Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
April 15, 2011
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ Ọ̀SẸ̀:
May 30, 2011–June 5, 2011
Bá A Ṣe Lè Fi Ọwọ́ Pàtàkì Mú Iṣẹ́ Ìsìn Wa sí Jèhófà
OJÚ ÌWÉ 9
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 125, 66
June 6-12, 2011
Ẹ Máa Ṣe Ìpinnu Tó Máa Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga
OJÚ ÌWÉ 13
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 112, 104
June 13-19, 2011
“Èso Ti Ẹ̀mí” Ń Fi Ògo fún Ọlọ́run
OJÚ ÌWÉ 18
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 25, 11
June 20-26, 2011
Ṣé Ò Ń Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ọlọ́run Máa Darí Rẹ?
OJÚ ÌWÉ 23
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 120, 48
Ohun Táwọn Àpilẹ̀kọ Tá A Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dá Lé
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1 OJÚ ÌWÉ 9 sí 13
Nínú ayé tí ọ̀pọ̀ èèyàn kì í ti í fi ọwọ́ pàtàkì mú ojúṣe wọn yìí, ó pọn dandan pé kí àwa Kristẹni má ṣe fi ọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbé ayé wa. Èyí tún wá ṣe pàtàkì jù lọ nínú ọ̀nà tá a gbà ń jọ́sìn Jèhófà. Àpilẹ̀kọ yìí á jẹ́ ká mọ bó ṣe yẹ ká máa bójú tó ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni lọ́nà tó wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì tó sì bá Ìwé Mímọ́ mu.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2 OJÚ ÌWÉ 13 sí 17
Ó máa ń ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti ṣe ìpinnu. Àpilẹ̀kọ yìí á ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣàgbéyẹ̀wò ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọ bá a ṣe lè máa ṣe àwọn ìpinnu tó dára. Ó tún máa jíròrò àwọn ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ kí àwọn ìpinnu tá a bá ṣe lè máa gbé orúkọ Ọlọ́run ga.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3, 4 OJÚ ÌWÉ 18 sí 27
Kí ni “èso ti ẹ̀mí”? Báwo la ṣe lè máa fi ṣèwà hù? Kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀? Wàá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí bá a ó ti máa ṣàgbéyẹ̀wò apá mẹ́sàn-án tí èso ti ẹ̀mí pín sí. Àwọn àbá tó wúlò wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí tó máa ran ọ̀pọ̀ nínú wa lọ́wọ́.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
3 Ǹjẹ́ Ò Ń Fòye Mọ Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé Ọlọ́run Ń Tọ́ Wa Sọ́nà?
6 Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ayé Aláìṣòótọ́ Yìí