ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w12 4/1 ojú ìwé 30-31
  • Mósè Gba Iṣẹ́ Pàtàkì Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mósè Gba Iṣẹ́ Pàtàkì Kan
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Sódómù àti Gòmórà Ṣe Pa Run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Jésù Fi Iṣẹ́ Ìyanu Mú Àwọn Aláìsàn Lára Dá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Òye Jésù Ṣe Àwọn Tó Gbọ́rọ̀ Rẹ̀ Ní Kàyéfì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Jésù Borí Ìdẹwò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
w12 4/1 ojú ìwé 30-31

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Mósè Gba Iṣẹ́ Pàtàkì Kan

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sí ariwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀. Jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn: Jèhófà Ọlọ́run àti Mósè

Àkópọ̀: Jèhófà yan Mósè pé kí ó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.

1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA Ẹ́KÍSÓDÙ 3:1-14; 4:1-17.

Ṣàpèjúwe bí iná tó ń jó igi kékeré náà ṣe rí lójú tìrẹ.

․․․․․

Kí lo rò pé Mósè ṣe, báwo sì ni ojú rẹ̀ àti ohùn rẹ̀ ṣe rí, nígbà tó gbọ́ ohùn Ọlọ́run tó ń pè é, bó ṣe wà nínú Ẹ́kísódù 3:4?

․․․․․

Báwo ni ohùn Mósè ṣe rí nígbà tó ń béèrè àwọn ìbéèrè tó wà nínú Ẹ́kísódù 3:11, 13 àti 4:1, 10 lọ́wọ́ Jèhófà?

․․․․․

2 ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Lo àwọn ìwé ìwádìí míì tó o mọ̀ láti fi ṣèwádìí síwájú sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí: “Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ́.” (Ẹ́kísódù 3:14) Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ̀rọ̀ yẹn láti fi dáhùn ìbéèrè tí Mósè béèrè nípa orúkọ Ọlọ́run?a

․․․․․

Kí lo rò pé ó fà á tí Mósè kò fi fẹ́ láti lọ sọ́dọ̀ Fáráò? (Ojútùú: Ka Númérì 12:3.)

․․․․․

Kí lo rò pé ó fà á tí Mósè kò fi fẹ́ láti lọ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀?

․․․․․

3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Bó ṣe jẹ́ pé ẹ̀rù sábà máa ń ba èèyàn nígbà tó bá fẹ́ ṣe ohun kan tí yóò wá dà bíi pé òun kò ní lè ṣe é.

․․․․․

Bó ṣe dá Jèhófà lójú pé o lè ṣe àwọn nǹkan tó bá sọ pé kó o ṣe.

․․․․․

ÀWỌN OHUN MÍÌ TÓ O LÈ FI ṢÈWÀ HÙ.

Àwọn nǹkan wo ló máa ń bà ọ́ lẹ́rù pé o kò ní lè ṣe nígbà tó o bá fẹ́ ṣe é?

․․․․․

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo nǹkan lo lè ṣe, àwọn nǹkan wo ni Jèhófà Ọlọ́run lè sọ pé kó o ṣe?

․․․․․

4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÀWỌN ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․

Tí o bá fẹ́ ka àpilẹ̀kọ yìí tàbí o fẹ́ tẹ̀ ẹ́ jáde, lọ sí orí ìkànnì wa www.jw.org

Kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Bíbélì, lórí ìkànnì wa www.watchtower.org àti www.jw.org

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ńlá àti àwọn ìwé pẹlẹbẹ jáde tí o lè fi ṣèwádìí jinlẹ̀ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀. Tí o bá fẹ́ mọ̀ sí i, gbìyànjú láti wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kí o kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé tó wà lọ́wọ́ rẹ yìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́