ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 3/1 ojú ìwé 30-31
  • Gbèjà Ìjọsìn Tòótọ́!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbèjà Ìjọsìn Tòótọ́!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọ́run Kórìíra Ìwà Ìrẹ́jẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Bí Sódómù àti Gòmórà Ṣe Pa Run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Jésù Fi Iṣẹ́ Ìyanu Mú Àwọn Aláìsàn Lára Dá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Mósè Gba Iṣẹ́ Pàtàkì Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 3/1 ojú ìwé 30-31

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Gbèjà Ìjọsìn Tòótọ́!

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sí ariwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn: Èlíjà, Áhábù àti nǹkan bí àádọ́ta lé nírínwó [450] àwọn wòlíì Báálì

Àkópọ̀: Èlíjà fi hàn pé Jèhófà lágbára ju Báálì lọ.

1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA 1 ÀWỌN ỌBA 18:17-40.

Mú abala ìwé kan, kó o sì ya àwòrán ibi tó o rò pé àwọn èèyàn àtàwọn nǹkan yìí wà síra wọn, ìyẹn ibi tí Èlíjà wà, ibi táwọn wòlíì Báálì wà àti ibi tí àwọn pẹpẹ náà wà.

Ìró wo lò ń “gbọ́” nígbà tí yánpọnyánrin tá a ṣàpèjúwe ní ẹsẹ 26 sí 29 ṣẹlẹ̀?

․․․․․

Kí lo kíyè sí nínú ohùn Èlíjà nígbà tó ń bá àwọn wòlíì Báálì sọ̀rọ̀?

․․․․․

2 ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Kí nìdí tí Èlíjà fi nílò ìgboyà láti bá Áhábù sọ̀rọ̀ àti láti lọ ṣe ìdánwò kan tó máa dójú ti ọgọ́rùn-ún mélòó kan àwọn wòlíì Báálì? (Ojútùú: Ka 1 Àwọn Ọba 18:4, 13, 14.)

․․․․․

Lo àwọn ìwé ìwádìí tó o mọ̀ láti fi ṣèwádìí ohun kan nípa ìjọsìn Báálì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn nǹkan wo ni wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn Báálì? Àkóbá wo ni ìjọsìn Báálì ṣe fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì?

․․․․․

Kí lo rò pé ó mú kí Èlíjà wa kòtò yí ká pẹpẹ Jèhófà, tó sì pọn omi kún inú rẹ̀?

․․․․․

3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Ìgboyà téèyàn gbọ́dọ̀ ní kéèyàn tó lè gbèjà ìjọsìn tòótọ́.

․․․․․

Àǹfààní tó wà fún àwọn tó ní irú ìgboyà náà.

․․․․․

ÀWỌN OHUN MÍÌ TÓ O LÈ FI ṢÈWÀ HÙ.

Àwọn apá ibo nínú ìgbésí ayé rẹ lo ti lè túbọ̀ fi ìgboyà gbèjà ìjọsìn tòótọ́?

․․․․․

4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․

Kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Bíbélì, lórí ìkànnì wa www.watchtower.org ÀTI www.jw.org

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́