ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w03 6/1 ojú ìwé 28-30
  • Tùràrí Sísun Ǹjẹ́ Ó Lóhun Tó Ń Ṣe Nínú Ìjọsìn Tòótọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Tùràrí Sísun Ǹjẹ́ Ó Lóhun Tó Ń Ṣe Nínú Ìjọsìn Tòótọ́?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ohun Mímọ́ Lójú Jèhófà”
  • Tùràrí àti Àwọn Kristẹni Ìjímìjí
  • Tùràrí Sísun Lóde Òní
  • Àwọn Àdúrà ‘Tá A Pèsè Sílẹ̀ Bíi Tùràrí’
  • Bí Ọjọ́ Ètùtù Ṣe Kàn Ẹ́
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Bá a Ṣe Lè Bá “Olùgbọ́ Àdúrà” Sọ̀rọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • O Ha ‘Ń pèsè Àdúrà Rẹ Bí Tùràrí’ bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Àwọn Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Ìwé Léfítíkù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
w03 6/1 ojú ìwé 28-30

Tùràrí Sísun Ǹjẹ́ Ó Lóhun Tó Ń Ṣe Nínú Ìjọsìn Tòótọ́?

“ỌLỌ́RUN fẹ́ràn òórùn atasánsán.” Ọ̀rọ̀ táwọn ará Íjíbítì ìgbàanì sábà máa ń sọ nìyẹn. Lójú tiwọn, tùràrí sísun kó apá pàtàkì nínú ìjọsìn wọn. Ìgbàgbọ́ pé àwọn ọlọ́run wà nítòsí ló ń mú àwọn ará Íjíbítì máa sun tùràrí lójoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì wọn, níbi pẹpẹ tí wọ́n ní sínú ilé wọn, kódà nígbà tí wọ́n bá wà nídìí òwò wọn pàápàá. Àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn náà ní àṣà tó fara jọ ìyẹn.

Kí ni Tùràrí? Oje igi olóòórùn dídùn àti gọ́ọ̀mù bí oje igi tùràrí àti básámù ni wọ́n fi ń ṣe é. Ńṣe ni wọ́n máa ń lọ àwọn èròjà wọ̀nyí di ekuru lẹ́búlẹ́bú tí wọ́n sì sábà máa ń fi àwọn èròjà bí nǹkan amóúnjẹ-tasánsán, èèpo igi, àti àwọn òdòdó kún un kó bàa lè ní àwọn òórùn atasánsán kan tó wà fún ète pàtó kan.

Tùràrí jẹ́ ohun fífani lọ́kàn mọ́ra tó sì tún ṣeyebíye gan-an láyé àtijọ́ débi pé àwọn èròjà rẹ̀ di ohun pàtàkì lórí àtẹ. Ńṣe làwọn oníṣòwò tó lọ ń rajà máa ń fi àwọn èròjà wọ̀nyí ṣe ẹrù rù láti àwọn ilẹ̀ jíjìnnà réré. O lè rántí pé àwọn oníṣòwò ọmọ Íṣímáẹ́lì tí wọ́n ‘ń bọ̀ láti Gílíádì, tí ràkúnmí wọn ru gọ́ọ̀mù lábídánúmù àti básámù àti èèpo-igi olóje, tí wọ́n ń gbé e lọ sí Íjíbítì’ ni wọ́n ta Jósẹ́fù ọ̀dọ́mọkùnrin Jékọ́bù fún. (Jẹ́nẹ́sísì 37:25) Àwọn tó ń ra tùràrí wá pọ̀ gan-an débi pé ojú ọ̀nà táwọn oníṣòwò tó ń ta oje igi tùràrí ń gbà, tó dájú pé àwọn oníṣòwò tó ń ta tùràrí ló kọ́kọ́ ń gbabẹ̀ wá di èyí tó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fáwọn èèyàn láti rìnrìn àjò láàárín Éṣíà àti Yúróòpù.

Àwọn èèyàn ṣì máa ń sun tùràrí láwọn ibi ètò ìsìn àtàwọn ààtò nínú ọ̀pọ̀ ìsìn lóde òní. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló tún yàn láti sun tùràrí nínú ilé wọn kí wọ́n kàn lè gbádùn òórùn atasánsán tó ń tinú rẹ̀ jáde. Ojú wo ló yẹ káwọn Kristẹni fi wo tùràrí sísun? Ṣé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà á nínú ìjọsìn? Ẹ jẹ́ ká yẹ ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀ràn yìí wò?

“Ohun Mímọ́ Lójú Jèhófà”

Láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì, tùràrí sísun kó apá tó ṣe pàtàkì gan-an nínú ojúṣe àwọn àlùfáà ní àgọ́ ìjọsìn. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Cyclopedia ti McClintock àti Strong sọ pé: “Láìsí àní-àní, ó ní láti jẹ́ pé ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn tàbí rírú ẹbọ ọlọ́wọ̀ nìkan làwọn Hébérù gbà pé tùràrí sísun wà fún tó fi jẹ́ pé a ò rí ohunkóhun kà nípa ọ̀nà mìíràn tí wọ́n gbà lo tùràrí ju ìyẹn lọ.”

Èròjà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà Ọlọ́run sọ pé kí wọ́n dà pọ̀ kí wọ́n sì sun ní àgọ́ ìjọsìn, ó ní: “Mú àwọn lọ́fínńdà fún ara rẹ: àwọn ẹ̀kán sítákítè àti ọ́níkà àti gábánọ́mù onílọ́fínńdà àti ògidì oje igi tùràrí. Ìpín kan náà ni kí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́. Kí ìwọ sì fi í ṣe tùràrí, àdàlù èròjà atasánsán, iṣẹ́ olùṣe òróró ìkunra, tí a fi iyọ̀ sí, ògidì, ohun mímọ́. Kí o sì gún lára rẹ̀ di ekuru lẹ́búlẹ́bú, kí o sì bù lára rẹ̀ síwájú Gbólóhùn Ẹ̀rí inú àgọ́ ìpàdé.” (Ẹ́kísódù 30:34-36) Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ sọ pé àwọn rábì tó jẹ́ Júù wá fi àwọn èròjà mìíràn kún un níkẹyìn ki wọ́n lè máa lò ó ní tẹ́ńpìlì.

Tùràrí sísun ní àgọ́ ìjọsìn jẹ́ ohun ọlọ́wọ̀, tí wọ́n ń lò fún kìkì ìjọsìn Ọlọ́run. Jèhófà pa á láṣẹ pé: “Tùràrí tí ìwọ yóò fi èròjà yìí ṣe, ni ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe fún ara yín. Kí ó máa bá a lọ fún ọ láti jẹ́ ohun mímọ́ lójú Jèhófà. Ẹnì yòówù tí ó bá ṣe èyíkéyìí bí rẹ̀ láti gbádùn òórùn rẹ̀ ni a óò ké kúrò láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀.” (Ẹ́kísódù 30:37, 38) Àwọn àlùfáà máa ń sun tùràrí lẹ́ẹ̀mejì lójúmọ́ lórí pẹ̀pẹ̀ kan tí wọ́n ṣe fún un. (2 Kíróníkà 13:11) Tó bá sì di Ọjọ́ Ètùtù, àlùfáà àgbà á sun tùràrí ní Ibi Mímọ́ Jù Lọ.—Léfítíkù 16:12, 13.

Kì í ṣe gbogbo tùràrí sísun ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. Ó fìyà jẹ àwọn tí kì í ṣe àlùfáà, tí wọ́n fi ìkùgbù sun ún bí ẹni pé àlùfáà ni wọ́n. (Númérì 16:16-18, 35-40; 2 Kíróníkà 26:16-20) Tùràrí tí orílẹ̀-èdè Júù sun jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà nítorí pé wọ́n ṣì ń lọ́wọ́ nínú ìjọsìn èké lákòókò kan náà tí ọwọ́ wọn sì kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀. Àgàbàgebè wọn ló mú kí Jèhófà polongo pé: “Tùràrí—ó jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí fún mi.” (Aísáyà 1:13, 15) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dẹni tí kò bìkítà nípa ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n gbà máa jọ́sìn Jèhófà mọ́ débi pé wọ́n ti tẹ́ńpìlì pa wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sun tùràrí lórí àwọn pẹpẹ mìíràn. (2 Kíróníkà 28:24, 25) Wọ́n tiẹ̀ lo tùràrí mímọ́ náà nínú ìjọsìn àwọn ọlọ́run èké nígbà tó yá. Irú àwọn àṣà yẹn kó Jèhófà nírìíra gan-an.—Ìsíkíẹ́lì 16:2, 17, 18.

Tùràrí àti Àwọn Kristẹni Ìjímìjí

Májẹ̀mú Òfin náà, títí kan àṣẹ tá a pa fáwọn àlùfáà pé kí wọ́n máa sun tùràrí mímọ́, dópin nígbà tí Kristi fìdí májẹ̀mú tuntun náà múlẹ̀ lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa. (Kólósè 2:14) Kò sí àkọsílẹ̀ kankan tó fi hàn pé àwọn Kristẹni ìjímìjí sun tùràrí nítorí ohun tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìsìn. Látàrí èyí, ìwé gbédègbẹyọ̀ Cyclopedia ti McClintock àti Strong sọ pé: “Ó hàn gbangba pé [àwọn Kristẹni ìjímìjí] ò lo tùràrí. Ní ti tòótọ́, lílò rẹ̀ jẹ́ àṣà àwọn kèfèrí . . . Ìwọ̀nba tùràrí díẹ̀ tí ẹnì kan tó jẹ́ olùfọkànsìn bá dà sórí pẹpẹ kèfèrí ti di ìjọsìn nìyẹn.”

Àwọn Kristian ìjímìjí tún kọ̀ láti sun tùràrí tó máa fi hàn pé wọ́n ka olú ọba Róòmù sí “ọlọ́run,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè pàdánù ẹ̀mí wọn nítorí èyí. (Lúùkù 4:8; 1 Kọ́ríńtì 10:14, 20) Kò ní yani lẹ́nu láti mọ̀ pé àwọn Kristẹni ìjímìjí ò tiẹ̀ bá wọn lọ́wọ́ nínú òwò tùràrí rárá láyé ìgbà yẹn nítorí pé àwọn èèyàn ń lò ó fún ìbọ̀rìṣà.

Tùràrí Sísun Lóde Òní

Ọ̀nà wo làwọn èèyàn gbà ń lo tùràrí lóde òní? Ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ni wọ́n ti máa ń sun tùràrí níbi àwọn ètò àti ààtò ìsìn wọn. Ọ̀pọ̀ ìdílé àwọn ará Éṣíà ló máa ń sun tùràrí nínú tẹ́ńpìlì tàbí níwájú pẹpẹ ìdílé wọn láti bọlá fún àwọn ọlọ́run wọn àti láti dáàbò bo àwọn òkú. Onírúurú ọ̀nà ni wọ́n gbà ń lo tùràrí nínú ètò ìsìn, wọ́n ń lò ó láti jẹ́ kí òórùn atasánsán gba gbogbo inú ilé, láti múni lára dá, láti sọni di mímọ́, àti láti dáàbò boni.

Tùràrí ti wá di ohun tí gbogbo èèyàn tún ń lò báyìí o, kódà àwọn tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn pàápàá ń lò ó. Àwọn kan máa ń sun tùràrí nígbà tí wọ́n bá ń ṣàṣàrò. Ìwé atọ́nà kan tiẹ̀ sọ pé kéèyàn máa lo tùràrí láti dé “ipò kan tó ga nínú ẹ̀mí” kó sì ní “àwọn agbára àrà ọ̀tọ̀ kan” tó ré kọjá ti ẹ̀dá. Ìwé náà tún dámọ̀ràn pé èèyàn ní láti ṣe àwọn ètùtù kan tó ní tùràrí sísun nínú tó sì tún ní í ṣe pẹ̀lú kíkàn sí “àwọn tí agbára wọn ju ti ẹ̀dá lọ” kéèyàn tóó lè rí ojútùú sáwọn ìṣòro igbésí ayé. Ǹjẹ́ irú àwọn àṣà yẹn wà fún Kristẹni?

Jèhófà dẹ́bi fún àwọn tó ń gbìyànjú láti da àwọn àṣà ìsìn èké pọ̀ mọ́ ìjọsìn mímọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàyọlò àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ó sì sọ bó ṣe kan àwọn Kristẹni, ó rọ̀ wọ́n láti yàgò fún àwọn ipa àìmọ́ tí ìsìn èké ní. Ó kọ̀wé pé: “‘Ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́’; ‘dájúdájú, èmi yóò sì gbà yín wọlé.’” (2 Kọ́ríńtì 6:17; Aísáyà 52:11) Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń ṣọ́ra láti yàgò fún ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn èké tàbí ẹgbẹ́ òkùnkùn.—Jòhánù 4:24.

Ṣé lílò táwọn èèyàn máa ń lo tùràrí nínú àwọn ààtò ìsìn àti nínú bíbá ẹ̀mí lò wá túmọ̀ sí pé gbogbo tùràrí sísun ló lòdì? Kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan wulẹ̀ fẹ́ sun tùràrí nínú ilé rẹ̀ kó lè gbádùn òórùn atasánsán tó ń mú jáde. (Òwe 27:9) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Kristẹni kan ní láti gbé àwọn kókó kan yẹ̀ wò nígbà tó bá ń pinnu bóyá kí òun lo tùràrí àbí kí òun máà lò ó. Ǹjẹ́ àwọn mìíràn tó ń gbé lágbègbè ibi tó ò ń gbé lè so lílo tùràrí mọ́ àṣà ìsìn èké? Ǹjẹ́ wọ́n sábà máa ń ka tùràrí sí ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ààtò ìbẹ́mìílò ládùúgbò rẹ? Àbí, ṣé wọ́n máa ń lò ó fún àwọn nǹkan tí kò ní í ṣe pẹ̀lú ìsìn níbẹ̀?

Bí ẹnì kan bá yàn láti sun tùràrí, ó ní láti ronú nípa ẹ̀rí ọkàn òun fúnra rẹ̀ àti bí ọ̀ràn náà yóò ṣe rí lára àwọn ẹlòmíràn kó tó ṣe ìpinnu. (1 Kọ́ríńtì 10:29) Ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù bá kókó yìí mú. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà àti àwọn ohun tí ń gbéni ró fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì. Dẹ́kun yíya iṣẹ́ Ọlọ́run lulẹ̀ kìkì nítorí oúnjẹ. Lóòótọ́, ohun gbogbo ni ó mọ́, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun aṣeniléṣe fún ẹni tí ń jẹun nínú àyè fún ìkọ̀sẹ̀. Ó dára láti má ṣe jẹ ẹran tàbí [mu] wáìnì tàbí ṣe ohunkóhun tí yóò mú arákùnrin rẹ kọsẹ̀.”—Róòmù 14:19-21.

Àwọn Àdúrà ‘Tá A Pèsè Sílẹ̀ Bíi Tùràrí’

Tùràrí sísun láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ àmì tá a fi ń mọ àwọn àdúrà tí Ọlọ́run gbọ́. Ìdí nìyẹn tí Dáfídì onísáàmù fi kọrin sí Jèhófà pé: “Kí a pèsè àdúrà mi sílẹ̀ bí tùràrí níwájú rẹ.”—Sáàmù 141:2.

Àwọn olóòótọ́ ọmọ Ísírẹ́lì kò fojú ààtò kan tí kò ní láárí wo tùràrí sísun. Wọ́n máa ń fara balẹ̀ ṣe tùràrí wọn dáadáa, wọ́n á sì sun ún lọ́nà tí Jèhófà ní kí wọ́n máa gbà sun ún. Dípò lílo tùràrí ní tààràtà, àdúrà tó fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ àti ọ̀wọ̀ fún Baba wa ọ̀run hàn làwọn Kristẹni máa ń gbà lóde òní. Bíi ti tùràrí olóòórùn dídùn táwọn àlùfáà inú tẹ́ńpìlì máa ń sun, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé: “Àdúrà àwọn adúróṣánṣán jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.”—Òwe 15:8.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Tùràrí sísun nínú àgọ́ ìjọsìn àti ní tẹ́ńpìlì jẹ́ ohun ọlọ́wọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Ǹjẹ́ sísun tùràrí nítorí àtiṣe àṣàrò tọ̀nà fún Kristẹni?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́