ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 5/1 ojú ìwé 3
  • Ìṣòro Tó Ń Fi Hàn Pé Ìrètí Ń Bẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìṣòro Tó Ń Fi Hàn Pé Ìrètí Ń Bẹ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Àwọn Àmì Wo Ló Fi Hàn Pé A Ti Wà Ní “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn,” Tàbí “Òpin Ayé”?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ẹ̀kọ́ Arannilọ́wọ́ Fún Àwọn Àkókò Lílekoko Wa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ohun Tó Dára Jù Ń Bọ̀ Lọ́jọ́ Iwájú!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 5/1 ojú ìwé 3

Ìṣòro Tó Ń Fi Hàn Pé Ìrètí Ń Bẹ

“Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín.”—2 TÍMÓTÌ 3:1.

ǸJẸ́ o ti gbọ́ nípa èyíkéyìí lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tó wà nísàlẹ̀ yìí rí tàbí kí ó ṣojú rẹ?

● Àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí tó pa ọ̀pọ̀ èèyàn.

● Ìyàn tó ṣekú pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn.

● Ìsẹ̀lẹ̀, ìyẹn ìmìtìtì ilẹ̀ tó ṣekú pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó sì sọ ọ̀pọ̀ di aláìnílé.

Láwọn ojú ìwé tó tẹ̀ lé èyí, wàá kà nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa mú kó o ronú jinlẹ̀ nípa ipò tí ayé yìí wà. Wàá tún rí i pé, Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,”a ni irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí á máa wáyé.

Àmọ́ ṣá o, a ò kọ àwọn àpilẹ̀kọ́ yìí láti mú kó o gbà pé, à ń gbé nínú ayé tó kún fún ìṣòro. Nítorí ó ṣeé ṣe kí ìwọ́ náà ti fojú ara rẹ rí i. Ìdí tá a fi kọ àwọn àpilẹ̀kọ yìí ni pé, kí wọ́n lè fún ẹ ní ìrètí. Wọ́n máa jẹ́ kó o mọ̀ pé, bí àsọtẹ́lẹ̀ mẹ́fà yìí ṣe ń ṣẹ fi hàn pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” kò ní pẹ́ dópin. Nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ yìí, a tún máa ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àtakò kan táwọn èèyàn ń ṣe sí ẹ̀rí pé a wà lọ́jọ́ ìkẹyìn, àwọn àpilẹ̀kọ yìí tún sọ ìdí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó máa mú ká gbà pé ohun tó dára ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láti mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí, ka àpilẹ̀kọ náà, “Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Ibi àti Ìjìyà?” lójú ìwé 16 àti 17 nínú ìwé ìròyìn yìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́