Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
May 15, 2010
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ Ọ̀SẸ̀:
June 28–July 4
Ẹ̀yin Ọkùnrin, Ṣé Ẹ̀ Ń Tẹrí Ba fún Ipò Orí Kristi?
OJÚ ÌWÉ 8
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 5, 123
July 5-11
Ẹ̀yin Obìnrin, Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kẹ́ Ẹ Máa Tẹrí Ba fún Ipò Orí?
OJÚ ÌWÉ 12
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 86, 120
July 12-18
Ẹ̀yin Arákùnrin, Ẹ Fúnrúgbìn Nípa Tẹ̀mí, Kẹ́ Ẹ sì Máa Wá Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn!
OJÚ ÌWÉ 24
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 45, 11
July 19-25
Ẹ Má Ṣe Kó Ẹ̀dùn-Ọkàn Bá Ẹ̀mí Mímọ́ Jèhófà
OJÚ ÌWÉ 28
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 71, 26
Ohun Táwọn Àpilẹ̀kọ Tá a Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dá Lé
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1 ÀTI 2 OJÚ ÌWÉ 8 SÍ 17 ▴
Àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ sọ bó ti ṣe pàtàkì tó fún àwọn arákùnrin láti máa tẹrí ba fún ẹni tí í ṣe Orí wọn, ìyẹn Kristi, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń bá àwọn ẹlòmíì lò. Àpilẹ̀kọ kejì ṣàlàyé ojú tí àwọn arábìnrin gbọ́dọ̀ máa fi wo gbólóhùn náà: “Orí obìnrin ni ọkùnrin.”
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3 ÀTI 4 OJÚ ÌWÉ 24 SÍ 32
Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ gba ti pé kí wọ́n máa yááfì àwọn nǹkan nítorí àwọn ẹlòmíì mọ́. A dìídì ṣe àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ lọ́nà tí yóò fi lè ran àwọn ọkùnrin tó ti ṣèrìbọmi lọ́wọ́ láti ṣàgbéyẹ̀wò ojú tí wọ́n fi ń wo ìfara-ẹni-rúbọ àti títẹ́wọ́ gba ojúṣe láti sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà. Àpilẹ̀kọ kejì ṣàlàyé bí a kò ṣe ní máa mú ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run bínú.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ:
Ojú Tí Àwọn Kristẹni Ọ̀rúndún Kìíní Fi Wo Òrìṣà Àwọn Ará Róòmù 3
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Bọ̀wọ̀ fún Àwọn Àgbàlagbà? 6
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Pa Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run Lára Bó O Bá Ń Tọ́jú Ìbátan Rẹ Tó Ń Ṣàìsàn 17
Háránì Ìlú Àtijọ́ Tó Kún fún Ìgbòkègbodò 20
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé 21