ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w10 8/1 ojú ìwé 23
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Bó Ṣe Wù Wá La Ṣe Lè Sin Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Tùràrí Sísun Ǹjẹ́ Ó Lóhun Tó Ń Ṣe Nínú Ìjọsìn Tòótọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
w10 8/1 ojú ìwé 23

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ nípa “ìtọ́wọ̀ọ́rìn aláyọ̀ ìṣẹ́gun”?

▪ Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run . . . ń ṣamọ̀nà wa . . . nínú ìtọ́wọ̀ọ́rìn aláyọ̀ ìṣẹ́gun ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, tí ó sì ń mú kí a tipasẹ̀ wa gbọ́ òórùn ìmọ̀ nípa rẹ̀ ní ibi gbogbo! Nítorí fún Ọlọ́run, àwa jẹ́ òórùn dídùn Kristi láàárín àwọn tí a ń gbà là àti láàárín àwọn tí ń ṣègbé; fún àwọn ti ìkẹyìn yìí, òórùn tí ń jáde láti inú ikú sí ikú, fún àwọn ti ìṣáájú òórùn tí ń jáde láti inú ìyè sí ìyè.”—2 Kọ́ríńtì 2:14-16.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí ayẹyẹ táwọn ará Róòmù máa ń ṣe láti ṣàyẹ́sí ọ̀gágun kan fún àṣeyọrí rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá orílẹ̀-èdè wọn. Lákòókò ayẹyẹ yìí, wọ́n máa ń ṣàfihàn àwọn ohun tí wọ́n kó ti ogun bọ̀ àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n, àwọn akọ màlúù tí wọ́n máa fi rúbọ náà máa ń wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì làwọn èèyàn á máa yin ọ̀gágun náà pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Lẹ́yìn àfihàn yìí, wọ́n á wá fi àwọn akọ màlúù náà rúbọ, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n pa ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà.

Ìwé The International Standard Bible Encyclopedia sọ pé, àfiwé nípa “òórùn dídùn Kristi” tó ń ṣàpẹẹrẹ ìyè fún àwọn kan àti ikú fún àwọn míì yìí “ṣeé ṣe kó jẹ́ pé láti inú bí àwọn ará Róòmù ṣe máa ń fi ohun olóòórùn rúbọ nígbà ìtọ́wọ̀ọ́rìn ni ọ̀rọ̀ yìí ti wá.” “Òórùn dídùn tó ń ṣàpẹẹrẹ àṣeyọrí aṣẹ́gun náà ń rán àwọn tí wọ́n mú lẹ́rú náà létí ikú tó ṣeé ṣe kó máa dúró dè wọ́n.”a

Kí ni “àwọn ibi gíga” tá a máa ń mẹ́nu kàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù?

▪ Nígbà tó kù díẹ̀ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Jèhófà sọ fún wọn pé kí wọ́n mú àwọn ibi táwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé níbẹ̀ ti ń jọ́sìn kúrò. Ọlọ́run pàṣẹ pé: “Kí ẹ sì pa gbogbo àwòrán àfòkútaṣe wọn run, gbogbo àwọn ère wọn tí a fi irin dídà ṣe sì ni kí ẹ pa run, gbogbo àwọn ibi gíga ọlọ́wọ̀ wọn sì ni kí ẹ pa rẹ́ ráúráú.” (Númérì 33:52) Ó lè jẹ́ ibi gbalasa lórí àwọn òkè ni wọ́n ti ń ṣe ìjọsìn èké yìí tàbí orí pèpéle tó wà láwọn ibòmíì, irú bí abẹ́ igi tàbí láwọn ìlú. (1 Àwọn Ọba 14:23; 2 Àwọn Ọba 17:29; Ìsíkíẹ́lì 6:3) Ó ṣeé ṣe kí àwọn pẹpẹ, ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ tàbí òpó ọlọ́wọ̀, àwòrán, pẹpẹ tùràrí àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n máa ń lò níbi ìjọsìn wọn wà níbẹ̀.

Ṣáájú kí wọ́n tó kọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ibi tí Jèhófà fọwọ́ sí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń jọ́sìn rẹ̀ ni Ìwé Mímọ́ pè ní àwọn ibi gíga. Sámúẹ́lì tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run rúbọ ní “ibi gíga” kan ní ìlú tí a kò dárúkọ ní ilẹ̀ Súfì. (1 Sámúẹ́lì 9:11-14) Lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ́ tẹ́ńpìlì náà tán, ọ̀pọ̀ ọba tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà sapá láti mú “àwọn ibi gíga” kúrò.—2 Àwọn Ọba 21:3; 23:5-8, 15-20; 2 Kíróníkà 17:1, 6.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ lórí ìtúmọ̀ tẹ̀mí tí àpèjúwe Pọ́ọ̀lù yìí ní, ka Ilé Ìṣọ́, November 15, 1990, ojú ìwé 27.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwòrán àtijọ́ nípa ìtọ́wọ̀ọ́rìn ìṣẹ́gun ti àwọn ará Róòmù ní ọ̀gọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni

[Credit Line]

British Museum ló yọ̀ǹda ká ya fọ́tò yìí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àfọ́kù àwọn òpó ọlọ́wọ̀ tó wà ní Gésérì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́