Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
November 15, 2011
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ Ọ̀SẸ̀:
December 26, 2011–January 1, 2011
OJÚ ÌWÉ 6
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 133, 23
January 2-8, 2011
Ẹ Máa Rìn Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ẹ̀mí Kẹ́ Ẹ Lè Jogún Ìyè àti Àlàáfíà
OJÚ ÌWÉ 10
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 83, 120
January 9-15, 2011
A Jẹ́ “Olùgbé fún Ìgbà Díẹ̀” Nínú Ayé Búburú
OJÚ ÌWÉ 16
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 40, 85
January 16-22, 2011
Ẹ Ran Àwọn Ọkùnrin Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí
OJÚ ÌWÉ ÀWỌN
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 123, 95
January 23-29, 2011
Ẹ Kọ́ Àwọn Míì Kí Wọ́n Lè Tóótun fún Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn
OJÚ ÌWÉ ÀWỌN
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 45, 10
Ohun Táwọn Àpilẹ̀kọ Tá A Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dá Lé
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1 OJÚ ÌWÉ 6 sí 10
Ọlọ́run fún wa láǹfààní láti máa gbàdúrà. Ṣé ò ń rí ìrànlọ́wọ́ gbà nípasẹ̀ àdúrà? Bó o ti ń dojú kọ àwọn ipò tí ń kó ìdààmú báni, tó ò ń ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, tàbí tó ò ń sapá láti dènà ìdẹwò, àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o rí bí àdúrà ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2 OJÚ ÌWÉ 10 sí 14
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó yẹ káwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Róòmù gbé èrò inú wọn kà kí wọ́n lè jèrè ìyè kí wọ́n sì ní àlàáfíà. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn tó fún wọn.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3 OJÚ ÌWÉ 16 sí 20
Bá a ṣe ṣàlàyé rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí, àwọn olóòótọ́ ayé ìgbàanì gbé láyé gẹ́gẹ́ bí “olùgbé fún ìgbà díẹ̀.” Bó sì ṣe rí fáwọn tó kọ́kọ́ di ọmọlẹ́yìn Jésù náà nìyẹn. Àwọn tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́ lóde òní ńkọ́? Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o mọ ohun tó túmọ̀ sí láti gbé gẹ́gẹ́ bí olùgbé fún ìgbà díẹ̀ nínú ayé búburú yìí.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4, 5 OJÚ ÌWÉ 24 sí 32
A nílò àwọn ọkùnrin tó lè máa mú ipò iwájú nínú ètò Ọlọ́run. Jésù ran ọ̀pọ̀ ọkùnrin lọ́wọ́ láti gbọ́ ìhìn rere, èyí sì wá mú kí wọ́n tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀nà tó gbà ṣe é, àwa náà á mọ bá a ṣe lè ran àwọn ọkùnrin tá à ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lọ́wọ́ àti bá a ṣe lè ran àwọn ọkùnrin tó ti ṣèrìbọmi nínú ìjọ lọ́wọ́ kí wọ́n lè sapá láti tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ètò Jèhófà.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
15 “Aláìlera Ni Mí Báyìí,àmọ́ Mi Ò Ní Wà Bẹ́ẹ̀ Títí Láé!”
21 Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
22 Ǹjẹ́ O Máa Ń Rí Ayọ̀ Nínú “Àǹfààní Ìfúnni Onínúrere”?