ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÉFÍTÍKÙ 16-17
Bí Ọjọ́ Ètùtù Ṣe Kàn Ẹ́
Kí la rí kọ́ látinú bí wọ́n ṣe ń sun tùràrí ní Ọjọ́ Ètùtù?
Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà àwọn olóòótọ́, torí ó dà bíi tùràrí lójú ẹ̀. (Sm 141:2) Bí àlùfáà àgbà ṣe máa ń sun tùràrí níwájú Jèhófà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀
Àlùfáà àgbà gbọ́dọ̀ sun tùràrí kó tó lè rúbọ. Bákan náà, kí Jésù tó fi ara rẹ̀ rúbọ, ó ṣe ohun tó mú kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ẹbọ rẹ̀ torí pé ó pa ìwà títọ́ mọ́, ó sì jẹ́ olóòótọ́
Kí ni màá ṣe tí mo bá fẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ohun tí mò ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀?