Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
February 15, 2011
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ Ọ̀SẸ̀:
April 4-10, 2011
Ẹ̀mí Mímọ́ Ni Ọlọ́run Lò Nígbà Ìṣẹ̀dá
OJÚ ÌWÉ 6
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 110, 112
April 11-17, 2011
Rírí Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run Ló Máa Mú Ká Jogún Ìyè Àìnípẹ̀kun
OJÚ ÌWÉ 13
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 106, 51
April 18-24, 2011
Fi Gbogbo Ọkàn Rẹ Nífẹ̀ẹ́ Òdodo
OJÚ ÌWÉ 24
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 22, 40
April 25, 2011–May 1, 2011
OJÚ ÌWÉ 28
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 61, 120
Ohun Táwọn Àpilẹ̀kọ Tá A Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dá Lé
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1 OJÚ ÌWÉ 6 sí 10
Àwọn ohun tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí máa mú ká ní òye tó jinlẹ̀ sí i nípa bí Ọlọ́run ṣe lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé. Àpilẹ̀kọ náà tún máa mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wa, jẹ́ ọlọgbọ́n àti alágbára.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2 OJÚ ÌWÉ 13 sí 17
Ohun tó jẹ ọ̀pọ̀ èèyàn lógún jù lọ ni bí wọ́n ṣe máa kó ohun ìní tara jọ. Àmọ́, Bíbélì fi hàn pé bá a ṣe máa rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run ló yẹ kó jẹ wá lógún jù lọ. Àpilẹ̀kọ yìí tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì jẹ́ ká mọ àwọn ohun tá a lè ṣe táá mú kó dá wa lójú pé a máa rí ojú rere rẹ̀.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3 àti 4 OJÚ ÌWÉ 24 sí 32
‘Jésù nífẹ̀ẹ́ òdodo, ó sì kórìíra ìwà àìlófin.’ (Héb. 1:9) Àwọn àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Wọ́n ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ òdodo, ká sì kórìíra ìwà àìlófin.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
3 Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Máa Bọ̀wọ̀ Fúnni
11 Ìsapá Náà Tó Bẹ́ẹ̀ Ó Jù Bẹ́ẹ̀ Lọ!
12 Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
18 Ṣé O Mọyì Àwọn Ìbùkún Tó O Ní Lóòótọ́?