Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
April 15, 2010
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ Ọ̀SẸ̀:
May 31–June 6
Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Mú Kí Ìfẹ́ Yín Láti Sin Jèhófà Jinlẹ̀ Sí I
OJÚ ÌWÉ 3
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 89, 41
June 7-13
Ipa Tí Ẹ̀mí Mímọ́ Ń Kó Nínú Bí Ète Jèhófà Ṣe Ń Ní Ìmúṣẹ
OJÚ ÌWÉ 7
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 116, 19
June 14-20
Má Ṣe Máa Wo Àwọn Ohun Tí Kò Ní Láárí!
OJÚ ÌWÉ 20
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 61, 52
June 21-27
Ṣé Ò Ń Tọ Kristi Lẹ́yìn Nígbà Gbogbo?
OJÚ ÌWÉ 24
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 54, 17
Ohun Táwọn Àpilẹ̀kọ Tá a Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dá Lé
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1 OJÚ ÌWÉ 3 SÍ 7
Jèhófà fẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ máa tẹ́tí sí òun, kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ òun, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà òun. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a jíròrò bí Bíbélì kíkà, àdúrà àti ìwà rere ṣe lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti máa sin Jèhófà tọkàntọkàn.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2 OJÚ ÌWÉ 7 SÍ 11
A mọ̀ pé kò sí ohun tó lè dí ète Jèhófà lọ́wọ́ pé kó máà ní ìmúṣẹ. Àpilẹ̀kọ yìí ṣe àrúnkúnná ipa tí ẹ̀mí mímọ́ ti kó, ipa tó ń kó báyìí àti ipa tó ń bọ̀ wá kó lọ́jọ́ iwájú nínú bí ète Ọlọ́run ṣe ń ní ìmúṣẹ.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3 OJÚ ÌWÉ 20 SÍ 24
Bí ayé Sátánì ṣe ń sún mọ́ òpin rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwòrán ọ̀pọ̀ nǹkan tó lè ṣàkóbá fún àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run túbọ̀ ń rọ́ wọlé tọ̀ wá wá. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò díẹ̀ lára àwọn nǹkan wọ̀nyí, a máa rí ìdí tí Sátánì fi ń lò wọ́n àti bá a ṣe lè dáàbò bo ara wa.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4 OJÚ ÌWÉ 24 SÍ 28
Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tí ìtara wa fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run kò fi ní dín kù? Àwọn ìfẹ́ ọkàn wo tó jẹ́ ti ẹ̀dá ló yẹ ká máa ṣọ́ra fún bí a kò bá fẹ́ dẹ́kun títọ Kristi lẹ́yìn? A máa rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ:
Ṣé Ò Ń Jẹ́ Kí Jèhófà Bi Ẹ́ Ní Ìbéèrè? 13
Àdánwò Mú Ká Túbọ̀ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà 16
Jèhófà Fẹ́ Kó O Wà ní “Àlàáfíà” àti Láìséwu 29