Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
June 15, 2010
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ Ọ̀SẸ̀:
July 26–August 1
Àárín Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Lo Ti Lè Rí Ààbò
OJÚ ÌWÉ 6
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 107, 122
August 2-8
OJÚ ÌWÉ 10
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 124, 53
August 9-15
Máa Ṣàkóso Ìbínú Rẹ Kó O Lè “Máa Fi Ire Ṣẹ́gun Ibi”
OJÚ ÌWÉ 15
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 83, 76
August 16-22
Ọ̀rọ̀ Tútù Máa Ń Mú Kí Àjọṣe Wa Pẹ̀lú Àwọn Míì Sunwọ̀n sí I
OJÚ ÌWÉ 20
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 80, 77
August 23-29
Bá A Ṣe Lè Rí Ìtura Nínú Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí
OJÚ ÌWÉ 25
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 57, 48
Ohun Táwọn Àpilẹ̀kọ Tá a Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dá Lé
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1 ÀTI 2 OJÚ ÌWÉ 6 SÍ 14
Àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì àwọn ìbùkún tá à ń rí gbà torí pé a wà nínú ìjọ Kristẹni. A tún máa rí ọ̀nà tí olúkúlùkù wa fi lè máa gbé àwọn ẹlòmíì ró àti bá a ṣe lè máa ran àwọn ará lọ́wọ́ nínú ìjọ wa.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3 ÀTI 4 OJÚ ÌWÉ 15 SÍ 24
Àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí máa ṣàgbéyẹ̀wò bí fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa wá àlàáfíà láìka àìpé tiwa àti tàwọn míì sí. Wọ́n á sì tún jẹ́ ká rí bí ọ̀rọ̀ tútù ṣe lè mú kí àwa àti àwọn míì jọ máa gbé ní ìrẹ́pọ̀.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 5 OJÚ ÌWÉ 25 SÍ 29
Èrò òdì tí aráyé ní ni pé àwọn ìgbòkègbodò téèyàn lè fi tẹ́ ìfẹ́ tara lọ́rùn ló máa ń mú ìtura wá. Àmọ́, àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run ló ń fún àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ìtura. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ní ojúlówó ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tó máa tọ́jọ́.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ:
Ìfẹ́ So Wá Pọ̀—Ìròyìn Ìpàdé Ọdọọdún 3
Bó O Ṣe Lè Fara Dà Á bí Ọkọ Tàbí Aya Rẹ Bá Já Ẹ Jù Sílẹ̀ 29