Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .
Ǹjẹ́ Gbogbo Èèyàn Ló Láǹfààní Kan Náà Láti Mọ Ọlọ́run?
▪ Nígbà tí ẹnì kan béèrè lọ́wọ́ Jésù nípa àṣẹ tó tóbi jù lọ, Jésù dáhùn pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:37) Àmọ́, káwọn èèyàn tó lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, wọ́n ní láti kọ́kọ́ ní ìmọ̀ tó péye nípa rẹ̀. (Jòhánù 17:3) Ǹjẹ́ gbogbo èèyàn ló láǹfààní láti ní ìmọ̀ yìí?
Bíbélì ni olórí ibi tí èèyàn ti lè rí ìmọ̀ Ọlọ́run. (2 Tímótì 3:16) Ọ̀pọ̀ ló ń gbé láàárín àwọn tó ní Bíbélì. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún láǹfààní láti ni ìmọ̀ Ọlọ́run nítorí àwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń wá sọ́dọ̀ wọn déédéé. (Mátíù 28:19) Àwọn ọmọ kan wà tó jẹ́ pé Kristẹni ni òbí wọn, àwọn òbí wọn nífẹ̀ẹ́ wọn, ojoojúmọ́ ni wọ́n sì ń fún àwọn ọmọ yìí láǹfààní láti mọ̀ nípa Ọlọ́run.—Diutarónómì 6:6, 7; Éfésù 6:4.
Àwọn míì sì wà tó jẹ́ pé ibi tí wọ́n gbé dàgbà kò jẹ́ kí wọ́n fi bẹ́ẹ̀ láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Àwọn kan wá látinú ìdílé oníwà ìbàjẹ́ níbi táwọn òbí kò ti ní ìfẹ́ tó yẹ kéèyàn ní fún ọmọ. (2 Tímótì 3:1-5) Ó lè ṣòro fún àwọn tí wọ́n tọ́ dàgbà nírú ìdílé yìí láti máa wo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi Bàbá ọ̀run onífẹ̀ẹ́. Àwọn kan wà tó jẹ́ pé ọdún tí wọ́n lò nílé ẹ̀kọ́ kò tó nǹkan, torí náà, wọn ò lè ka Bíbélì. Àwọn míì sì ti jẹ́ kí ẹ̀kọ́ èké fọ́ èrò inú wọn lójú tàbí kó jẹ́ pé inú ìdílé, àgbègbè tàbí orílẹ̀-èdè tí wọn kò ti fàyè gba ẹ̀kọ́ Bíbélì ni wọ́n ti tọ́ wọn dàgbà. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Ǹjẹ́ àwọn nǹkan yìí lè dí àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n má ṣe láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?
Jésù gbà pé, ìṣòro táwọn kan dojú kọ máa jẹ́ kó ṣòro fún wọn láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì ṣègbọràn sí i. (Mátíù 19:23, 24) Àmọ́ Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ létí pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣòro kan wà tó dà bíi pé agbára èèyàn kò ká, “ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.”—Mátíù 19:25, 26.
Jẹ́ ká wo àwọn òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro yìí. Jèhófà Ọlọ́run ti mú kí wọ́n pín Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kárí ayé lọ́nà tó gbòòrò jù lọ. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé, a máa wàásù ìhìn rere nípa Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́ ṣe fún ayé kárí “gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mátíù 24:14) Lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù ìhìn rere yìí ní ilẹ̀ tó ju ọgbọ̀n lé ní igba [230], wọ́n sì ń ṣe àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] èdè. Àwọn tí kò láǹfààní láti ka Bíbélì pàápàá ṣì lè kẹ́kọ̀ọ́ ohun tó pọ̀ nípa Ọlọ́run tòótọ́ nípa wíwo ohun tó dá.—Róòmù 1:20.
Síwájú sí i, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Gbogbo ọkàn-àyà ni Jèhófà ń wá, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú sì ni ó ń fi òye mọ̀. Bí ìwọ bá wá a, yóò jẹ́ kí o rí òun.” (1 Kíróníkà 28:9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kò ṣèlérí pé gbogbo èèyàn máa láǹfààní kan náà, àmọ́ ó rí i dájú pé àǹfààní wà fún gbogbo àwọn tó lọ́kàn tó tọ́. Ó tún máa rí i dájú pé gbogbo àwọn tí kò láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun lòun máa fún láǹfààní yẹn nípa jíjí wọn dìde sínú ayé titun òdodo.—Ìṣe 24:15.