Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ta ni Ọlọ́run?
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a béèrè àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa ṣe kàyéfì nípa wọn, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí ohun tí àwọn ìdáhùn náà jẹ́.
1. Ta ni Ọlọ́run?
Ọlọ́run tòótọ́ ló dá ohun gbogbo. Bíbélì pè é ní “Ọba ayérayé,” tó túmọ̀ sí pé kò ní ìbẹ̀rẹ̀, kò sì ní ní òpin láé. (Ìṣípayá 15:3) Nítorí pé Ọlọ́run ni Orísun ìwàláàyè, òun nìkan ṣoṣo la ní láti máa jọ́sìn.—Ka Ìṣípayá 4:11.
2. Báwo ni Ọlọ́run ṣe rí?
Kò sí ẹni tó rí Ọlọ́run rí nítorí pé ẹ̀mí ni, ìyẹn ni pé irú ẹni to jẹ́ ju ti àwọn ẹ̀dá tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé lọ fíìfíì. (Jòhánù 1:18; 4:24) A mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ nínú àwọn ohun tó dá. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá wo àwọn iṣẹ́ ọnà tí Ọlọ́run ṣe, oríṣiríṣi èso àti òdòdó tó dá, a rí ìfẹ́ àti ọgbọ́n Ọlọ́run nínú wọn. Bí ayé àti ọ̀run ṣe lọ salalu jẹ́ ká mọ bí agbára Ọlọ́run ti pọ̀ tó.—Ka Róòmù 1:20.
A lè túbọ̀ mọ̀ nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fún wa nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ àti ohun tí kò fẹ́, nípa bó ṣe ń ṣe sí àwọn èèyàn àti bó ṣe ń ṣe nígbà tí àwọn nǹkan bá ṣẹlẹ̀.—Ka Sáàmù 103:7-10.
3. Ǹjẹ́ Ọlọ́run ní orúkọ?
Jésù sọ pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ní àwọn orúkọ oyè tó pọ̀, orúkọ kan ṣoṣo ló ní. Ní èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ọ̀nà tó yàtọ̀ là ń gbà pe orúkọ yìí. Ní èdè Yorùbá, a máa ń pè é ní “Jèhófà.”—Ka Sáàmù 83:18.
Wọ́n ti yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì, wọ́n sì ti fi orúkọ oyè náà, Olúwa tàbí Ọlọ́run rọ́pò rẹ̀. Àmọ́ nígbà tí wọ́n kọ Bíbélì, nǹkan bí ìgbà ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ni orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú rẹ̀. Jésù sọ orúkọ Ọlọ́run fún àwọn èèyàn nígbà tó lò ó láti fi ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn. Ó ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run.—Ka Jòhánù 17:26.
4. Ǹjẹ́ Jèhófà bìkítà nípa wa?
Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ní ti pé òun fúnra rẹ̀ ló ń tẹ́tí gbọ́ àdúrà wa. (Sáàmù 65:2) Ǹjẹ́ ìyà rẹpẹtẹ tó wà láyé yìí túmọ̀ sí pé Ọlọ́run kò bìkítà nípa wa? Àwọn èèyàn kan sọ pé Ọlọ́run ń jẹ́ kí ìyà jẹ wá kó lè dán wa wò, àmọ́ èyí kì í ṣòótọ́. Bíbélì sọ pé: “Kí a má rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ yóò hùwà burúkú.”—Jóòbù 34:10; ka Jákọ́bù 1:13.
Ọlọ́run ti fún èèyàn ní òmìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n. Ǹjẹ́ a mọyì òmìnira tí Ọlọ́run fún wa láti yàn bóyá á fẹ́ wù ú tàbí a kò fẹ́ wù ú? (Jóṣúà 24:15) Ìyà pọ̀ gan-an nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń dìídì hùwà ibi sí àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn. Inú Jèhófà kò dùn sí irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 6.
Láìpẹ́, Jèhófà máa lo Jésù láti mú ìyà kúrò pátápátá àti àwọn tó ń fà á. Àmọ́, ṣáájú ìgbà yẹn, ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ wà tí Jèhófà fi ní láti fàyè gba ìjìyà fún ìgbà díẹ̀, bí ìgbà tí bàbá onífẹ̀ẹ́ kan bá fún àwọn dókítà láyè láti tọ́jú ọmọ rẹ̀. Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí ṣì máa ṣàlàyé ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà.—Ka Aísáyà 11:4.
5. Kí ni Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe?
Jèhófà dá wa lọ́nà tá a fi lè mọ̀ ọ́n, tí a ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó fẹ́ ká mọ òtítọ́ nípa òun. (1 Tímótì 2:4) Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a ó mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa.—Ka Òwe 2:4, 5.
A ní láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ju bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ ẹnikẹ́ni mìíràn lọ, nítorí pé òun ló fún wa ní ìwàláàyè. A lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tá a bá ń bá a sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àdúrà, tá a sì ń ṣe ohun tó fẹ́. (Òwe 15:8) Jèhófà sọ pé ká máa fìfẹ́ hùwà sí àwọn èèyàn.—Ka Máàkù 12:29, 30; 1 Jòhánù 5:3.
Fún àlàyé síwájú sí i, ka orí 1 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ǹjẹ́ ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ wà tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà fún ìgbà díẹ̀?