O Ha ‘Ń pèsè Àdúrà Rẹ Bí Tùràrí’ bí?
“Kí a pèsè àdúrà mi sílẹ̀ bí tùràrí níwájú rẹ.”—SÁÀMÙ 141:2.
1, 2. Sísun tùràrí dúró fún kí ni?
JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN pàṣẹ fún Mósè wòlíì rẹ̀ pé kí ó pèsè tùràrí mímọ́ fún lílò nínú àgọ́ ìjọsìn Ísírẹ́lì. Èròjà tí Ọlọ́run ní kó pò pọ̀ jẹ́ oríṣi èròjà mẹ́rin tí ń ta sánsán. (Ẹ́kísódù 30:34-38) Olóòórùn dídùn ni lóòótọ́.
2 Májẹ̀mú Òfin tí a bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dá sọ pé kí wọ́n máa sun tùràrí lójoojúmọ́. (Ẹ́kísódù 30:7, 8) Ìlò tùràrí ha ní ìtumọ̀ pàtàkì bí? Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí pé onísáàmù sọ pé: “Kí a pèsè àdúrà mi sílẹ̀ bí tùràrí níwájú rẹ [Jèhófà Ọlọ́run], àti gbígbé tí mo gbé àtẹ́lẹwọ́ mi sókè bí ọrẹ ẹbọ ọkà ìrọ̀lẹ́.” (Sáàmù 141:2) Nínú ìwé Ìṣípayá, àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé àwọn tó yí ìtẹ́ Ọlọ́run lókè ọ̀run ká gbé àwokòtò wúrà tó kún fún tùràrí lọ́wọ́. Àkọsílẹ̀ onímìísí náà kà pé: “Tùràrí náà sì túmọ̀ sí àdúrà àwọn ẹni mímọ́.” (Ìṣípayá 5:8) Nítorí náà, sísun tùràrí olóòórùn dídùn dúró fún àdúrà tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń gbà tọ̀sán tòru.—1 Tẹsalóníkà 3:10; Hébérù 5:7.
3. Kí ló yẹ kó ràn wá lọ́wọ́ láti ‘pèsè àdúrà wa bí tùràrí níwájú Ọlọ́run’?
3 Bí àdúrà wa yóò bá ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí i lórúkọ Jésù Kristi. (Jòhánù 16:23, 24) Ṣùgbọ́n báwo la ṣe lè mú kí àdúrà wa sunwọ̀n sí i? Ó dára, ó yẹ kí gbígbé àwọn àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò láti inú Ìwé Mímọ́ ràn wá lọ́wọ́ láti pèsè àdúrà wa bí tùràrí níwájú Jèhófà.—Òwe 15:8.
Máa Fi Ìgbàgbọ́ Gbàdúrà
4. Báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe wé mọ́ àdúrà tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà?
4 Bí àdúrà wa yóò bá gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run bí tùràrí olóòórùn dídùn, a gbọ́dọ̀ fi ìgbàgbọ́ gbà á. (Hébérù 11:6) Nígbà tí àwọn Kristẹni alàgbà bá rí i pé ẹnì kan tí ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n fún un láti inú Ìwé Mímọ́, “àdúrà ìgbàgbọ́ [wọn] yóò . . . mú aláàárẹ̀ náà lára dá.” (Jákọ́bù 5:15) Àdúrà táa bá fi ìgbàgbọ́ gbà máa ń ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Baba wa ọ̀run, inú rẹ̀ sì máa ń dùn sí fífi tàdúrà-tàdúrà kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Onísáàmù náà fi ẹ̀mí rere hàn nígbà tó kọ ọ́ lórin pé: “Èmi yóò sì gbé àtẹ́lẹwọ́ mi sókè sí àwọn àṣẹ rẹ, tí mo ti nífẹ̀ẹ́, ṣe ni èmi yóò máa fi àwọn ìlànà rẹ ṣe ìdàníyàn mi. Kọ́ mi ní ìwà rere, ìlóyenínú àti ìmọ̀ pàápàá, nítorí pé mo ti lo ìgbàgbọ́ nínú àwọn àṣẹ rẹ.” (Sáàmù 119:48, 66) Ẹ jẹ́ ká fìrẹ̀lẹ̀ ‘tẹ́wọ́’ àdúrà, kí a sì lo ìgbàgbọ́ nípa pípa àṣẹ Ọlọ́run mọ́.
5. Kí ló yẹ ká ṣe bí ọgbọ́n bá kù díẹ̀ káàtó fún wa?
5 Ká sọ pé a kò mọ ọgbọ́n tí a lè fi kojú àdánwò kan. Bóyá kò dá wa lójú pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan pàtó ń ní ìmúṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́. Dípò jíjẹ́ kí èyí jìn wá lẹ́sẹ̀ nípa tẹ̀mí, ẹ jẹ́ ká gbàdúrà fún ọgbọ́n. (Gálátíà 5:7, 8; Jákọ́bù 1:5-8) Ṣùgbọ́n, a kò lè retí pé kí Ọlọ́run dá wa lóhùn lọ́nà àràmàǹdà. A ní láti fi hàn pé òótọ́ inú la fi ń gbàdúrà nípa ṣíṣe ohun tó retí pé kí gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ máa ṣe. Ó pọndandan pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ lọ́nà tí ń fún ìgbàgbọ́ lókun, ní lílo àwọn ìtẹ̀jáde tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pèsè. (Mátíù 24:45-47; Jóṣúà 1:7, 8) Ó tún yẹ ká máa gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ nípa kíkópa déédéé nínú àwọn ìpàdé ènìyàn Ọlọ́run.—Hébérù 10:24, 25.
6. (a) Kí ló yẹ kí gbogbo wa mọ̀ nípa ọjọ́ wa àti ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì? (b) Ní àfikún sí gbígbàdúrà fún ìsọdimímọ́ orúkọ Jèhófà, kí ló tún yẹ ká ṣe?
6 Lónìí, àwọn Kristẹni kan ń lépa àwọn góńgó àti iṣẹ́ ìgbésí ayé tó ń mú kó dà bí ẹni pé wọ́n ti gbàgbé pátápátá pé “àkókò òpin” ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bùṣe. (Dáníẹ́lì 12:4) Ó yẹ kí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn máa gbàdúrà pé kí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ koná mọ́ ìgbàgbọ́ wọn tàbí kí wọ́n fún un lókun nípa kíkíyèsí ẹ̀rí láti inú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé wíwàníhìn-ín Kristi bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1914, nígbà tí Jèhófà fi í jẹ Ọba lókè ọ̀run, àti pé ó ti ń jọba láàárín àwọn ọ̀tá rẹ̀. (Sáàmù 110:1, 2; Mátíù 24:3) Ó yẹ kí ó yé gbogbo wa pé irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bí ìparun ẹ̀sìn èké, ìyẹn, “Bábílónì Ńlá,” àti kíkọlù tí Sátánì tí í ṣe Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù yóò kọlu àwọn ènìyàn Jèhófà, àti gbígbà tí Ọlọ́run Olódùmarè yóò gbà wọ́n nínú ogun Amágẹ́dọ́nì, lè bẹ́ sílẹ̀ lójijì, kí gbogbo rẹ̀ sì ṣẹlẹ̀ láàárín àkókò kúkúrú gan-an. (Ìṣípayá 16:14, 16; 18:1-5; Ìsíkíẹ́lì 38:18-23) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run ká lè wà lójúfò nípa tẹ̀mí. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa fi tọkàntara gbàdúrà pé kí a sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, kí Ìjọba rẹ̀ dé, kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, bí ti ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni, ǹjẹ́ kí a máa bá a nìṣó ní lílo ìgbàgbọ́, kí a sì fi hàn pé àdúrà wa jẹ́ àtọkànwá. (Mátíù 6:9, 10) Bẹ́ẹ̀ ni, ǹjẹ́ kí gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa wá Ìjọba náà àti òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́, kí wọ́n sì máa fi gbogbo agbára wọn nípìn-ín nínú wíwàásù ìhìn rere kí òpin tó dé.—Mátíù 6:33; 24:14.
Máa Yin Jèhófà, Máa Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Rẹ̀
7. Kí ló wú ẹ lórí nípa àdúrà Dáfídì, tí apá kan rẹ̀ wà nínú 1 Kíróníkà 29:10-13?
7 Ọ̀nà pàtàkì láti gbà ‘pèsè àdúrà wa bí tùràrí’ ni láti máa fi ìyìn àti ọpẹ́ àtọkànwá fún Ọlọ́run. Ọba Dáfídì gba irú àdúrà yẹn nígbà tí òun àtàwọn ènìyàn Ísírẹ́lì dá àwọn nǹkan jọ fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà. Dáfídì gbàdúrà pé: “Ìbùkún ni fún ọ, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì baba wa, láti àkókò tí ó lọ kánrin àní dé àkókò tí ó lọ kánrin. Tìrẹ, Jèhófà, ni títóbi àti agbára ńlá àti ẹwà àti ìtayọlọ́lá àti iyì; nítorí ohun gbogbo tí ó wà ní ọ̀run àti ní ilẹ̀ ayé jẹ́ tìrẹ. Tìrẹ ni ìjọba, Jèhófà, ìwọ Ẹni tí ń gbé ara rẹ sókè ṣe olórí pẹ̀lú lórí ohun gbogbo. Ọrọ̀ àti ògo jẹ́ ní tìtorí rẹ, ìwọ sì jọba lé ohun gbogbo; ọwọ́ rẹ sì ni agbára àti agbára ńlá wà, ọwọ́ rẹ sì ni agbára láti sọni di ńlá wà àti láti fi okun fún gbogbo ènìyàn. Wàyí o, Ọlọ́run wa, àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, a sì ń yin orúkọ rẹ alẹ́wàlógo.”—1 Kíróníkà 29:10-13.
8. (a) Àwọn ọ̀rọ̀ ìyìn wo tó wà nínú Sáàmù 148 sí 150 ló wọ̀ ẹ́ lọ́kàn ṣinṣin? (b) Bí èrò wa bá bá ti Sáàmù 27:4 mu, kí la óò máa ṣe?
8 Ọ̀rọ̀ ìyìn àti ọpẹ́ yìí mà wúni lórí o! Àdúrà wa lè má lọ geere báyẹn, ṣùgbọ́n ó lè jẹ́ àtọkànwá bí eléyìí. Ìwé Sáàmù kún fún àdúrà ìyìn àti ọpẹ́. Àṣàyàn ọ̀rọ̀ ìyìn ń bẹ nínú Sáàmù 148 sí 150. Ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pọ̀ nínú sáàmù. Dáfídì kọ ọ́ lórin pé: “Ohun kan ni mo béèrè lọ́wọ́ Jèhófà—ìyẹn ni èmi yóò máa wá, kí n lè máa gbé inú ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé mi, kí n lè máa rí adùn Jèhófà kí n sì lè máa fi ẹ̀mí ìmọrírì wo tẹ́ńpìlì rẹ̀.” (Sáàmù 27:4) Ẹ jẹ́ ká máa hùwà ní ìbámu pẹ̀lú irú àdúrà bẹ́ẹ̀ nípa fífi ìtara kópa nínú gbogbo ìgbòkègbodò ìjọ àwọn ènìyàn Jèhófà. (Sáàmù 26:12) Ṣíṣe èyí àti ṣíṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ yóò jẹ́ ká ní ìdí púpọ̀ fún títọ Jèhófà lọ pẹ̀lú ìyìn àti ìdúpẹ́ àtọkànwá.
Máa Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Wá Ìrànlọ́wọ́ Jèhófà
9. Báwo ni Ọba Ásà ṣe gbàdúrà, kí sì ni ìyọrísí rẹ̀?
9 Tó bá jẹ́ pé tọkàntọkàn la fi ń sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí rẹ̀, kí ó dá wa lójú pé yóò gbọ́ àdúrà wa fún ìrànlọ́wọ́. (Aísáyà 43:10-12) Gbé ọ̀ràn Ọba Ásà ti Júdà yẹ̀ wò. Ṣe ni àlàáfíà jọba ní ọdún mẹ́wàá àkọ́kọ́ lára ọdún mọ́kànlélógójì tó fi ṣèjọba (ọdún 977 sí 937 ṣááju Sànmánì Tiwa). Nígbà tó yá, àádọ́ta ọ̀kẹ́ ọmọ ogun lábẹ́ Síírà ará Etiópíà gbógun ti Júdà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbóguntini náà pọ̀ ju Ásà àti àwọn èèyàn rẹ̀ lọ fíìfíì, wọ́n jáde lọ kò wọ́n lójú. Àmọ́ ṣá o, kí ogun tó bẹ̀rẹ̀, Ásà fi taratara gbàdúrà. Ó lóun mọ̀ pé Jèhófà lágbára láti dáni nídè. Ọba wá tẹ́wọ́ ẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́, ó ní: “Ìwọ ni a gbára lé, orúkọ rẹ sì ni a fi dojú kọ ogunlọ́gọ̀ yìí. Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run wa. Má ṣe jẹ́ kí ẹni kíkú ní okun láti dojú kọ ọ́.” Gbígbà tí Jèhófà gba Júdà là nítorí orúkọ ńlá rẹ̀ yọrí sí ìṣẹ́gun pátápátá. (2 Kíróníkà 14:1-15) Yálà Ọlọ́run gbà wá lọ́wọ́ àdánwò tàbí ó fún wa lókun láti fara dà á, ó dájú pé ó ń gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa fún ìrànwọ́.
10. Tí a kò bá mọ ọ̀nà tí a óò gbé ìṣòro kan gbà, báwo ni àdúrà Ọba Jèhóṣáfátì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
10 Bí a kò bá mọ ọ̀nà tí a óò gbé ìṣòro kan gbà, ẹ jẹ́ ká fọkàn balẹ̀ pé Jèhófà yóò gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa fún ìrànlọ́wọ́. Àpẹẹrẹ èyí wáyé ní ọjọ́ Ọba Jèhóṣáfátì ti Júdà, ẹni tó fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ṣèjọba, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 936 ṣááju Sànmánì Tiwa. Nígbà tí àgbájọ àwọn ọmọ ogun Móábù, ti Ámónì, àti àwọn ti ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Séírì bẹ̀rẹ̀ sí dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ Júdà, Jèhóṣáfátì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ pé: “Ìwọ Ọlọ́run wa, ìwọ kì yóò ha mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún lé wọn lórí? Nítorí pé kò sí agbára kankan nínú wa níwájú ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí tí ń bọ̀ wá gbéjà kò wá; àwa alára kò sì mọ ohun tí à bá ṣe, ṣùgbọ́n ojú wa ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.” Jèhófà dáhùn àdúrà tó fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gbà yẹn, ó jà fún Júdà nípa dídá ìdàrúdàpọ̀ sílẹ̀ lágbo àwọn ọ̀tá, tó fi jẹ́ pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pa ara wọn. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí ba àwọn orílẹ̀-èdè tó yí Júdà ká, àlàáfíà sì jọba ní Júdà. (2 Kíróníkà 20:1-30) Nígbà tí a kò bá rọ́gbọ́n dá sí ìṣòro kan, gẹ́gẹ́ bí Jèhóṣáfátì, a lè gbàdúrà pé: ‘A kò mọ ohun tí à bá ṣe, ṣùgbọ́n ojú rẹ là ń wò o, Jèhófà.’ Ẹ̀mí mímọ́ lè jẹ́ ká rántí àwọn kókó kan nínú Ìwé Mímọ́ tí a ó fi yanjú ìṣòro náà, tàbí kẹ̀, Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ lọ́nà kan tó ta yọ ìrònú ènìyàn.—Róòmù 8:26, 27.
11. Kí la lè rí kọ́ nípa àdúrà, láti inú ìṣarasíhùwà Nehemáyà nípa odi Jerúsálẹ́mù?
11 Ó lè di dandan pé ká tẹra mọ́ àdúrà gbígbà fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run. Nehemáyà kárí sọ, ó sunkún, ó gbààwẹ̀, ó sì gbàdúrà fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ nítorí odi Jerúsálẹ́mù tó ti wó àti ipò àìsírètí táwọn olùgbé Júdà wà. (Nehemáyà 1:1-11) Láìsí àní-àní, àdúrà rẹ̀ gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run bí tùràrí olóòórùn dídùn. Lọ́jọ́ kan, Ọba Atasásítà ará Páṣíà béèrè lọ́wọ́ Nehemáyà tí ìrònú dorí rẹ̀ kodò, pé: “Kí ni ohun náà tí ìwọ ń wá?” Nehemáyà ròyìn pé: “Lójú-ẹsẹ̀, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run.” A dáhùn àdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ ráńpẹ́ yẹn, nítorí pé a gba Nehemáyà láyè láti lọ ṣe ohun tó wà ní góńgó ẹ̀mí rẹ̀, wọ́n jẹ́ kí ó lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ tún odi rẹ̀ tó ti wó kọ́.—Nehemáyà 2:1-8.
Jẹ́ Kí Jésù Kọ́ Ẹ Bí A Ṣe Ń Gbàdúrà
12. Bí ìwọ yóò bá sọ ọ́ lọ́rọ̀ tìrẹ, báwo ni ìwọ yóò ṣe ṣàkópọ̀ lájorí kókó tó wà nínú àdúrà àwòṣe Jésù?
12 Nínú gbogbo àdúrà tó wà nínú Ìwé Mímọ́, èyí tó kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ jù lọ ni àdúrà àwòṣe tí Jésù Kristi gbà gẹ́gẹ́ bí tùràrí olóòórùn dídùn. Ìhìn rere Lúùkù sọ pé: “Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn [Jésù] wí fún un pé: ‘Olúwa, kọ́ wa bí a ṣe ń gbàdúrà, gẹ́gẹ́ bí Jòhánù pẹ̀lú ti kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.’ Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé: ‘Nígbàkigbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ wí pé, “Baba, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Fún wa ní oúnjẹ wa fún òòjọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí òòjọ́ ń béèrè. Sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí àwa fúnra wa pẹ̀lú a máa dárí ji olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè; má sì mú wa wá sínú ìdẹwò.”’” (Lúùkù 11:1-4; Mátíù 6:9-13) Ẹ jẹ́ ká gbé àdúrà yìí yẹ̀ wò, ká rántí pé kì í ṣe àdúrà àkàsórí, bí kò ṣe èyí tí ń tọ́ni sọ́nà.
13. Báwo ni ìwọ yóò ṣe ṣàlàyé ìjẹ́pàtàkì àwọn ọ̀rọ̀ yìí, “Baba, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́”?
13 “Baba, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” Pípe Jèhófà ní Baba jẹ́ àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti ṣe ìyàsímímọ́. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ti ń tara ṣàṣà mú ìṣòro èyíkéyìí tọ baba aláàánú lọ, a ní láti máa wá àkókò fún gbígba àdúrà déédéé, àdúrà tí ń bọlá fún Ọlọ́run tó sì ń bọ̀wọ̀ fún un. (Sáàmù 103:13, 14) Ó yẹ kí àdúrà wa fi ìdàníyàn wa nípa ìsọdimímọ́ orúkọ Jèhófà hàn, nítorí pé a ń hára gàgà láti rí i pé gbogbo ẹ̀gàn tí a mú bá a la mú kúrò. Àní, a fẹ́ ya orúkọ Jèhófà sọ́tọ̀, kí a kà á sí mímọ́, tàbí ọlọ́wọ̀.—Sáàmù 5:11; 63:3, 4; 148:12, 13; Ìsíkíẹ́lì 38:23.
14. Kí ló túmọ̀ sí láti gbàdúrà pé, “Kí ìjọba rẹ dé”?
14 “Kí ìjọba rẹ dé.” Ìjọba náà ni ìṣàkóso Jèhófà tí yóò ṣàkóso nípasẹ̀ ìjọba Mèsáyà lókè ọ̀run ní ọwọ́ Ọmọ rẹ̀ àti “àwọn ẹni mímọ́” tí yóò bá Jésù jọba. (Dáníẹ́lì 7:13, 14, 18, 27; Ìṣípayá 20:6) Yóò “dé” láìpẹ́ láti dojúùjà kọ gbogbo àwọn alátakò ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé, yóò sì mú wọn kúrò lójú ọpọ́n. (Dáníẹ́lì 2:44) Nígbà náà ni ìfẹ́ Jèhófà yóò di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti ń ṣe é lọ́run. (Mátíù 6:10) Ayọ̀ tí yóò mú wá fún gbogbo ẹ̀dá tí ń fi ìdúróṣinṣin sin Ọba Aláṣẹ Àgbáyé yóò mà pọ̀ o!
15. Bíbéèrè ‘oúnjẹ òòjọ́’ lọ́wọ́ Jèhófà fi kí ni hàn?
15 “Fún wa ní oúnjẹ wa fún òòjọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí òòjọ́ ń béèrè.” Bíbéèrè oúnjẹ “òòjọ́” lọ́wọ́ Jèhófà fi hàn pé a kò béèrè fún ìpèsè tó kúnlé-kúnnà, bí kò ṣe tòòjọ́ nìkan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a gbẹ́kẹ̀ lé ìpèsè Ọlọ́run, síbẹ̀ a ń ṣiṣẹ́, a sì ń lo gbogbo ọ̀nà bíbójúmu tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa láti fi wá oúnjẹ àti àwọn ohun kòṣeémánìí mìíràn. (2 Tẹsalóníkà 3:7-10) Àmọ́ o, a gbọ́dọ̀ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olùpèsè yìí láti ọ̀run, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀, ọgbọ́n rẹ̀, àti agbára rẹ̀ ló mú kó pèsè nǹkan wọ̀nyí fún wa.—Ìṣe 14:15-17.
16. Báwo la ṣe lè rí ìdáríjì Ọlọ́run gbà?
16 “Dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí àwa fúnra wa pẹ̀lú a máa dárí ji olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè.” Níwọ̀n bí a ti jẹ́ aláìpé àti ẹlẹ́ṣẹ̀, a kò lè dé ojú ìwọ̀n gbogbo ohun tí ọ̀pá ìdíwọ̀n Jèhófà béèrè. Fún ìdí yìí, a ní láti máa gbàdúrà fún ìdáríjì rẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù. Ṣùgbọ́n bí a bá fẹ́ kí “Olùgbọ́ àdúrà” lo àǹfààní ẹbọ yẹn fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, a gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà, kí a sì ṣe tán láti gba ìbáwí yòówù tó bá fún wa. (Sáàmù 65:2; Róòmù 5:8; 6:23; Hébérù 12:4-11) Síwájú sí i, a lè retí kí Ọlọ́run dárí jì wá, kìkì bí a bá “ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa,” ìyẹn, àwọn tó ṣẹ̀ wá.—Mátíù 6:12, 14, 15.
17. Kí ni ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ náà, “Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò”?
17 “Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò.” Nígbà mìíràn Bíbélì máa ń sọ pé Jèhófà ṣe nǹkan kan, nígbà tó jẹ́ pé ó kàn gbà á láyè ni. (Rúùtù 1:20, 21) Ọlọ́run kì í fi ẹ̀ṣẹ̀ dán wa wò. (Jákọ́bù 1:13) Èṣù àti ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ wa àti ayé yìí ló máa ń fi ohun búburú dán wa wò. Sátánì ni Adẹniwò tí ń gbìyànjú láti sún wa dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. (Mátíù 4:3; 1 Tẹsalóníkà 3:5) Nígbà táa bá bẹ̀bẹ̀ pé, “Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò,” a ń bẹ Ọlọ́run pé kí ó má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa yẹ̀ nígbà tí a bá dán wa wò láti ṣàìgbọràn sí i. Ó lè tọ́ wa sọ́nà tí a kò fi ní juwọ́ sílẹ̀, tí Sátánì, “ẹni burúkú náà,” kò fi ní rí wa gbéṣe.—Mátíù 6:13; 1 Kọ́ríńtì 10:13.
Máa Ṣiṣẹ́ ní Ìbámu Pẹ̀lú Àdúrà Rẹ
18. Báwo la ṣe lè máa ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà wa fún ìgbéyàwó àti ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀?
18 Àdúrà àwòṣe Jésù kárí àwọn kókó pàtàkì-pàtàkì, ṣùgbọ́n a lè gbàdúrà nípa kókó èyíkéyìí. Fún àpẹẹrẹ, a lè gbàdúrà nípa ìfẹ́ ọkàn wa fún ìgbéyàwó aláyọ̀. Láti lè mára dúró nínú ìwà mímọ́ títí a ó fi ṣègbéyàwó, a lè gbàdúrà fún ìkóra-ẹni-níjàánu. Ṣùgbọ́n ṣá, ẹ jẹ́ ká ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà wa nípa yíyàgò fún àwọn ìwé àti eré oníṣekúṣe. Ẹ sì tún jẹ́ ká pinnu láti ‘ṣe ìgbéyàwó kìkì nínú Olúwa.’ (1 Kọ́ríńtì 7:39; Diutarónómì 7:3, 4) Táa bá wá ṣe ìgbéyàwó ọ̀hún tán, a óò ní láti máa ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà wa fún níní ayọ̀ nípa fífi ìmọ̀ràn Ọlọ́run sílò. Báa bá sì lọ́mọ, kí á kàn máa gbàdúrà pé kí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà kò tó. A gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti fi ìtẹnumọ́ gbin òtítọ́ nípa Ọlọ́run sí wọn lọ́kan nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti nípasẹ̀ mímú wọn dání lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé.—Diutarónómì 6:5-9; 31:12; Òwe 22:6.
19. Kí ló yẹ ká máa ṣe báa bá ń gbàdúrà nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
19 A ha ń gbàdúrà fún ìbùkún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà bí? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ẹ jẹ́ ká ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú irú àdúrà bẹ́ẹ̀, nípa kíkó ipa tó ṣe gúnmọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà. Báa bá ń gbàdúrà fún àǹfààní láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti bọ́ sójú ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun, ó yẹ ká ní àkọsílẹ̀ tó kún nípa àwọn olùfìfẹ́hàn, kí a ṣe tán láti fi ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé kún ìtòlẹ́sẹẹsẹ wa. Báa bá fẹ́ wọnú iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún bí aṣáájú ọ̀nà ńkọ́? Nígbà náà, ẹ jẹ́ ká gbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà wa, nípa fífikún ìgbòkègbodò wa nínú iṣẹ́ ìwàásù àti nípa bíbá àwọn aṣáájú ọ̀nà jáde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Gbígbé irú ìgbésẹ̀ báwọ̀nyí yóò fi hàn pé a ń ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà wa.
20. Kí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn báyìí?
20 Báa bá ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà, a lè ní ìdánilójú pé yóò dáhùn àdúrà wa tó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀. (1 Jòhánù 5:14, 15) Dájúdájú, a ti rí àwọn kókó tó ṣàǹfààní jèrè láti inú ṣíṣe àgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn àdúrà tó wà nínú Bíbélì. Àpilẹ̀kọ wa tó kàn báyìí yóò gbé àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ mìíràn yẹ̀ wò, àwọn ìlànà tó wà fún àwọn tó ń fẹ́ láti ‘pèsè àdúrà wọn bí tùràrí níwájú Jèhófà.’
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Èé ṣe tó fi yẹ ká máa fi ìgbàgbọ́ gbàdúrà?
◻ Ipa wo ló yẹ kí ìyìn àti ọpẹ́ kó nínú àdúrà wa?
◻ Èé ṣe tí a lè fi tọkàntọkàn wá ìrànlọ́wọ́ Jèhófà nínú àdúrà?
◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn lájorí kókó inú àdúrà àwòṣe náà?
◻ Báwo la ṣe lè máa ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Gẹ́gẹ́ bí Ọba Jèhóṣáfátì, nígbà mìíràn ó lè di dandan ká gbàdúrà pé: ‘A kò mọ ohun tí à bá ṣe, ṣùgbọ́n ojú rẹ là ń wò o, Jèhófà’
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
O ha ń gbàdúrà ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà àwòṣe Jésù bí?