Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
January 15, 2011
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ Ọ̀SẸ̀:
February 28, 2011–March 6, 2011
OJÚ ÌWÉ 3
March 7-13, 2011
Bọ̀wọ̀ fún Ìgbéyàwó Tó Jẹ́ Ẹ̀bùn Ọlọ́run
OJÚ ÌWÉ 13
March 14-20, 2011
Lo Ẹ̀bùn Wíwà Láìní Ọkọ Tàbí Aya Lọ́nà Tó Dára Jù Lọ
OJÚ ÌWÉ 17
March 21-27, 2011
Ẹ̀mí Mímọ́ Ń Fún Wa Lágbára Ká Lè Kojú Ìdẹwò Ká sì Borí Ìrẹ̀wẹ̀sì
OJÚ ÌWÉ 22
March 28, 2011–April 3, 2011
Ẹ̀mí Mímọ́ Ń Fún Wa Lágbára Ká Lè Borí Àdánwò Èyíkéyìí
OJÚ ÌWÉ 26
Ohun Táwọn Àpilẹ̀kọ Tá A Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dá Lé
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1 OJÚ ÌWÉ 3 sí 7
Ibo la ti lè rí ààbò ní àkókò lílekoko tá à ń gbé yìí? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàlàyé pé a lè fi orúkọ Jèhófà ṣe ibi ìsádi wa. Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò bí a ṣe lè rí ààbò nísinsìnyí àti ní ìgbà tí “ọjọ́ ńlá Jèhófà” bá dé. Àpilẹ̀kọ náà dá lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2011.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2 àti 3 OJÚ ÌWÉ 13 sí 21
Ìgbéyàwó àti wíwà láìṣègbéyàwó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní àǹfààní tirẹ̀. Yálà a ti ṣègbéyàwó tàbí a kò tíì ṣègbéyàwó, ohun tá a jíròrò nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí á jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká mọyì àwọn ẹ̀bùn méjèèjì náà, ó sì máa ṣàlàyé ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a mọyì wọn fún wa.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4 àti 5 OJÚ ÌWÉ 22 sí 30
Ká bàa lè mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ, a nílò ìrànlọ́wọ́ Jèhófà. Nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí, a jíròrò bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè kojú ìdẹwò, ká borí ìrẹ̀wẹ̀sì, ká fara da inúnibíni, ká dènà ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe, ká sì fara da ìpọ́njú.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ:
7 A Rí Orúkọ Ọlọ́run Níbi Àfonífojì
9 Mo Dúpẹ́ Pé Àdánwò Kò Mú Kí N Dẹ́kun Láti Máa Sin Jèhófà
31 Máa Ṣe Àṣàrò Lórí Ohun tí Jèhófà Ti Ṣe fún Ẹ
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
© Stähli Rolf A/age fotostock