ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w10 12/1 ojú ìwé 3
  • Àwọn Wo Ló Ń Gbé ní Ọ̀run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Wo Ló Ń Gbé ní Ọ̀run?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Wo Ló Ń Gbé ní Ibùgbé Àwọn Ẹni Ẹ̀mí?
    Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
  • Ìran Nípa Ọ̀run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ṣé Èèyàn Máa Ń Wà Láàyè Lẹ́yìn Ikú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Àwọn Wo Ní Ń Gbé Ilẹ̀ Ọba Ẹ̀mí?
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
w10 12/1 ojú ìwé 3

Àwọn Wo Ló Ń Gbé ní Ọ̀run?

Obìnrin àgbàlagbà kan ní ilẹ̀ Yúróòpù wọ inú ṣọ́ọ̀ṣì kan, ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà wà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì kúnlẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ níwájú ère Màríà. Nílẹ̀ Áfíríkà, ìdílé kan ta ọtí sílẹ̀ lẹ́bàá sàréè ẹbí wọn kan tó jẹ́ ẹni iyì. Nílẹ̀ àwọn Amẹ́ríkà, ọ̀dọ́kùnrin kan gbààwẹ̀, ó sì ń ṣàṣàrò, ó fẹ́ bá áńgẹ́lì tó gbà pé ó ń dáàbò bo òun sọ̀rọ̀. Nílẹ̀ Éṣíà, àlùfáà kan sun àwọn bébà aláràbarà láti fi júbà àwọn alálẹ̀, ìyẹn àwọn èèyàn wọn tó ti kú tipẹ́.

KÍ LÓ mú kí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn yìí jọra? Gbogbo wọn gbà gbọ́ pé àwọn kan tó jẹ́ olóye wà ní ọ̀run, àwọn tá a lè bá sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì lágbára láti máa darí ìgbésí ayé èèyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí kì í ṣe èrò tuntun, tí kò sì yani lẹ́nu, àmọ́ ohun tó yani lẹ́nu gan-an ni pé, oríṣiríṣi èrò ni àwọn èèyàn ní nípa àwọn tó ń gbé ní ọ̀run.

Ọlọ́run kan ṣoṣo, ìyẹn Allaha ni àwọn Mùsùlùmí ń jọ́sìn. Àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì sọ pé Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan, ìyẹn Ọlọ́run Baba, Ọlọ́run Ọmọ àti Ọlọ́run Ẹ̀mí Mímọ́. Àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ọlọ́run àtàwọn abo ọlọ́run tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan. Àwọn kan sọ pé, àwọn ẹ̀mí kan ń gbé inú oríṣi àwọn ẹranko kan, àwọn igi kan, àpáta kan àtàwọn odò kan. Wọ́n sì ti ṣi àwọn míì lọ́nà nípasẹ̀ àwọn ìwé, sinimá àtàwọn eré orí tẹlifíṣọ̀n tó dá lórí àwọn áńgẹ́lì àtàwọn ẹ̀mí èṣù, àwọn iwin àtàwọn ọlọ́run àti abo ọlọ́run.

Bó ti jẹ́ pé oríṣiríṣi èrò ni àwọn èèyàn ní nípa àwọn ọlọ́run àtàwọn ọlọ́run àjúbàfún, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe ní oríṣiríṣi èrò nípa bó ṣe yẹ kéèyàn bá wọn sọ̀rọ̀. Ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé kì í ṣe gbogbo ọ̀nà tí wọ́n sọ pé èèyàn lè gbà bá wọn sọ̀rọ̀ yìí ló tọ̀nà. Rò ó wò ná: Ká tó fi fóònù pe ẹnì kan, a ní láti mọ ẹni náà, ó sì gbọ́dọ̀ dá wa lójú pé ẹni náà wà láàyè àti pé, ó máa dá wa lóhùn. Kò ní bọ́gbọ́n mu kéèyàn máa gbìyànjú láti bá ẹnì kan téèyàn rò pé ó wà àmọ́ tí kò sí sọ̀rọ̀. Èyí tó wá burú jù ni pé kéèyàn máa bá afàwọ̀rajà sọ̀rọ̀.

Nítorí náà, àwọn wo ló ń gbé ní ọ̀run? Yàtọ̀ sí pé Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí, ó tún ṣàlàyé ẹni tá a lè bá sọ̀rọ̀ àti irú ìdáhùn tá a lè rí gbà. Máa kàwé yìí nìṣó. Wàá rí i pé ohun tí Bíbélì sọ máa yà ẹ́ lẹ́nu.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Allah” túmọ̀ sí “Ọlọ́run,” kò ní ìtumọ̀ míì.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́