ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w09 5/1 ojú ìwé 26
  • Jésù Borí Ìdẹwò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jésù Borí Ìdẹwò
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Sódómù àti Gòmórà Ṣe Pa Run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Jésù Fi Iṣẹ́ Ìyanu Mú Àwọn Aláìsàn Lára Dá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Òye Jésù Ṣe Àwọn Tó Gbọ́rọ̀ Rẹ̀ Ní Kàyéfì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ọ̀rọ̀ Bẹ́yìn Yọ!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
w09 5/1 ojú ìwé 26

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Jésù Borí Ìdẹwò

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sáriwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ báwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bóhun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA MÁTÍÙ 4:1-11.

Ṣàpèjúwe bí aginjù tí Jésù ti lo ogójì [40] ọjọ́ ṣe rí.

․․․․․

Kí lo kíyè sí nínú bí Adẹniwò náà ṣe sọ̀rọ̀? àti bí Jésù ṣe fèsì?

․․․․․

ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Báwo ni Sátánì ṣe fi hàn pé akóninífà lòun? (Tún ẹsẹ 2 kà.)

․․․․․

Kí nídìí tó fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí Èṣù fi gbogbo ìjọba ayé lọ Jésù ó tún fi “ògo wọn” hàn-án? (Tún ẹsẹ 8 kà.)

․․․․․

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìjọba ayé ni Sátánì sọ pé òun máa gbé fún Jésù?

․․․․․

(a) Kí ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun tí Sátánì fi dẹ Jésù wò jẹ́ ká mọ̀ nípa ohun tí Sátánì ń rò lọ́kàn? ․․․․․

(b) Àmọ́, kí ni ọ̀kọ̀ọ̀kan èsì tí Jésù fún un jẹ́ ká mọ̀ nípa ohun tí Jésù ń rò lọ́kàn? ․․․․․

MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. KỌ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Ìgbà tó ṣeé ṣe kí ìdẹwò wáyé.

․․․․․

Oríṣiríṣi ọ̀nà tí Sátánì lè gbà dẹ wá wò.

․․․․․

Béèyàn ṣe lè kojú ìdẹwò.

․․․․․

KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́