Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
October 15, 2011
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ Ọ̀SẸ̀:
November 28, 2011–December 4, 2011
Ṣé Eré Ìtura Tó O Yàn Máa Ṣe Ẹ́ Láǹfààní?
OJÚ ÌWÉ 8
December 5-11, 2011
Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Fáwọn Tí Kò Ṣègbéyàwó Àtàwọn Tó Ṣègbéyàwó
OJÚ ÌWÉ 13
December 12-18, 2011
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, “Ọlọ́run Ìtùnú Gbogbo”
OJÚ ÌWÉ 23
December 19-25, 2011
“Tu Gbogbo Àwọn Tí Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú”
OJÚ ÌWÉ 27
Ohun Táwọn Àpilẹ̀kọ Tá A Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dá Lé
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1 OJÚ ÌWÉ 8 sí 12
Ibi yòówù ká máa gbé, tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, ó máa mú ká lè yan irú eré ìtura tó máa ṣe wá láǹfààní. Ohun tá a máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè yan eré ìtura tó gbámúṣé.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2 OJÚ ÌWÉ 13 sí 17
Ìpinnu tẹ́nì kan bá ṣe yálà láti má ṣègbéyàwó tàbí láti ṣègbéyàwó máa nípa lórí ìgbésí ayé rẹ̀ látòkèdélẹ̀, ó sì tún máa nípa lórí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ káwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí kò ṣègbéyàwó àtàwọn tó ṣègbéyàwó mọ bí àwọn ìlànà Bíbélì tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì orí 7 ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa ṣe àwọn ìpinnu tó dára.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3, 4 OJÚ ÌWÉ 23 sí 31
Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tí ń kó ìdààmú ọkàn báni làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà àtàwọn mìíràn ń fojú winá rẹ̀. Kí ni díẹ̀ lára irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀? Ibo la ti lè rí ìtùnú tá a nílò gbà? Àwọn àpilẹ̀kọ méjì yìí fi hàn bí Jèhófà àtàwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ṣe ń tu àwọn èèyàn nínú ní àwọn àkókò wàhálà yìí.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
3 Kí Nìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Kí Á “Máa Bá A Nìṣó ní Ṣíṣọ́nà”?
18 Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà Ń Fún Mi Láyọ̀
32 Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Àwòrán Àgbáyé: Replogle Globes ló yọ̀ǹda pé ká lo fọ́tò yìí