Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
May 15, 2011
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ Ọ̀SẸ̀:
June 27, 2011–July 3, 2011
Ẹ̀yin Ìdílé Kristẹni—“Ẹ Wà Lójúfò”
OJÚ ÌWÉ 7
July 4-10, 2011
Ẹ̀yin Ìdílé Kristẹni—“Ẹ Wà Ní Ìmúratán”
OJÚ ÌWÉ 11
July 11-17, 2011
Ta Ló Ṣe Pàtàkì Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Rẹ?
OJÚ ÌWÉ 16
July 18-24, 2011
‘Ìjìnlẹ̀ Ọgbọ́n Ọlọ́run Mà Pọ̀ O!’
OJÚ ÌWÉ 21
July 25-31, 2011
Ìgbọ́kànlé Kíkún Nínú Jèhófà Ń Mú Ká Ní Ìgboyà
OJÚ ÌWÉ 28
Ohun Táwọn Àpilẹ̀kọ Tá A Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dá Lé
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1, 2 OJÚ ÌWÉ 7 sí 15
Nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́, a jíròrò ojúṣe tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé Kristẹni ní kó lè rí i pé òun wà lójúfò nípa tẹ̀mí. Àpilẹ̀kọ kejì ṣàgbéyẹ̀wò bí jíjẹ́ kí ojú wa mú ọ̀nà kan, níní àwọn àfojúsùn tẹ̀mí àti ṣíṣe Ìjọsìn Ìdílé ti ṣe pàtàkì tó fún mímú kí gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé ní àjọṣe rere pẹ̀lú Ọlọ́run.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3 OJÚ ÌWÉ 16 sí 20
Jèhófà ló gbọ́dọ̀ ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Àpilẹ̀kọ yìí sọ ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nípa bó ṣe yẹ kí Jèhófà ṣe pàtàkì sí wa tó látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Éfà obìnrin àkọ́kọ́; Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ náà; àti Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni pípé.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4 OJÚ ÌWÉ 21 sí 25
Nínú Róòmù orí 11, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa igi ólífì ìṣàpẹẹrẹ. Kí ni apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lára igi náà dúró fún? Bí a ó ṣe máa ṣe àyẹ̀wò ohun tí wọ́n dúró fún nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa lóye ohun púpọ̀ sí i nípa ète Jèhófà. Yàtọ̀ sí ìyẹn, bí ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe jinlẹ̀ tó máa jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wa.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 5 OJÚ ÌWÉ 28 sí 32
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a jíròrò Sáàmù Kẹta àti Ìkẹrin, èyí tí Dáfídì Ọba kọ. Àwọn orin tí Ọlọ́run mí sí yìí fi hàn pé bá a bá ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ tá a sì ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú rẹ̀ a ó lè máa lo ìgboyà. Ohun tí Dáfídì ṣe nìyẹn nígbà tí ìwà àdàkàdekè, irú èyí tí ọmọ rẹ̀ Ábúsálómù hù, kó ìdààmú bá a.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
3 Ṣé O Máa Ń Gbádùn Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
6 “Alábòójútó Rere àti Ọ̀rẹ́ Wa Ọ̀wọ́n”
26 Bá A Ṣe Lè Máa Tọ Kristi Aṣáájú Pípé Náà Lẹ́yìn