Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
January 15, 2012
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
FEBRUARY 27, 2012–MARCH 4, 2012
Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
OJÚ ÌWÉ 4 • ÀWỌN ORIN: 113, 116
MARCH 5-11, 2012
Kọ́ Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́nà Látinú Àpẹẹrẹ Àwọn Àpọ́sítélì Jésù
OJÚ ÌWÉ 9 • ÀWỌN ORIN: 125, 43
MARCH 12-18, 2012
OJÚ ÌWÉ 16 • ÀWỌN ORIN: 107, 13
MARCH 19-25, 2012
Bá A Ṣe Lè Máa Rúbọ Sí Jèhófà Tọkàntọkàn
OJÚ ÌWÉ 21 • ÀWỌN ORIN: 66, 56
MARCH 26, 2012–APRIL 1, 2012
Ẹgbẹ́ Àlùfáà Aládé Tó Máa Ṣe Gbogbo Aráyé Láǹfààní
OJÚ ÌWÉ 26 • ÀWỌN ORIN: 60, 102
OHUN TÁWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ DÁ LÉ
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1 OJÚ ÌWÉ 4 sí 8
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí i pé ọjọ́ pẹ́ tí àwọn Kristẹni tòótọ́ ti ń sapá kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè máa darí àwọn. A máa jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 2012 nínú àpilẹ̀kọ yìí.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2 OJÚ ÌWÉ 9 sí 13
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a jíròrò ohun mẹ́ta tá a lè rí kọ́ lára àwọn àpọ́sítélì àtàwọn Kristẹni mìíràn ní ọ̀rúndún kìíní nípa bá a ṣe lè wà lójúfò. Ó yẹ kí àpilẹ̀kọ yìí mú ká túbọ̀ fẹ́ láti máa jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3 àti 4 OJÚ ÌWÉ 16 sí 25
Lábẹ́ Òfin Mósè, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì máa ń rúbọ sí Jèhófà lọ́pọ̀ ìgbà. Àwọn Kristẹni kò sí lábẹ́ Òfin yẹn. Àmọ́, àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà lónìí lè kọ́ bí wọ́n ṣe lè ní ẹ̀mí ìmoore tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n ní bí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú Òfin náà. Ìyẹn gan-an sì ni ohun tá a máa jíròrò nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 5 OJÚ ÌWÉ 26 sí 30
Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí a mú aráyé pa dà bá Ọlọ́run rẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ṣàlàyé bí ẹgbẹ́ àlùfáà aládé ṣe máa mú aráyé pa dà bá Ọlọ́run rẹ́ àti bí ìyẹn ṣe máa ṣe wá láǹfààní.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
15 Bó O Ṣe Lè Mú Kí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Gbádùn Mọ́ Ẹ Kó sì Ṣe Ẹ́ Láǹfààní
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Ọjà ojú pópó ní San Cristóbal de las Casas, ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Tọkọtaya tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, tí wọ́n kọ́ èdè Tzotzil ń wàásù fún ìdílé kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ ibẹ̀
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MẸ́SÍKÒ
IYE ÈÈYÀN
108,782,804
IYE AKÉDE
710,454
IṢẸ́ ÌTÚMỌ̀ ÈDÈ
30 èdè ìbílẹ̀