ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 12/1 ojú ìwé 10
  • Ǹjẹ́ Ayé Máa Pa Run Ní Ọdún 2012?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ayé Máa Pa Run Ní Ọdún 2012?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ilẹ̀ Ayé Máa Pa Run?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ǹjẹ́ Ilẹ̀ Ayé Wa Yìí Yóò Pa Run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ṣé Àwọn Èèyàn Ò Ní Ba Ayé Yìí Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ilẹ̀ Ayé Yóò Ha Jóná Lúúlúú Bí?
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 12/1 ojú ìwé 10

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Ǹjẹ́ Ayé Máa Pa Run Ní Ọdún 2012?

▪ “Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó gbà gbọ́ pé ayé máa pa run ń rọ́ lọ sí abúlé kan ní orílẹ̀-èdè Faransé . . . Wọ́n gbà gbọ́ pé ayé máa pa run ní December 21, ọdún 2012, ìyẹn jẹ́ òpin ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ó lé àrùnlélọ́gọ́fà ọdún [5,125] lórí kàlẹ́ńdà àtijọ́ tí àwọn Maya ń lò.”—Ìròyìn BBC News.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣáájú ìsìn, àwọn tó pe ara wọn ní onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la ní ọgọ́rùn-ún ọdún kọkànlélógún yìí ń sọ pé ayé máa pa run, àmọ́ ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀, nítorí ayé yìí máa wà títí láé ni. Ó dájú pé ayé kò ní pa run ní ọdún 2012. Yàtọ̀ sí pé ayé kò ni pa run ni ọdún 2012, ńṣe ni a máa wà lọ títí láé.

Bíbélì sọ fún wa pé: “Iran kan lọ, iran miran si bọ̀: ṣugbọn aiye duro titi lai.” (Oníwàásù 1:4, Bibeli Mimọ) Bákan náà, tún ronú nípa ohun tí Aísáyà 45:18 túmọ̀ sí, ó ní: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, . . . Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé àti Olùṣẹ̀dá rẹ̀, Òun tí í ṣe Ẹni tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, ẹni tí kò wulẹ̀ dá a lásán, ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀: ‘Èmi ni Jèhófà, kò sì sí ẹlòmíràn.’”

Ǹjẹ́ bàbá onífẹ̀ẹ́ kan tó fi ọ̀pọ̀ wákàtí ṣe ọkọ̀ ojú omi fún ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí bèbí fún ọmọbìnrin rẹ̀, lè ba ohun ìṣeré náà jẹ́ lẹ́yìn àkókò díẹ̀ tó fi lé ọmọ náà lọ́wọ́? Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìwà ìkà nìyẹn! Bákan náà, Ọlọ́run dá ayé yìí kí àwọn èèyàn lè máa gbádùn rẹ̀. Ọlọ́run sọ fún tọkọtaya àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” Lẹ́yìn náà, “Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28, 31) Ọlọ́run kò tíì yí ohun tó ní lọ́kàn fún ayé yìí pa dà, kò ní gbà kí ayé yìí pa run. Jèhófà fi ìdánilójú sọ̀rọ̀ nígbà tó ń sọ nípa àwọn ìlérí tó ṣe, ó ní: “Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”—Aísáyà 55:11.

Àmọ́ ṣá o, ìfẹ́ Jèhófà ni “láti run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:18) Ó ṣe ìlérí yìí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Nítorí àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.”—Òwe 2:21, 22.

Ìgbà wo ni ọ̀rọ̀ yẹn máa ṣẹ? Kò sí ẹni tó mọ ìgbà náà. Jésù sọ pé: “Ní ti ọjọ́ yẹn tàbí wákàtí náà, kò sí ẹni tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba.” (Máàkù 13:32) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í sọ pé ìgbà kan ni Ọlọ́run máa pa àwọn èèyàn búburú run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ “àmì” àkókò òpin tí wọ́n sì gbà gbọ́ pé aráyé ń gbé ní àkókò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” wọn kò mọ ìgbà náà gan-an tí “òpin” máa dé. (Máàkù 13:4-8, 33; 2 Tímótì 3:1) Wọ́n gbà pé Bàbá wọn ọ̀run àti Ọmọ rẹ̀ nìkan ló mọ ìgbà tó máa dé.

Ní báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run nìṣó ní pẹrẹu, ìyẹn ìjọba ọ̀run tó máa ṣàkóso ayé tó sì máa sọ ọ́ di Párádísè alálàáfíà, èyí tó máa jẹ́ ti ‘àwọn olódodo, tí wọ́n á sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.’—Sáàmù 37:29.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 10]

Image Science and Analysis Laboratory, NASA-Johnson Space Center

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́