ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 9/1 ojú ìwé 22-26
  • Bá a Ṣe Lè Bá “Olùgbọ́ Àdúrà” Sọ̀rọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá a Ṣe Lè Bá “Olùgbọ́ Àdúrà” Sọ̀rọ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ohun Tó Pọn Dandan Kéèyàn Tó Lè Bá Ọlọ́run Sọ̀rọ̀
  • Ọ̀nà Táwọn Èèyàn Gbà Bá Jèhófà Sọ̀rọ̀ Lábẹ́ Májẹ̀mú Òfin
  • Ọ̀nà Tá A Ń Gbà Bá Ọlọ́run Sọ̀rọ̀ Nínú Ètò Kristẹni
  • Irú Àwọn Àdúrà Wo Ni Ọlọ́run Máa Ń Gbọ́?
  • O Ha ‘Ń pèsè Àdúrà Rẹ Bí Tùràrí’ bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Sún Mọ́ Ọlọ́run Nípasẹ̀ Àdúrà
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Bí O Ṣe Lè Súnmọ́ Ọlọrun
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Mọyì Àǹfààní Tó O Ní Láti Máa Gbàdúrà sí Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 9/1 ojú ìwé 22-26

Bá a Ṣe Lè Bá “Olùgbọ́ Àdúrà” Sọ̀rọ̀

“Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, àní ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo yóò wá.”—SÁÀMÙ 65:2.

1. Kí ló mú káwa èèyàn yàtọ̀ sáwọn ohun mìíràn tí Ọlọ́run dá sórí ilẹ̀ ayé, àǹfààní wo sì lèyí ṣí sílẹ̀ fún wa?

NÍNÚ gbogbo ẹgbàágbèje ohun ẹlẹ́mìí tí Ọlọ́run dá sórí ilẹ̀ ayé, kìkì àwa èèyàn la lè jọ́sìn Ẹlẹ́dàá. Àwa èèyàn nìkan ló mọ̀ pé ó yẹ ká jọ́sìn Ọlọ́run, tó sì máa ń wù wá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí ló wá fún wa ní àgbàyanu àǹfààní láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Bàbá wa ọ̀run.

2. Ipa búburú wo ni ẹ̀ṣẹ̀ ní lórí àjọṣe àárín èèyàn àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀?

2 Ọlọ́run dá èèyàn lọ́nà tó fi lè bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nítorí pé Ọlọ́run kò dá ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ Ádámù àti Éfà, wọ́n láǹfààní láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ fàlàlà bí ìgbà tí ọmọ kékeré kan bá ń bá bàbá rẹ̀ sọ̀rọ̀. Àmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mú kí wọ́n pàdánù àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ yẹn. Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì pàdánù àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín àwọn àti Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:8-13, 17-24) Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé àwa aláìpé èèyàn tá a jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù ò lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ni? Rárá o, Jèhófà ṣì fún wa láǹfààní láti bá òun sọ̀rọ̀, àmọ́ a ní láti ṣe àwọn ohun kan kíyẹn tó lè ṣeé ṣe. Kí làwọn nǹkan náà?

Àwọn Ohun Tó Pọn Dandan Kéèyàn Tó Lè Bá Ọlọ́run Sọ̀rọ̀

3. Àwọn ohun wo ló pọn dandan fáwọn èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ kí wọ́n tó lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, àpẹẹrẹ wo ló sì fi èyí hàn?

3 Ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé láàárín méjì lára àwọn ọmọkùnrin tí Ádámù bí ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn aláìpé ní kí wọ́n tó lè bá òun sọ̀rọ̀. Kéènì àti Ébẹ́lì gbìyànjú láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípa rírú ẹbọ sí i. Jèhófà tẹ́wọ́ gba ẹbọ Ébẹ́lì, àmọ́ kò gba ẹbọ Kéènì. (Jẹ́nẹ́sísì 4:3-5) Kí nìdí? Hébérù 11:4 sọ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Ébẹ́lì rú ẹbọ tí ó níye lórí ju ti Kéènì sí Ọlọ́run, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ náà tí ó fi ní ẹ̀rí tí a jẹ́ sí i pé ó jẹ́ olódodo.” Ó hàn gbangba pé èèyàn gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ kó tó lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Ohun mìíràn téèyàn tún ní láti ṣe la rí nínú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Kéènì pé: “Bí ìwọ bá yíjú sí ṣíṣe rere, ara rẹ kò ha ní yá gágá bí?” Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run ì bá tẹ́wọ́ gba ẹbọ tí Kéènì rú ká ní Kéènì ṣe iṣẹ́ rere. Àmọ́, Kéènì kọ ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run fún un yìí, ó pa Ébẹ́lì, ó sì di ìsáǹsá. (Jẹ́nẹ́sísì 4:7-12) Nítorí náà, láti ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn èèyàn, a rí i pé ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ rere pọn dandan kéèyàn tó lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀.

4. Kí ló yẹ ká mọ̀ ká tó lè gbàdúrà sí Ọlọ́run?

4 Ká tó lè gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó yẹ ká kọ́kọ́ mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá. Gbogbo èèyàn ni ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ sì jẹ́ ìdènà tí kì í jẹ́ kéèyàn lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Wòlíì Jeremáyà kọ̀wé nípa orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé: “Àwa fúnra wa ti ré ìlànà kọjá . . . O ti fi ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà dí ọ̀nà àbáwọlé sọ́dọ̀ ara rẹ, kí àdúrà má lè là á kọjá.” (Ìdárò 3:42, 44) Síbẹ̀, kò sígbà kan rí tí Ọlọ́run kò múra tán láti gbọ́ àdúrà àwọn tó ń fi ìgbàgbọ́ ké pè é, tí wọ́n ní ọkàn tó dáa, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. (Sáàmù 119:145) Àwọn wo làwọn èèyàn wọ̀nyí, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ látinú àdúrà wọn?

5, 6. Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ látinú ọ̀nà tí Ábúráhámù gbà bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀?

5 Ọ̀kan lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ni Ábúráhámù. Ọlọ́run gbọ́ àdúrà Ábúráhámù, nítorí Ọlọ́run pè é ní “ọ̀rẹ́” òun. (Aísáyà 41:8) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú àwọn ọ̀nà tí Ábúráhámù gbà bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀? Baba ńlá tó jẹ́ olóòótọ́ yìí béèrè lọ́wọ́ Jèhófà nípa ẹni tó máa jogún òun, ó sọ pé: “Kí ni ìwọ yóò fi fún mi, bí èmi ti ń bá a lọ láìbímọ?” (Jẹ́nẹ́sísì 15:2, 3; 17:18) Ní àkókò mìíràn, ó tún sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ jáde nípa àwọn tó ṣeé ṣe kó yè bọ́ nígbà tí Ọlọ́run fẹ́ pa àwọn ẹni ibi tó wà ní Sódómù àti Gòmórà run. (Jẹ́nẹ́sísì 18:23-33) Ábúráhámù tún rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn ẹlòmíràn. (Jẹ́nẹ́sísì 20:7, 17) Àwọn ìgbà mìíràn sì wà tí Ábúráhámù máa ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípa rírú ẹbọ sí Jèhófà bí Ébẹ́lì ti ṣe.—Jẹ́nẹ́sísì 22:9-14.

6 Ní gbogbo àkókò tá a wí yìí, ọkàn Ábúráhámù balẹ̀ láti bá Jèhófà sọ̀rọ̀. Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tó ní, ó mọ̀ pé òun rẹlẹ̀ gan-an sí Ẹlẹ́dàá òun. Kíyè sí ọ̀rọ̀ to sọ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ nínú Jẹ́nẹ́sísì 18:27, níbi tó ti sọ pé: “Jọ̀wọ́, kíyè sí i, èmi fúnra mi ti dáwọ́ lé bíbá Jèhófà sọ̀rọ̀, nígbà tí ó jẹ́ pé ekuru àti eérú ni èmi.” Ohun tó dára gan-an tá a lè fara wé lèyí jẹ́!

7. Àwọn ohun wo làwọn baba ńlá ìgbàanì gbàdúrà nípa rẹ̀ sí Jèhófà?

7 Àwọn baba ńlá ìgbàanì gbàdúrà nípa onírúurú nǹkan, Jèhófà sì gbọ́ àdúrà wọn. Jékọ́bù gba àdúrà kan tó dà bí ẹni pé ó ń jẹ́jẹ̀ẹ́. Lẹ́yìn tó ti bẹ Ọlọ́run pé kó ti òun lẹ́yìn, ó wá ṣèlérí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé: “Ní ti ohun gbogbo tí ìwọ yóò sì fi fún mi ni èmi yóò san ìdá mẹ́wàá rẹ̀ fún ọ láìkùnà.” (Jẹ́nẹ́sísì 28:20-22) Nígbà tó yá tí Jékọ́bù fẹ́ pàdé Ísọ̀, ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó bẹ Jèhófà pé kó dáàbò bo òun, ó ní: “Mo bẹ̀ ọ́, dá mi nídè lọ́wọ́ arákùnrin mi, lọ́wọ́ Ísọ̀, nítorí tí àyà rẹ̀ ń fò mí.” (Jẹ́nẹ́sísì 32:9-12) Jóòbù, baba ńlá náà, gbàdúrà sí Jèhófà nítorí ìdílé rẹ̀, ó sì rú ẹbọ nítorí wọn. Nígbà táwọn mẹ́ta tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jóòbù ṣẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ tó tẹnu wọn jáde, Jóòbù gbàdúrà fún wọn, “Jèhófà sì . . . tẹ́wọ́ gba ojú Jóòbù.” (Jóòbù 1:5; 42:7-9) Àwọn ìtàn wọ̀nyí jẹ́ ká mọ ohun tá a lè bá Jèhófà sọ nínú àdúrà wa. A tún rí i pé Jèhófà múra tán láti gbọ́ àdúrà àwọn tó bá ké pè é lọ́nà tó yẹ.

Ọ̀nà Táwọn Èèyàn Gbà Bá Jèhófà Sọ̀rọ̀ Lábẹ́ Májẹ̀mú Òfin

8. Lábẹ́ májẹ̀mú Òfin, ọ̀nà wo ni wọ́n máa ń gbà mú àwọn ọ̀ràn tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà?

8 Lẹ́yìn tí Jèhófà dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nídè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, ó fún wọn ní májẹ̀mú Òfin. Òfin náà sọ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ẹgbẹ́ àlùfáà kan tó fúnra rẹ̀ yàn. Wọ́n yan àwọn ọmọ Léfì kan láti máa ṣe àlùfáà fún àwọn èèyàn náà. Nígbà táwọn ọ̀ràn tó kan gbogbo orílẹ̀-èdè bá yọjú, ẹnì kan tó jẹ́ aṣojú àwọn èèyàn náà ló máa mú ọ̀ràn náà tọ Ọlọ́run lọ nínú àdúrà. Aṣojú yìí lè jẹ́ ọba tàbí wòlíì. (1 Sámúẹ́lì 8:21, 22; 14:36-41; Jeremáyà 42:1-3) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n ń ya tẹ́ńpìlì sí mímọ́, Sólómọ́nì Ọba gba àdúrà àtọkànwá sí Jèhófà. Jèhófà sì fi hàn pé òun gbọ́ àdúrà Sólómọ́nì nípa fífi ògo rẹ̀ kún inú tẹ́ńpìlì náà, ó sì sọ pé: “etí mi yóò sì ṣí sí àdúrà ní ibí yìí.”—2 Kíróníkà 6:12–7:3, 15.

9. Kí làwọn àlùfáà gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n tó gbàdúrà sí Jèhófà ní ibi mímọ́?

9 Nínú Òfin tí Jèhófà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n tó gbàdúrà sí òun ní ibi mímọ́. Kí ni nǹkan náà? Yàtọ̀ sí fífi ẹran rúbọ ní òròòwúrọ̀ àti ní alaalẹ́, àlùfáà àgbà tún ní láti sun tùràrí onílọ́fínńdà níwájú Jèhófà. Lẹ́yìn náà, àwọn àlùfáà tó wà lábẹ́ rẹ̀ á tún ṣe ohun kan náà yìí, Ọjọ́ Ètùtù nìkan ni wọn kì í ṣe é. Táwọn àlùfáà náà ò bá ṣe ààtò ìjọsìn tó fi ọ̀wọ̀ hàn yìí, inú Jèhófà ò ní dùn sí iṣẹ́ ìsìn wọn.—Ẹ́kísódù 30:7, 8; 2 Kíróníkà 13:11.

10, 11. Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Jèhófà ń tẹ́wọ́ gba àdúrà tẹ́nì kọ̀ọ̀kan bá gbà?

10 Ṣé àwọn aṣojú tá a yàn nìkan ló lè gbàdúrà sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ìgbàanì? Rárá o, Ìwé Mímọ́ fi yé wa pé Jèhófà múra tán láti gbọ́ àdúrà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá gbà. Nígbà tí Sólómọ́nì ń gbàdúrà lákòókò tí wọ́n ń ya tẹ́ńpìlì sí mímọ́, ó bẹ Jèhófà pé: “Àdúrà yòówù, ìbéèrè fún ojú rere yòówù tí ó bá wáyé láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tàbí láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì, . . . nígbà tí ó bá tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ ní tòótọ́ síhà ilé yìí, nígbà náà, kí ìwọ alára gbọ́ láti ọ̀run.” (2 Kíróníkà 6:29, 30) Àkọsílẹ̀ Lúùkù sọ fún wa pé nígbà tí Sekaráyà, bàbá Jòhánù Olùbatisí, ń sun tùràrí nínú ibi mímọ́, ọ̀pọ̀ àwọn olùjọsìn Jèhófà tí wọ́n kì í ṣe àlùfáà “ń gbàdúrà ní òde.” Ó hàn gbangba pé ó jẹ́ àṣà àwọn èèyàn náà láti máa kóra jọ kí wọ́n sì máa gbàdúrà ní òde nígbà táwọn àlùfáà bá wà nínú ibi mímọ́ tí wọ́n ń sun tùràrí sí Jèhófà lórí pẹpẹ oníwúrà.—Lúùkù 1:8-10.

11 Nítorí náà, táwọn èèyàn bá bá Jèhófà sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó tọ́, inú rẹ̀ máa ń dùn láti gbọ́ àdúrà wọn. Bó ṣe ń gbọ́ àdúrà àwọn tó ń ṣojú fún orílẹ̀-èdè náà ló máa ń gbọ́ àdúrà tẹ́nì kọ̀ọ̀kan bá gbà. A ò sí lábẹ́ májẹ̀mú Òfin mọ́ lóde òní. Síbẹ̀, a lè kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan nípa àdúrà látinú ọ̀nà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì gbà bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀.

Ọ̀nà Tá A Ń Gbà Bá Ọlọ́run Sọ̀rọ̀ Nínú Ètò Kristẹni

12. Ètò wo ló wà fáwọn Kristẹni báyìí láti bá Jèhófà sọ̀rọ̀?

12 Abẹ́ ètò tí Kristi fúnra rẹ̀ gbé kalẹ̀ la wà báyìí. Kò tún sí tẹ́ńpìlì kan tó ṣeé fojú rí mọ́ níbi táwọn àlùfáà ti máa ń ṣojú fún gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run tàbí èyí tá a lè máa kọjú sí nígbà tá a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run. Síbẹ̀, Jèhófà ti ṣe ètò kan tá a fi lè máa bá a sọ̀rọ̀. Ètò wo nìyẹn ná? Ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yan Kristi tó sì tún yàn án sípò Àlùfáà Àgbà, tẹ́ńpìlì tẹ̀mí kan bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.a Tẹ́ńpìlì tẹ̀mí yìí ni ètò tuntun tó wà fún jíjọ́sìn Jèhófà, lọ́lá ẹbọ tí Jésù Kristi fi ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa.—Hébérù 9:11, 12.

13. Lórí ọ̀rọ̀ àdúrà, kí ni ohun kan tí tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì tẹ̀mí fi jọra?

13 Ọ̀pọ̀ ohun tó wáyé nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù ló ní í ṣe pẹ̀lú ohun tó ń lọ nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí yìí, títí kan àwọn ohun tó jẹ mọ́ àdúrà. (Hébérù 9:1-10) Bí àpẹẹrẹ, kí ni tùràrí tí wọ́n ń sun lórí pẹpẹ tùràrí inú ibi Mímọ́ tẹ́ńpìlì náà lárààárọ̀ àti ní alaalẹ́ ń ṣàpẹẹrẹ rẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí ìwé Ìṣípayá ti wí, “tùràrí náà . . . túmọ̀ sí àdúrà àwọn ẹni mímọ́.” (Ìṣípayá 5:8; 8:3, 4) Ọlọ́run mí sí Dáfídì láti kọ̀wé pé: “Kí a pèsè àdúrà mi sílẹ̀ bí tùràrí níwájú rẹ.” (Sáàmù 141:2) Nítorí èyí, nínú ètò Kristẹni, tùràrí olóòórùn dídùn náà dúró fún àdúrà àti ìyìn tí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà.—1 Tẹsalóníkà 3:10.

14, 15. Kí la lè sọ nípa àdúrà (a) táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń gbà sí Jèhófà? (b) tí “àwọn àgùntàn mìíràn” ń gbà?

14 Ta ló lè gbàdúrà sí Ọlọ́run nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí yìí? Nínú tẹ́ńpìlì tó ṣeé fojú rí, àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì láǹfààní láti sìn nínú àgbàlá inú lọ́hùn-ún, àmọ́ kìkì àwọn àlùfáà nìkan ló lè wọ inú Ibi Mímọ́. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n ní ìrètí ti ọ̀run ní àǹfààní ńláǹlà kan, ìyẹn ni ipò tẹ̀mí àrà ọ̀tọ̀ tí àgbàlá inú lọ́hùn-ún àti ibi Mímọ́ ṣàpẹẹrẹ rẹ̀, èyí tó mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti máa gbàdúrà kí wọ́n sì máa yin Ọlọ́run lógo.

15 Àwọn tó nírètí láti wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé ńkọ́, ìyẹn àwọn “àgùntàn mìíràn”? (Jòhánù 10:16) Wòlíì Aísáyà sọ pé àwọn èèyàn látinú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá jọ́sìn Jèhófà “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́.” (Aísáyà 2:2, 3) Ó tún kọ̀wé pé “àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè” yóò dara wọn pọ̀ mọ́ Jèhófà. Èyí fi hàn pé Ọlọ́run múra tán láti tẹ́tí sí àdúrà wọn, ó sọ pé: “Èmi yóò . . . mú kí wọ́n máa yọ̀ nínú ilé àdúrà mi.” (Aísáyà 56:6, 7) Ìṣípayá 7:9-15 tún fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé. Ó sọ nípa “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó wá láti inú “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” tí wọ́n kóra jọ tí wọ́n ń jọ́sìn tí wọ́n sì ń gbàdúrà sí Ọlọ́run “tọ̀sán-tòru” bí wọ́n ti dúró sí àgbàlá òde tẹ́ńpìlì tẹ̀mí náà. Ẹ ò rí i pé ìtùnú gidi ló jẹ́ pé gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní ló lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ fàlàlà pẹ̀lú ìdánilójú pé ó ń gbọ́ àdúrà àwọn!

Irú Àwọn Àdúrà Wo Ni Ọlọ́run Máa Ń Gbọ́?

16. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àdúrà àwọn Kristẹni ìjímìjí?

16 Àwọn Kristẹni ìjímìjí máa ń gbàdúrà gan-an. Kí ni àdúrà wọn máa ń dá lé lórí? Àwọn alàgbà gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà láti yan àwọn ọkùnrin tí yóò máa bójú tó iṣẹ́ nínú ètò Ọlọ́run. (Ìṣe 1:24, 25; 6:5, 6) Epafírásì gbàdúrà fún àwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀. (Kólósè 4:12) Àwọn ará nínú ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù gbàdúrà fún Pétérù nígbà tó wà lẹ́wọ̀n. (Ìṣe 12:5) Àwọn Kristẹni ìjímìjí bẹ Ọlọ́run pé kó fáwọn nígboyà láti kojú àtakò, wọ́n sọ pé: “Jèhófà, fiyè sí àwọn ìhalẹ̀mọ́ni wọn, kí o sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹrú rẹ láti máa bá a nìṣó ní fífi àìṣojo rárá sọ ọ̀rọ̀ rẹ.” (Ìṣe 4:23-30) Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù rọ àwọn Kristẹni láti gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fún wọn ní ọgbọ́n nígbà tí wọ́n bá dojú kọ àdánwò. (Jákọ́bù 1:5) Ǹjẹ́ o máa ń mẹ́nu kan irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ nígbà tó o bá ń gbàdúrà sí Jèhófà?

17. Àdúrà àwọn wo ni Jèhófà máa ń gbọ́?

17 Kì í ṣe gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run máa ń gbọ́. Báwo la ṣe lè gbàdúrà kó sì dá wa lójú pé Ọlọ́run yóò gbọ́ àdúrà wa? Àwọn olóòótọ́ èèyàn tí Ọlọ́run tẹ́tí sí àdúrà wọn láyé ọjọ́un fi òótọ́ inú àti ọkàn tó dáa gbàdúrà. Wọ́n tún nígbàgbọ́, wọ́n sì fi èyí hàn nípa ṣíṣe iṣẹ́ rere. Ó dá wá lójú pé Jèhófà yóò tẹ́tí sáwọn tó bá ń gbàdúrà sí i ní irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀ lónìí.

18. Kí làwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣe tí wọ́n bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà àwọn?

18 Nǹkan mìíràn tún wà táwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé èyí, ó ní: “Nípasẹ̀ rẹ̀ àwa . . . ní ọ̀nà ìwọlé sọ́dọ̀ Baba nípasẹ̀ ẹ̀mí kan.” Ta ni Pọ́ọ̀lù ń sọ nípa rẹ̀ nígbà tó kọ̀wé pé, “nípasẹ̀ rẹ̀”? Jésù Kristi ni. (Éfésù 2:13, 18) Bẹ́ẹ̀ ni o, nípasẹ̀ Jésù nìkan la fi lè bá Bàbá sọ̀rọ̀ fàlàlà.—Jòhánù 14:6; 15:16; 16:23, 24.

19. (a) Ìgbà wo ni tùràrí tí wọ́n ń sun ní Ísírẹ́lì di ohun ìríra lójú Jèhófà? (b) Báwo la ṣe lè jẹ́ kí àdúrà wa dà bíi tùràrí olóòórùn dídùn sí Jèhófà?

19 Bá a ṣe sọ níṣàájú, tùràrí táwọn àlùfáà orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì máa ń sun dúró fún àdúrà tó ṣètẹ́wọ́gbà táwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń gbà. Àmọ́ ṣá o, àwọn ìgbà mìíràn wà tí tùràrí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń sùn máa ń jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyẹn nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń sun tùràrí ní tẹ́ńpìlì àmọ́ tí wọ́n tún lọ ń forí balẹ̀ fáwọn òrìṣà. (Ìsíkíẹ́lì 8:10, 11) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, ńṣe ni àdúrà àwọn tó sọ̀ pé Jèhófà làwọn ń sìn àmọ́ tí wọ́n ń ṣe àwọn ohun tó lòdì sófin rẹ̀ máa ń dà bí òórùn burúkú sí Jèhófà. (Òwe 15:8) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká rí i pé gbogbo apá ìgbésí ayé wa ló jẹ́ mímọ́ kí àdúrà wa lè dà bíi tùràrí olóòórùn dídùn sí Ọlọ́run. Inú Jèhófà máa ń dùn sí àdúrà àwọn tó bá ń tẹ̀ lé ọ̀nà òdodo rẹ̀. (Jòhánù 9:31) Àmọ́, àwọn ìbéèrè kan ṣì wà. Báwo ló ṣe yẹ ká máa gbàdúrà? Kí làwọn ohun tó yẹ kí àdúrà wa máa dá lé lórí? Báwo sì ni Ọlọ́run ṣe ń dáhùn àwọn àdúrà wa? Àpilẹ̀kọ wa tó kàn yóò dáhùn àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè mìíràn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ilé Ìṣọ́, May 15, 2001, ojú ìwé 27.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Báwo làwa èèyàn tá a jẹ́ aláìpé ṣe lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà?

• Nínú àdúrà wa, báwo la ṣe lè fara wé àwọn baba ńlá ìgbàanì?

• Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àdúrà àwọn Kristẹni ìjímìjí?

• Ìgbà wo làwọn àdúrà wa máa ń dà bíi tùràrí olóòórùn dídùn sí Ọlọ́run?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi tẹ́wọ́ gba ẹbọ Ébẹ́lì àmọ́ tí kò tẹ́wọ́ gba ti Kéènì?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

“Ekuru àti eérú ni èmi”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

“Èmi yóò san ìdá mẹ́wàá rẹ̀ fún ọ láìkùnà”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ǹjẹ́ àwọn àdúrà rẹ dà bíi tùràrí olóòórùn dídùn sí Jèhófà?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́