Àwọn Wo Ní Ń Gbé Ilẹ̀ Ọba Ẹ̀mí?
AYÉ ti di “ilé ìtajà ńlá” fún àwọn èrò ìgbàgbọ́ àti ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́. Ní Áfíríkà nìkan, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹgbẹ́ onísìn ló wà, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n ní àwọn èrò tirẹ̀ nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ ọba ẹ̀mí. Àmọ́ fún ìsọfúnni kedere, tí ó sì jẹ́ òtítọ́, a ní láti gbé Bíbélì yẹ̀ wò. Ó tọ́ka sí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí—rere àti búburú—tí ń gbé ilẹ̀ ọba ẹ̀mí. Ó tún fi ẹni tí a lè ké sí fún ìrànlọ́wọ́ àti ààbò, tí yóò sì ní àbájáde rere hàn.
Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè
Ìsìn ìbílẹ̀ ní Áfíríkà ń fi kọ́ni pé ẹni tí ń ṣàkóso àwọn baba ńlá àti àwọn irúnmọlẹ̀ ni Ọlọ́run alágbára gbogbo kan. Ìwé African Mythology sọ pé: “Kò sí àní-àní pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn ará Áfíríkà, bí kì í bá ṣe gbogbo wọn, ló gbàgbọ́ nínú Ẹni Gíga Jù Lọ kan, ẹlẹ́dàá ohun gbogbo.” Ìwé African Religion in African Scholarship sọ pé: “Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti jẹ́ olùṣàkóso pátápátá lórí àgbáyé, gbogbo àwọn ẹ̀dá àti gbogbo agbára jẹ́ àbáyọrí wíwà Rẹ̀. Àṣẹ àti agbára pátápátá wà lọ́wọ́ Rẹ̀.”
Bíbélì fohùn ṣọ̀kan pé Ẹnì kan wà tí ó wà ní ipò gíga jù lọ ní ilẹ̀ ọba ẹ̀mí. Ó ṣàpèjúwe rẹ̀ bí “Ọlọ́run àwọn ọlọ́run . . . àti Olúwa àwọn olúwa, Ọlọ́run títóbi, alágbára, àti ẹlẹ́rù, tí kì í ṣe ojúsàájú, bẹ́ẹ̀ ni kì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”—Diutarónómì 10:17.
Jákèjádò Áfíríkà, ọgọ́rọ̀ọ̀rún orúkọ àti orúkọ oyè ni wọ́n fún ẹni tí wọ́n kà sí ẹni gíga jù lọ náà. Síbẹ̀, kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa orúkọ àtọ̀runwá náà? Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Ìwọ, orúkọ ẹnì kan ṣoṣo tí í jẹ́ Jèhófà, ìwọ ni Ọ̀gá Ògo lórí ayé gbogbo.” (Orin Dáfídì 83:18) Ó lé ní 7,000 ìgbà tí orúkọ mímọ́ ọlọ́wọ̀ yìí fara hàn nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn atúmọ̀ Bíbélì mélòó kan ti fi àwọn orúkọ oyè bí “Ọlọ́run” tàbí “Olúwa” rọ́pò rẹ̀.
Nítorí pé ní ti agbára, Jèhófà jẹ́ alágbára gbogbo, ó lè ràn wá lọ́wọ́. Ó ṣàpèjúwe ara rẹ̀ bí “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, onípamọ́ra, àti ẹni tí ó pọ̀ ní oore àti òtítọ́; ẹni tí ó ń pa àánú mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tí ó ń dárí àìṣe déédéé, àti ìrékọjá, àti ẹ̀ṣẹ̀ jì, àti ní tòótọ́, tí kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà.”—Ẹ́kísódù 34:6, 7; Sámúẹ́lì Kìíní 2:6, 7.
Àwọn Áńgẹ́lì, Àwọn Òjíṣẹ́ Alágbára Ti Ọlọ́run
Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí Jèhófà tó dá àwọn ẹ̀dá ènìyàn tàbí ilẹ̀ ayé fúnra rẹ̀ pàápàá, ó ti dá àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí sí ọ̀run. Bíbélì sọ pé ní àkókò tí Ọlọ́run “fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ . . . , gbogbo àwọn [áńgẹ́lì] ọmọ Ọlọ́run ń hó ìhó ayọ̀.” (Jóòbù 38:4-7) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn áńgẹ́lì ló wà. Dáníẹ́lì, ìránṣẹ́ Jèhófà, kọ̀wé ìran kan nípa àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run, nínú èyí tí ó rí tí “àwọn ẹgbẹ̀rún gbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún [Ọlọ́run], àti àwọn ẹgbẹẹgbàárùn-ún nígbà ẹgbàárùn-ún dúró níwájú rẹ̀.”—Dáníẹ́lì 7:10.
Ẹ̀dá ẹ̀mí àkọ́kọ́ tí Jèhófà dá ni ẹni tí a wá mọ̀ sí Jésù Kristi. (Jòhánù 17:5; Kólósè 1:15) Kí ó tó wá gbé orí ilẹ̀ ayé bí ènìyàn, Jésù ti gbé ní ọ̀run bí ẹ̀dá ẹ̀mí. Lẹ́yìn ikú rẹ̀ bí ènìyàn, a jí Jésù dìde sí ọ̀run, níbi tí ó tún padà lọ gbé ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára kan.—Ìṣe 2:32, 33.
Jésù ní agbára ńlá ní ọ̀run. Nínú Júdà 9, Jésù, tí a tún mọ̀ sí Máíkẹ́lì, ni a pè ní “olú áńgẹ́lì,” tí ó túmọ̀ sí pé òun ni ọ̀gá, tàbí olórí, áńgẹ́lì. (Tẹsalóníkà Kìíní 4:16) Ó tún ní àṣẹ lórí ilẹ̀ ayé. Jèhófà ti fún un ní “agbára ìjọba àti ògo, àti ìjọba, kí gbogbo ènìyàn, àti orílẹ̀, àti èdè, kí ó lè máa sìn ín.” (Dáníẹ́lì 7:13, 14) Láìka ọlá àṣẹ ńlá tí ó ní sí, Jésù wà ní abẹ́ Bàbá rẹ̀, Jèhófà.—Kọ́ríńtì Kìíní 11:3.
Bí àwọn áńgẹ́lì olùṣòtítọ́ ti ń ṣe ìránṣẹ́ fún Jèhófà ni wọ́n tún ń ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn olùjọsìn Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo [àwọn áńgẹ́lì] kì í ha ṣe ẹ̀mí fún iṣẹ́ ìsìn gbogbo ènìyàn, tí a rán jáde láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn wọnnì tí yóò jogún ìgbàlà?” (Hébérù 1:14) Ó jẹ wọ́n lógún ní pàtàkì láti rí i pé àwọn ènìyàn kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jèhófà. Nínú ìran kan, àpọ́sítélì Jòhánù rí “áńgẹ́lì . . . tí ń fò ní agbede méjì ọ̀run, ó sì ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bí àwọn làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn wọnnì tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn, ó ń wí ní ohùn rara pé: ‘Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run kí ẹ sì fi ògo fún un.’”—Ìṣípayá 14:6, 7.
Sátánì àti Àwọn Ẹ̀mí Èṣù, Ọ̀tá Ọlọ́run àti Ti Ènìyàn
Ó bani nínú jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo àwọn áńgẹ́lì ni wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ sí Ọlọ́run. Àwọn kan ṣọ̀tẹ̀ sí i, wọ́n sì di ọ̀tá Ọlọ́run àti ti aráyé. Olórí àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà ni Sátánì Èṣù.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí ló ń sọ pé kò sí Sátánì, kò sí ẹni tí ó sọ pé kò sí ibi. Ìwé The Death of Satan sọ pé, gbígbàgbọ́ nínú ibi, láìgbàgbọ́ pé ohun kan ní ń fà á, ń sinni sí “ìṣòro aláìṣeéyèbọ́. A ń nímọ̀lára ohun kan tí àṣà ìbílẹ̀ wa kò jẹ́ kí a tún ní ọ̀rọ̀ èdè láti fi pè é ní ohun tí ń jẹ́ mọ́.”
Ní ìyàtọ̀, Bíbélì ní ọ̀rọ̀ èdè, ó sì sọ òtítọ́ jáde ní kedere nípa orísun ibi. Ó ṣàlàyé pé gbogbo àwọn áńgẹ́lì tí Jèhófà dá ni wọ́n jẹ́ olódodo, wọ́n sì dára; kò dá áńgẹ́lì búburú kankan. (Diutarónómì 32:4; Orin Dáfídì 5:4) Síbẹ̀, a fún àwọn áńgẹ́lì ní agbára láti yàn láàárín ohun tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́, bí a ṣe fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn. Ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin ẹ̀mí pípé yìí mú ìfẹ́ ọkàn onímọtara-ẹni-nìkan dàgbà láti fipá gba ìjọsìn tí ó tọ́ sí Jèhófà fún ara rẹ̀. Ó tipa bẹ́ẹ̀ gba orúkọ náà, Sátánì, tí ó túmọ̀ sí “Alátakò.” (Fi wé Jákọ́bù 1:14, 15.) Sátánì kì í ṣe atannijẹ lásán, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìsìn kan ní Áfíríkà ṣe fi kọ́ni; bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe “ẹ̀ṣọ́” tí ń dáàbò bo àwọn tí ń rúbọ sí i déédéé. Bíbélì fi í hàn bí olubi àti abèṣe gbáà.
Àwọn áńgẹ́lì míràn dara pọ̀ mọ́ Sátánì nínú ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Àwọn áńgẹ́lì ẹ̀mí èṣù wọ̀nyí tún jẹ́ ọ̀tá àwọn ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn pẹ̀lú jẹ́ aláránkan àti olubi. Ní àwọn ìgbà tí ó ti kọjá, wọ́n ya àwọn ènìyàn kan lódi, wọ́n sì fọ́ wọn lójú. (Mátíù 9:32, 33; 12:22) Wọ́n fi àìsàn tàbí àrùn ọpọlọ pọ́n àwọn mìíràn lójú, títí kan àwọn ọmọdé. (Mátíù 17:15, 18; Máàkù 5:2-5) Ní kedere, kò sí ẹ̀dá kan tí orí rẹ̀ pé tí yóò fẹ́ láti ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú Sátánì tàbí àwọn ẹ̀mí èṣù.
Ibo Ni Àwọn Baba Ńlá Wà?
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ní Áfíríkà àti ní àwọn ibòmíràn gbà gbọ́ pé ikú kì í ṣe òpin ìwàláàyè, ṣùgbọ́n pé ó wulẹ̀ jẹ́ ìyípadà kan lásán, sísọdá sínú ìwàláàyè ní ilẹ̀ ọba ẹ̀mí, ilẹ̀ àkóso àwọn irúnmọlẹ̀ àti àwọn baba ńlá. Ọ̀mọ̀wé John Mbiti, ògbógi nípa àwọn ìsìn Áfíríkà, kọ̀wé nípa èrò ìgbàgbọ́ nínú àwọn baba ńlá, tí ó pè ní “àkúdàáyà,” pé: “Àwọn wọ̀nyí ni ‘àwọn ẹ̀mí’ tí àwọn ènìyàn Áfíríkà ń ṣàníyàn nípa wọn jù lọ . . . Wọ́n mọ ohun tí ń lọ nínú ìdílé [lórí ilẹ̀ ayé], wọ́n sì lọ́kàn ìfẹ́ nínú rẹ̀. . . . Àwọn ni olùdáàbòbò àwọn àlámọ̀rí, àṣà, ìlànà ìwà híhù àti àwọn ìgbòkègbodò ìdílé. Ṣíṣẹ̀ sí àwọn ìlànà yìí jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ pátápátá sí àwọn baba ńlá, àwọn ẹni tí, wíwà tí wọ́n wà ní ipò yẹn, mú kí wọ́n jẹ́ ọlọ́pàá àìrí fún àwọn ìdílé àti àwùjọ. Nítorí pé wọ́n ṣì jẹ́ ‘ènìyàn’, àwọn àkúdàáyà wá tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ àwùjọ àwọn alárinnà dídára jù lọ láàárín àwọn ènìyàn àti Ọlọ́run: wọ́n mọ àwọn àìní àwọn ènìyàn, wọ́n ti wà níhìn-ín ‘láìpẹ́’ pẹ̀lú àwọn ènìyàn, lákòókò kan náà, àwọn ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ṣí sílẹ̀ gbayawu fún wọn.”
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kí ni Bíbélì sọ nípa ipò tí àwọn òkú wà? Ó fi hàn pé kò sí nǹkan tí a ń pè ní “àkúdàáyà.” Àwọn ènìyàn lè jẹ́ alààyè tàbí òkú—wọn kò lè jẹ́ méjèèjì lẹ́ẹ̀kan náà láé. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ni pé àwọn òkú kò lè gbọ́rọ̀, ríran, sọ̀rọ̀, tàbí ronú. Àwọn òkú kò sí ní ipò àtiṣe ọlọ́pàá àwọn alààyè. Bíbélì wí pé: “Àwọn òkú kò mọ ohun kan . . . Ìfẹ́ wọn pẹ̀lú, àti ìríra wọn, àti ìlara wọn, ó parun nísinsìnyí; . . . kò sí ète, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀, tàbí ọgbọ́n, ní isà òkú níbi tí ìwọ́ ń rè.” (Oníwàásù 9:5, 6, 10) “[Ènìyàn] padà sí erùpẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ náà gan-an, èrò inú rẹ̀ run.”—Orin Dáfídì 146:4.
Pípadà sí Erùpẹ̀
Bí èyí bá ṣòro fún ọ láti gbà, gbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin àkọ́kọ́ náà, Ádámù, yẹ̀ wò. Jèhófà “fi erùpẹ̀ ilẹ̀” mọ Ádámù. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Nígbà tí Ádámù ṣàìgbọ́ràn sí àṣẹ Jèhófà, ikú ni ìjìyà rẹ̀. Ọlọ́run wí fún un pé: “Ìwọ óò . . . padà sí ilẹ̀; nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá, erùpẹ̀ sá ni ìwọ, ìwọ óò sì padà di erùpẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:19.
Ṣáájú kí Jèhófà tó fi erùpẹ̀ ṣẹ̀dá Ádámù, Ádámù kò sí ní ibikíbi. Nítorí náà, nígbà tí ó “padà sí ilẹ̀,” ó tún di aláìlẹ́mìí bí erùpẹ̀, lẹ́ẹ̀kan sí i. Kò sọdá sí ilẹ̀ ọba ẹ̀mí àwọn baba ńlá. Kò lọ sí ọ̀run tàbí ọ̀run àpáàdì. Nígbà tí ó kú, gbogbo rẹ̀ wá sópin.
Ǹjẹ́ ohun kan náà máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn míràn tí wọ́n bá kú bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn. Bíbélì wí pé: “Níbì kan náà ni gbogbo wọn [àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko] ń lọ; láti inú erùpẹ̀ wá ni gbogbo wọn, gbogbo wọ́n sì tún padà di erùpẹ̀.” (Oníwàásù 3:20) Bíbélì ṣèlérí pé Ọlọ́run yóò jí àwọn ènìyàn tí wọ́n kú dìde sí ìyè nínú párádísè ilẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n àkókò yẹn ṣì wà lọ́jọ́ iwájú. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Ní báyìí ná, kò yẹ kí a máa bẹ̀rù àwọn òkú tàbí kí a máa rúbọ sí wọn, níwọ̀n bí wọn kò ti lè ràn wá lọ́wọ́, tí wọn kò sì lè pa wá lára.
Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń fẹ́ láti ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà nípa ipò tí àwọn baba ńlá wọn tí wọ́n ti kú wà, nítorí náà, wọ́n ń ṣonígbọ̀wọ́ irọ́ náà pé àwọn ènìyàn ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn ikú. Ọ̀nà kan tí wọ́n ń gbà ṣe èyí jẹ́ nípa àwọn ìtàn irọ́. (Tímótì Kìíní 4:1) Wọ́n tún máa ń lo àwọn ìran, àlá, àti àwọn abẹ́mìílò, láti tan àwọn ènìyàn jẹ láti ronú pé àwọ́n ti bá òkú sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n àwọn òkú kọ́ ni wọ́n kàn sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ẹ̀mí èṣù tí wọ́n ń díbọ́n bí àwọn tí ó ti kú ni. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi dẹ́bi gidigidi fún àwọn tí ń tọ òkú lọ, yálà ní tààràtà tàbí láìṣe tààràtà, ní àwọn ọ̀nà míràn, bí iṣẹ́ wíwò.—Diutarónómì 18:10-12.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn ẹ̀mí èṣù tún ń lo àwọn ìran, àlá, àti àwọn abẹ́mìílò láti tan àwọn ènìyàn jẹ, àti láti dẹ́rù bà wọ́n
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Láti ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà, àwọn ẹ̀mí èṣù ń díbọ́n bí àwọn tí ó ti kú