Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
October 15, 2010
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ Ọ̀SẸ̀:
November 29, 2010–December 5, 2010
“Ta Ni Ó Ti Wá Mọ Èrò Inú Jèhófà?”
OJÚ ÌWÉ 3
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 69, 51
December 6-12, 2010
Ẹ Máa Wá “Òdodo Rẹ̀” Lákọ̀ọ́kọ́
OJÚ ÌWÉ 7
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 40, 22
December 13-19, 2010
Ǹjẹ́ O Máa Ń Mú Ipò Iwájú Nínú Bíbọlá fún Àwọn Tá A Jọ Jẹ́ Onígbàgbọ́?
OJÚ ÌWÉ 16
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 122, 104
December 20-26, 2010
Ṣé O Máa Ń Mú Kí Àwọn Ìpàdé Ìjọ Gbéni Ró?
OJÚ ÌWÉ 20
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 20, 64
Ohun Táwọn Àpilẹ̀kọ Tá A Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dá Lé
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1 àti 2 OJÚ ÌWÉ 3 sí 11
Àwọn àpilẹ̀kọ yìí jíròrò bá a ṣe lè sapá láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn ìgbòkègbodò Jésù. Wọ́n tún ṣàlàyé ohun tí òdodo Ọlọ́run wé mọ́, ìdí tá a fi ní láti wá a lákọ̀ọ́kọ́ àti ìdí tí a kò fi gbọ́dọ̀ máa fi ìlànà èèyàn dá Jèhófà lẹ́jọ́.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3 OJÚ ÌWÉ 16 sí 20
Báwo la ṣe lè máa bọlá fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́? Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa bọlá fún wọn? Báwo la ṣe lè máa mú ipò iwájú nínú bíbọlá fúnni? Díẹ̀ nìyí lára àwọn ìbéèrè tá a gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4 OJÚ ÌWÉ 20 sí 25
Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò bí àwọn tó ń darí àwọn ìpàdé ìjọ àti àwùjọ ṣe lè mú kí àwọn ìpàdé wa máa gbé àwọn tó ń wá síbẹ̀ ró. Ó tún jíròrò àwọn àtúnṣe tá a ti ṣe sí ìwé ìròyìn yìí.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ:
Ojú Wo Ni Jèhófà Fi Ń Wo Àwíjàre? 12
Ẹ Ran Àwọn Ọ̀dọ́ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Mọ Ètò Jèhófà Dunjú 25
Mo Mú Kí Ọwọ́ Mi Dí Nínú Ètò Jèhófà 29
“Ó Ń Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Mi Wọ Àwọn Èèyàn Lọ́kàn” 32