, bó ṣe máa ń dàgbà àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, àti (2) ohun tí àpò ìdọ̀họ tí ọba Nínéfè fi bora àti jíjókòó tó jókòó sínú eérú túmọ̀ sí.

․․․․․

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jónà lọ́ tìkọ̀ láti kéde àsọtẹ́lẹ̀ nílùú Nínéfè, kí nìdí tá a fi lè pè é ní wòlíì olóòótọ́ àti onígboyà? (Mátíù 21:28-31)

․․․․․

3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Àwọn èèyàn lè yí ìgbésí ayé burúkú tí wọ́n ń gbé pa dà.

․․․․․

Àánú Jèhófà.

․․․․․

Ìdí tó fi yẹ ká jẹ́ aláàánú.

․․․․․

4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․

Fún ìwádìí síwájú sí i, wo Ilé Ìṣọ́, April 1, 2009, ojú ìwé 14 sí 18.

KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I NÍPA BÍBÉLÌ LÓRÍ ÌKÀNNÌ WA www.watchtower.org ÀTI www.jw.org

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́