Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
March 15, 2012
© 2012 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. Gbogbo ẹ̀tọ́ jẹ́ tiwa.
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
APRIL 30, 2012–MAY 6, 2012
Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè “Jí Lójú Oorun”
OJÚ ÌWÉ 10 • ÀWỌN ORIN: 65, 96
MAY 7-13, 2012
Máa Fi Sọ́kàn Pé Iṣẹ́ Ìwàásù Jẹ́ Kánjúkánjú
OJÚ ÌWÉ 15 • ÀWỌN ORIN: 92, 47
MAY 14-20, 2012
Jẹ́ Kí Ìrètí Tá A Ní Máa Fún Ẹ Láyọ̀
OJÚ ÌWÉ 20 • ÀWỌN ORIN: 129, 134
MAY 21-27, 2012
Ẹ Má Ṣe Wo “Àwọn Ohun Tí Ń Bẹ Lẹ́yìn”
OJÚ ÌWÉ 25 • ÀWỌN ORIN: 119, 17
OHUN TÁWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ DÁ LÉ
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1 àti 2 OJÚ ÌWÉ 10 sí 19
Àwọn ẹ̀kọ́ tí ẹ̀sìn èké ń kọ́ni ti mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn máa tòògbé tàbí kí wọ́n máa sùn nípa tẹ̀mí. Àwọn àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí jíròrò bí a ṣe lè máa jí àwọn èèyàn lójú oorun àti ìdí tó fi jẹ́ kánjúkánjú pé ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. A tún máa rí ìdáhùn sí ìbéèrè méjì yìí: Báwo la ṣe lè máa fi sọ́kàn pé iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ kánjúkánjú? Kí ló túmọ̀ sí láti máa wàásù lọ́nà tó fi hàn pé iṣẹ́ náà jẹ́ kánjúkánjú?
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3 OJÚ ÌWÉ 20 sí 24
Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní “ìrètí tí ó wà láàyè.” (1 Pét. 1:3) Lọ́nà wo, báwo ló sì ṣe kan “àwọn àgùntàn mìíràn”? (Jòh. 10:16) Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o rí ìdí tó fi yẹ kó o máa yọ̀ nínú ìrètí tó o ní, kó o sì máa fojú sọ́nà fún ìmúṣẹ ìrètí náà.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4 OJÚ ÌWÉ 25 sí 29
Jésù kìlọ̀ pé: “Ẹ rántí aya Lọ́ọ̀tì.” (Lúùkù 17:32) Kí nìdí tí ìkìlọ̀ yìí fi ṣe pàtàkì? Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí ọ̀nà mẹ́ta tá a lè gbà ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ náà. Kíyè sí i bóyá ọ̀kan tàbí méjì wà nínú wọn tó yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí nínú ìgbésí ayé rẹ.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
3 “Adùn Ń Bẹ ní Ọwọ́ Ọ̀tún Rẹ Títí Láé”
7 Báwo Lo Ṣe Ń Fúnni Ní Ìmọ̀ràn?
30 Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
32 “Jọ̀wọ́, Ṣé O Lè Yà Wá Ní Fọ́tò?”
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ní orílẹ̀-èdè Màláwì ti jíròrò àwọn ìsọfúnni tó fani mọ́ra tó sì wúlò pẹ̀lú àwọn ọmọléèwé wọn látinú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
MÀLÁWÌ
IYE ÈÈYÀN
13,077,160
IYE AKÉDE
79,157
KÍKỌ́ GBỌ̀NGÀN ÌJỌBA
1,031 láti ọdún 1998