Ta Ló Lè Túmọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀?
Àwọn èèyàn sọ pé okùn kan tí ọ̀gbẹ́ni Gordius ta ní kókó ló jẹ́ àdììtú tó ṣòro jù lọ nígbà ayé Alẹkisáńdà Ńlá. Wọ́n gbà pé amòye ló máa lè tú kókó yìí, ìṣẹ́gun ẹni yìí yóò sì tóbi.a Gẹ́gẹ́ bí ìtàn àtẹnudẹ́nu náà ṣe sọ, Alẹkisáńdà tú àdììtú náà, nígbà tó fi idà rẹ̀ gé kókó náà.
JÁLẸ̀ ọ̀pọ̀ ọdún, yàtọ̀ sí pé àwọn amòye ti gbìyànjú láti tú àdììtú tó ṣòro, wọ́n tún ti gbìyànjú láti túmọ̀ àlọ́, láti túmọ̀ àsọtẹ́lẹ̀, wọ́n sì ti gbìyànjú láti sọ bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí.
Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, wọn kì í lè túmọ̀ àdììtú wọ̀nyẹn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn amòye ará Bábílónì kò lè túmọ̀ ìkọ̀wé tó hàn lọ́nà ìyanu lára ògiri ààfin Ọba Bẹliṣásárì nígbà tí àsè ńlá kan ń lọ lọ́wọ́. Wòlíì Jèhófà Ọlọ́run náà, Dáníẹ́lì tí ó ti darúgbó tí àwọn èèyàn mọ̀ pé ó mọ̀ nípa “títú àwọn ìdè títakókó,” ni ẹni tó sì lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ náà. (Dáníẹ́lì 5:12) Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn jẹ́ nípa ìparun Ilẹ̀ Ọba Bábílónì, ó sì ṣẹ ní òru ọjọ́ yẹn gan-an!—Dáníẹ́lì 5:1, 4-8, 25-30.
Kí Ni Àsọtẹ́lẹ̀?
Àsọtẹ́lẹ̀ jẹ́ sísọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ti ṣàkọ́sílẹ̀ rẹ̀ kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ tòótọ́ jẹ́ ọ̀rọ̀ onímìísí tí a kọ sílẹ̀ tàbí tí a sọ, ó jẹ́ ṣíṣí ìfẹ́ Ọlọ́run payá. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wà nínú Bíbélì tó sọ nípa ìgbà tí Mèsáyà máa fara hàn àti bí a ṣe lè dá a mọ̀ àti nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan,” títí kan ìkéde ìdájọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.—Mátíù 24:3; Dáníẹ́lì 9:25.
“Àwọn amòye” ti òde òní, ìyẹn àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, ọrọ̀ ajé, ọ̀ràn ìlera, òṣèlú, ọ̀ràn àyíká àti ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan míì ti gbìyànjú láti sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń gbé ọ̀pọ̀ lára irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ jáde nínú ìròyìn, tí àwọn èèyàn sì ń tẹ́wọ́ gbà wọ́n, síbẹ̀ wọ́n kì í ṣe àsọtẹ́lẹ̀ bí kò ṣe èrò àwọn èèyàn. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà ni èrò wọn máa ń ta ko ara wọn tí wọ́n sì máa ń jiyàn. Ó léwu gan-an láti sọ bí ọjọ́ iwájú ṣe máa rí nítorí kò sẹ́ni tó mọ ọ̀la.
Ọ̀dọ̀ Ẹni Tí Àsọtẹ́lẹ̀ Tòótọ́ Ti Wá
Ibo wá ni àsọtẹ́lẹ̀ tòótọ́ ti wá, ta ló sì lè túmọ̀ rẹ̀? Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kankan nínú Ìwé Mímọ́ tí ó jáde wá láti inú ìtumọ̀ ti ara ẹni èyíkéyìí.” (2 Pétérù 1:20) Ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “ìtumọ̀” jẹ́ ni “ojútùú, ìṣípayá,” ìyẹn “ohun kan tó wà ní dídè tẹ́lẹ̀, àmọ́ tí a tú.” Nítorí náà, Bíbélì The Amplified New Testament túmọ̀ ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ lọ́nà yìí, ó ní: “Àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ kì í ṣe [èrò] tí ẹnì kan . . . gbé kalẹ̀.”
Fojú inú wo awakọ̀ òkun kan tó ta okùn kan ní kókó. Nígbà tó bá ta okùn náà tán, ẹni tí kò mọ okùn ta, á rí bí okùn náà ṣe wé mọ́ra, àmọ́ kò lè mọ bó ṣe máa tú u. Bákan náà, àwọn èèyàn lè ṣàkíyèsí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ tó máa yọrí sí àwọn ìṣòro ńlá lọ́jọ́ iwájú, àmọ́ kò dá wọn lójú ohun tó máa jẹ́ àbájáde rẹ̀.
Kì í ṣe ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò àwọn wòlíì tí Ọlọ́run mí sí láyé àtijọ́ ni wọ́n máa ń gbé yẹ̀ wò tí wọ́n fi máa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, àpẹẹrẹ irú èyí ni ti wòlíì Dáníẹ́lì. Tó bá jẹ́ irú ọgbọ́n yìí ni wọ́n dá láti sọ àsọtẹ́lẹ̀, irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ á jẹ́ èrò ti ara wọn. Yóò jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ ti èèyàn, tó wá látinú èrò ẹ̀dá èèyàn aláìpé. Kàkà bẹ́ẹ̀, Pétérù ń bá àlàyé rẹ̀ lọ pé: “A kò fi ìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípa ìfẹ́ ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.”—2 Pétérù 1:21.
“Ìtúmọ̀ Kò Ha Jẹ́ Ti Ọlọ́run?”
Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún méje [3,700] ọdún sẹ́yìn, wọ́n ju ọkùnrin méjì sínú ẹ̀wọ̀n ní Íjíbítì. Àwọn méjèèjì lá àlá tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Nítorí pé wọn kò lè lọ wádìí lọ́dọ̀ àwọn amòye ilẹ̀ náà, wọ́n sọ ìdààmú ọkàn wọn fún Jósẹ́fù tí wọ́n jọ jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n, wọ́n ní: “A lá àlá kan, kò sì sí olùtumọ̀ lọ́dọ̀ wa.” Ìránṣẹ́ Ọlọ́run yìí ní kí wọ́n sọ àlá náà fún òun, ó ní: “Ìtúmọ̀ kò ha jẹ́ ti Ọlọ́run?” (Jẹ́nẹ́sísì 40:8) Jèhófà Ọlọ́run nìkan ló lè sọ ìtumọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀, bó ti jẹ́ pé awakọ̀ òkun tó ta okùn kan ní kókó nìkan ló lè tú u. Ó ṣe tán, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ti wá. Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mú pé ká yíjú sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún ìtumọ̀ wọn. Ó dájú pé Jósẹ́fù tọ̀nà nígbà tó sọ pé Ọlọ́run ló mọ ìtumọ̀ àwọn àlá.
Ọ̀nà wo ni “ìtúmọ̀ [gbà] jẹ́ ti Ọlọ́run?” Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan àti bí wọ́n ṣe ṣẹ wà lákọsílẹ̀ nínú Bíbélì. Ìtumọ̀ irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń rọrùn láti mọ̀ dé ìwọ̀n àyè kan, ńṣe ló dà bí ìgbà tí awakọ̀ òkun kan tó ta kókó kan bá ṣàlàyé bí a ṣe lè tú u.—Jẹ́nẹ́sísì 18:14; 21:2.
Nínú Bíbélì, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì wà tó jẹ́ pé téèyàn bá ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ tó yí wọn ká lèèyàn lè fi mọ ìtumọ̀ wọn. Wòlíì Dáníẹ́lì rí ìran àsọtẹ́lẹ̀ nípa ‘àgbò tó ní ìwo méjì’ tí “òbúkọ onírun” kan ṣá balẹ̀, òbúkọ yìí ní “ìwo kan tí ó fara hàn gbangba-gbàǹgbà . . . láàárín àwọn ojú rẹ̀.” Àwọn ọ̀rọ̀ tó yí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ká fi hàn pé àgbò tó ní ìwo méjì dúró fún “àwọn ọba Mídíà àti Páṣíà,” òbúkọ náà sì dúró fún “ọba Gíríìsì.” (Dáníẹ́lì 8:3-8, 20-22) Ní ohun tó ju igba [200] ọdún lọ lẹ́yìn náà, “ìwo ńlá” náà, ìyẹn Alẹkisáńdà Ńlá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́gun Páṣíà. Òpìtàn àwọn Júù tó ń jẹ́ Josephus sọ pé, lákòókò kan tí Alẹkisáńdà wà ní àgbègbè Jerúsálẹ́mù tó ń sọ̀rọ̀ nípa ogun tó fẹ́ lọ jà, wọ́n fi àsọtẹ́lẹ̀ yìí hàn án, ó sì gbà pé òun ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ń tọ́ka sí.
Ọ̀nà míì wà tí ‘ìtumọ̀ gbà jẹ́ ti Ọlọ́run.’ Ẹ̀mí mímọ́ ló darí Jósẹ́fù olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run tó fi lè mọ ìtumọ̀ àwọn àlá tó ń pinni lẹ́mìí táwọn ẹlẹ́wọ̀n ẹgbẹ́ rẹ̀ sọ fún un. (Jẹ́nẹ́sísì 41:38) Nígbà tí ìtumọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ kan kò bá dá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run òde òní lójú, wọ́n máa ń gbàdúrà kí wọ́n lè ní ẹ̀mí Ọlọ́run, lẹ́yìn náà, wọ́n á kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n á sì ṣèwádìí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọlọ́run yóò wá tọ́ wọn sọ́nà láti rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó máa jẹ́ kí wọ́n mọ ìtumọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan. Kì í ṣe nípasẹ̀ ọgbọ́n àràmàǹdà èèyàn ni wọ́n fi ń lóye àwọn ìtumọ̀ náà. Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá nítorí pé ẹ̀mí Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ń mú kí wọ́n lóye ìtumọ̀ náà. Inú Bíbélì ni ìtumọ̀ náà ti wá, kò wá látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tó ń wòye sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.—Ìṣe 15:12-21.
Ọ̀nà míì tí ‘ìtumọ̀ gbà jẹ́ ti Ọlọ́run’ ni pé, Ọlọ́run ló máa ń pinnu ìgbà tí àsọtẹ́lẹ̀ máa yé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n máa ń mọ ìtumọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ṣáájú kó tó ṣẹ àti nígbà tó bá ń ṣẹ lọ́wọ́ tàbí lẹ́yìn ìgbà to bá ti ṣẹ tán. Nítorí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ti wá, òun ló máa sọ ìtumọ̀ wọn tí àkókò bá tó lójú rẹ̀.
Nínú ìtàn Jósẹ́fù àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n méjì náà, ó túmọ̀ àlá wọn lọ́jọ́ mẹ́ta ṣáájú kí ó tó ṣẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 40:13, 19) Nígbà tó yá tí wọ́n mú Jósẹ́fù wá síwájú Fáráò alágbára láti túmọ̀ àlá rẹ̀, ọdún méje tí oúnjẹ máa pọ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bẹ̀rẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọ́run mú kí Jósẹ́fù sọ ìtumọ̀ àlá Fáráò kí wọ́n bàa lè ṣètò láti kó ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tí àsọtẹ́lẹ̀ náà fi hàn pé ó máa wà pa mọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 41:29, 39, 40.
Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì bá ti ṣẹ tán làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa tó lóye wọn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé Jésù ni wọ́n ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ wọn ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí i, àmọ́ ẹ̀yìn ìgbà tó jíǹde ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó lóye wọn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. (Sáàmù 22:18; 34:20; Jòhánù 19:24, 36) Paríparí rẹ̀, bí ìwé Dáníẹ́lì 12:4 ti sọ, wọ́n á ‘fi èdìdì di’ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan “títí di àkókò òpin,” ìyẹn ìgbà tí “ìmọ̀ tòótọ́ yóò . . . di púpọ̀ yanturu” gẹ́gẹ́ bí Dáníẹ́lì ti sọ. Àkókò tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ń ṣẹ là ń gbé yìí.b
Bí Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Ṣe Kàn Ẹ́
Jósẹ́fù àti Dáníẹ́lì dúró níwájú àwọn ọba ọjọ́ ayé wọn láti kéde àsọtẹ́lẹ̀ tó kan àwọn orílẹ̀-èdè àtàwọn ìjọba. Àwọn Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní dúró níwájú àwọn èèyàn ọjọ́ ayé wọn láti gbẹnu sọ fún Jèhófà Ọlọ́run alásọtẹ́lẹ̀, àwọn tó sì ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ wọn jàǹfààní tó pọ̀.
Lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ń kéde ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀, ìyẹn ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń sọ fún àwọn èèyàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan” ti ń ṣẹ báyìí. (Mátíù 24:3, 14) Ǹjẹ́ o mọ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn àti bó ṣe kàn ẹ́? Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí o lè lóye, kó o sì jàǹfààní látinú ohun tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó tóbi jù lọ nínú Bíbélì.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìtàn àtẹnudẹ́nu àwọn Gíríìkì sọ pé ọ̀gbẹ́ni Gordius tó tẹ ìlú Gọ́díọ̀mù, tó jẹ́ olú ìlú Fíríjíà dó, so kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ mọ́ òpó kan ní ìlú náà, wọ́n sọ pé ẹni tó bá lè tú kókó okùn náà ló máa ṣẹ́gun Éṣíà lọ́jọ́ iwájú.
b Wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Mẹ́fà Nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Tó Ń Ṣẹ Lójú Wa,” nínú Ilé Ìṣọ́ May 1, 2011.
[Àwọn Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]
Jósẹ́fù àti Dáníẹ́lì sọ pé Ọlọ́run ló mú kí àwọn lè sọ ìtumọ̀ àsọtẹ́lè