ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w10 8/1 ojú ìwé 27
  • “Gbé Ọmọkùnrin Rẹ”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Gbé Ọmọkùnrin Rẹ”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọmọ Ogun Jèhófà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Èlíṣà Rí Kẹ̀kẹ́ Ẹṣin Oníná—Ṣé Ìwọ Náà Rí I?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Àwọn Ọmọkùnrin Méjì Tó Jí Dìde
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
w10 8/1 ojú ìwé 27

Sún Mọ́ Ọlọ́run

“Gbé Ọmọkùnrin Rẹ”

2 ÀWỌN ỌBA 4:8-37

IKÚ ọmọ jẹ́ ọ̀kan lára àdánù tó máa ń kó ìbànújẹ́ tó pọ̀ báni. Jèhófà Ọlọ́run lágbára láti fòpin sí àdánù yìí. A mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí torí pé nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, Ọlọ́run fún àwọn ọkùnrin kan lágbára láti jí òkú dìde. Àpẹẹrẹ kan ni èyí tó wà nínú ìwé 2 Àwọn Ọba 4:8-37, tó sọ nípa bí wòlíì Èlíṣà ṣe jí ọmọdékùnrin kan dìde.

Ìlú Ṣúnémù ni nǹkan náà ti ṣẹlẹ̀. Obìnrin opó kan àti ọkọ rẹ̀ máa ń fi inúure hàn sí Èlíṣà, wọ́n máa ń fún un ní oúnjẹ àti ilé tó máa dé sí. Lọ́jọ́ kan, wòlíì tó moore yìí sọ fún obìnrin náà pé: “Ní àkókò tí a yàn kalẹ̀ yìí ní ọdún tí ń bọ̀, ìwọ yóò máa gbé ọmọkùnrin kan mọ́ra.” Ohun tí obìnrin yìí rò pé kò lè ṣẹlẹ̀ láé ṣẹlẹ̀, bí Èlíṣà ṣe sọ gan-an lọ̀rọ̀ rí, ó bí ọmọkùnrin. Ó bani nínú jẹ́ pé, ayọ̀ rẹ̀ kò tọ́jọ́. Lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn náà, ẹ̀fọ́rí tó lágbára kan ki ọmọ náà mọ́lẹ̀ nínú pápá, wọ́n sì gbé e wá sílé, ó sì kú “lórí eékún” ìyá rẹ̀. (Ẹsẹ 16, 19, 20) Ìyá tí iná ọmọ jó yìí gbé òkú ọmọ náà, ó sì tẹ́ ẹ sórí àga tí wòlíì náà sábà máa ń sùn sí.

Lẹ́yìn tí obìnrin náà fi tó ọkọ rẹ̀ létí, ó gbéra lọ sọ́dọ̀ Èlíṣà ní Òkè Ńlá Kámẹ́lì, ìyẹn sì jẹ́ ìrìn àjò nǹkan bí ọgbọ̀n kìlómítà. Nígbà tó dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, kò bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún tàbí kó máa ṣe nǹkan láti fi bí ìbànújẹ́ rẹ̀ ti pọ̀ tó hàn. Àbí nítorí pé ó gbọ́ pé Èlíjà tí Èlíṣà gba iṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ ti jí ọmọ opó kan dìde rí ló mú kó má sunkún ni? (1 Àwọn Ọba 17:17-23) Àbí ó lè jẹ́ pé obìnrin ará Ṣúnémù náà ní ìgbàgbọ́ pé Èlíṣà bákan náà lè jí ọmọ òun dìde ni kò jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún ni? Ohun yòówù kó jẹ́, obìnrin yìí kọ̀ láti lọ sí ilé títí Èlíṣà fi gbà láti bá a lọ.

Nígbà tí wọ́n dé Ṣúnémù, Èlíṣà nìkan ló wọnú yàrà tó máa ń dé sí, ó sì rí òkú ọmọ náà tí wọ́n tẹ́ “sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú rẹ̀.” (Ẹsẹ 32) Àdúrà ẹ̀bẹ̀ àtọkànwá ni wòlíì yìí gbà sí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, bí Èlíṣà ti di ọwọ́ ọmọdékùnrin náà mú, ní ‘kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ara ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí í móoru.’ Bí ọkàn ọmọ náà tó ti dúró tẹ́lẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ nìyẹn! Èlíṣà wá pe ìyá ọmọ náà, ó sì sọ ọ̀rọ̀ tó sọ ìbànújẹ́ rẹ̀ dayọ̀ fún un pé: “Gbé ọmọkùnrin rẹ.”—Ẹsẹ 34, 36.

Ìtùnú ni àkọsílẹ̀ nípa àjíǹde ọmọkùnrin obìnrin ará Ṣúnémù yìí jẹ́, ó sì tún jẹ́ ká ní ìrètí. Jèhófà mọ bí ìbànújẹ́ àwọn òbí tí ọmọ wọn kú ṣe pọ̀ tó. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé, Jèhófà ń fẹ́ láti fòpin sí irú àdánù yìí. (Jóòbù 14:14, 15) Àjíǹde nípasẹ̀ Èlíṣà àtàwọn míì nínú Bíbélì jẹ́ àpẹẹrẹ kékeré lẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun tó pabanbarì tí Jèhófà máa ṣe nínú ayé tuntun òdodo tó ń bọ̀.a

Àmọ́ ṣá o, ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa àjíǹde kò mú ìbànújẹ́ ẹni kúrò pátápátá nígbà téèyàn ẹni bá kú. Ọkùnrin kan tó jẹ́ Kristẹni tó ń fi òótọ́ inú sin Ọlọ́run tí ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo tó bí kú sọ pé: “Ìbànújẹ́ mi kò lè lọ tán pátápátá títí dìgbà tí màá fi gbá ọmọ mi mọ́ra lẹ́ẹ̀kan sí i.” Fojú inú wo àkókò tó o máa tún wà pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n ti kú. Mímọ̀ tó o mọ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ tó o tún lè gbá wọn mọ́ra lè fún ẹ lókun láti fara da ìbànújẹ́ náà. Ǹjẹ́ kò wù ẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ọlọ́run tó fún wa ní ìrètí amọ́kànyọ̀ yìí?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa àjíǹde, ka orí 7 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́